ÌWÉ ÒWE 20
20
1Ẹlẹ́yà ni ọtí waini,
aláriwo ní ọtí líle,
ẹnikẹ́ni tí a bá fi tànjẹ kò gbọ́n.
2Ibinu ọba dàbí bíbú kinniun,
ẹni tí ó bá mú ọba bínú fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu.
3Nǹkan iyì ni pé kí eniyan máa yẹra fún ìjà,
ṣugbọn òmùgọ̀ eniyan níí máa ń jà.
4Ọ̀lẹ kì í dáko ní àkókò,
nítorí náà, nígbà ìkórè, kò ní rí nǹkankan kó jọ.
5Èrò ọkàn eniyan dàbí omi jíjìn,
ẹni tí ó bá ní ìmọ̀ ló lè fà á jáde.
6Ọ̀pọ̀ eniyan a máa ka ara wọn kún olóòótọ́,
ṣugbọn níbo la ti lè rí ẹyọ ẹnìkan tó jẹ́ olódodo?
7Olódodo a máa rìn ní ọ̀nà òtítọ́,
ibukun ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n tẹ̀lé e.
8Nígbà tí ọba bá jókòó sórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀,
ojú ni yóo fi gbọn àwọn ẹni ibi dànù.
9Ta ló lè sọ pé ọkàn òun mọ́,
ati pé òun mọ́, òun kò ní ẹ̀ṣẹ̀?
10Ayédèrú òṣùnwọ̀n jẹ́ ohun ìríra lójú OLUWA.
11Ọmọde pàápàá a máa fi irú eniyan tí òun jẹ́ hàn nípa ìṣe rẹ̀,
bí ohun tí ó ṣe dára, tí ó sì tọ̀nà.
12Ati etí tí ń gbọ́ràn, ati ojú tí ń ríran,
OLUWA ló dá ekinni-keji wọn.
13Má fẹ́ràn oorun àsùnjù, kí o má baà di talaka,
lajú, o óo sì ní oúnjẹ ní àníṣẹ́kù.
14“Èyí kò dára, kò dára” ni ẹni tí ń rajà máa ń wí,
bí ó bá lọ tán, a máa fọ́nnu ọjà ọ̀pọ̀ tí ó rà.
15Wúrà ń bẹ, òkúta olówó iyebíye sì wà lọpọlọpọ,
ṣugbọn ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ni ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye.
16Gba ẹ̀wù ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò,
gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ ẹni tí kò mọ̀ rí.
17Oúnjẹ tí a bá rí lọ́nà èrú máa ń dùn lẹ́nu eniyan,
ṣugbọn nígbà tí a bá jẹ ẹ́ tán, ẹnu ẹni a máa kan.
18Ìmọ̀ràn níí fìdí ètò múlẹ̀,
gba ìtọ́sọ́nà kí o tó lọ jagun.
19Ẹni tí ó ń ṣe òfófó káàkiri a máa tú ọpọlọpọ àṣírí,
nítorí náà má ṣe bá ẹlẹ́jọ́ kẹ́gbẹ́.
20Bí eniyan bá ń fi baba tabi ìyá rẹ̀ bú,
àtùpà rẹ̀ yóo kú láàrin òkùnkùn biribiri.
21Ogún tí a fi ìkánjú kójọ níbẹ̀rẹ̀,
kì í ní ibukun nígbẹ̀yìn.
22Má sọ pé o fẹ́ fi burúkú san burúkú,
gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, yóo sì gbà ọ́.
23Ayédèrú òṣùnwọ̀n jẹ́ ohun ìríra lójú OLUWA,
ìwọ̀n èké kò dára.
24OLUWA ní ń tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni,
eniyan kò lè ní òye ọ̀nà ara rẹ̀.
25Ronú jinlẹ̀ kí o tó jẹ́jẹ̀ẹ́ fún OLUWA,
kí o má baà kábàámọ̀ rẹ̀.
26Ọba tó gbọ́n a máa fẹ́ eniyan burúkú dànù,
a sì lọ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.
27Ẹ̀mí eniyan ni fìtílà OLUWA,
tíí máa wá gbogbo kọ́lọ́fín inú rẹ̀ kiri.
28Ìfẹ́ ati òtítọ́ níí mú kí ọba pẹ́,
òdodo níí sì ń gbé ìjọba rẹ̀ ró.
29Agbára ni ògo ọ̀dọ́,
ewú sì ni ẹwà àgbà.
30Ìjìyà tó fa ọgbẹ́ a máa mú ibi kúrò,
pàṣán a máa mú kí inú mọ́.
Currently Selected:
ÌWÉ ÒWE 20: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010