ORIN DAFIDI 103
103
Ìfẹ́ Ọlọrun
1Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,
fi tinútinú yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.
2Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,
má sì ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀,
3ẹni tí ó ń dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,
tí ó ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn;
4ẹni tí ó ń yọ ẹ̀mí rẹ kúrò ninu ọ̀fìn,
tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati àánú dé ọ ládé.
5Ẹni tí ó ń fi ohun dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn,
tí ó fi ń sọ agbára ìgbà èwe rẹ dọ̀tun bíi ti idì.
6OLUWA a máa dáni láre
a sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo fún gbogbo
àwọn tí a ni lára.
7Ó fi ọ̀nà rẹ̀ han Mose,
ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ han àwọn ọmọ Israẹli.
8Aláàánú ati olóore ni OLUWA,
kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀.
9Kì í fi ìgbà gbogbo báni wí,
bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ̀ kì í pẹ́ títí ayé.
10Kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa,
bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa bí àìdára wa.
11Nítorí bí ọ̀run ti jìnnà sí ilẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣe tóbi tó
sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
12Bí ìlà oòrùn ti jìnnà sí ìwọ oòrùn,
bẹ́ẹ̀ ni ó mú ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.
13Bí baba ti máa ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni OLUWA máa ń ṣàánú àwọn
tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀.
14Nítorí ó mọ ẹ̀dá wa;
ó ranti pé erùpẹ̀ ni wá.#Jak 5:11
15Ọjọ́ ayé ọmọ eniyan dàbí ti koríko,
eniyan a sì máa gbilẹ̀ bí òdòdó inú igbó;
16ṣugbọn bí afẹ́fẹ́ bá ti fẹ́ kọjá lórí rẹ̀,
á rẹ̀ dànù,
ààyè rẹ̀ kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́.
17Ṣugbọn títí ayé ni ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀,
sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
òdodo rẹ̀ wà lára arọmọdọmọ wọn.
18Ó wà lára àwọn tí ó ń pa majẹmu rẹ̀ mọ́,
tí wọn sì ń ranti láti pa òfin rẹ̀ mọ́.
19OLUWA ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́run,
ó sì jọba lórí ohun gbogbo.
20Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,
ẹ̀yin alágbára tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀,
tí ẹ sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
21Ẹ yin OLUWA gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀,
ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀, tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
22Ẹ yin OLUWA, gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,
níbi gbogbo ninu ìjọba rẹ̀.
Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi.
Currently Selected:
ORIN DAFIDI 103: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010