ÌFIHÀN 14
14
Orin Àwọn Ọ̀kẹ́ Meje Ó Lé Ẹgbaaji (144,000) Eniyan
1Mo rí Ọ̀dọ́ Aguntan náà tí ó dúró lórí òkè Sioni, pẹlu àwọn ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹgbaaji (144,000) eniyan tí a kọ orúkọ rẹ̀ ati orúkọ Baba rẹ̀ sí wọn níwájú.#Isi 9:4; Ifi 7:3 2Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run bí ìró ọpọlọpọ omi ati bí ìgbà tí ààrá líle bá ń sán. Ohùn tí mo gbọ́ ni ti àwọn oníhapu tí wọn ń lu hapu wọn. 3Wọ́n ń kọrin titun kan níwájú ìtẹ́ náà ati níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun. Kò sí ẹni tí ó lè mọ orin náà àfi àwọn ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹgbaaji (144,000) eniyan tí a ti rà pada ninu ayé. 4Àwọn ni àwọn tí kò fi obinrin ba ara wọn jẹ́, nítorí wọn kò bá obinrin lòpọ̀ rí. Àwọn yìí ni wọ́n ń tẹ̀lé Ọ̀dọ́ Aguntan náà káàkiri ibi gbogbo tí ó bá ń lọ. Àwọn ni a ti rà pada láti inú ayé, wọ́n dàbí èso àkọ́so fún Ọlọrun ati fún Ọ̀dọ́ Aguntan. 5Ọ̀rọ̀ èké kankan kò sí ní ẹnu wọn. Kò sí àléébù ninu ìgbé-ayé wọn.#Sef 3:13
Iṣẹ́ tí Àwọn Angẹli Mẹta Jẹ́
6Mo tún rí angẹli mìíràn tí ń fò lágbedeméjì ọ̀run. Ó mú ìyìn rere ayérayé lọ́wọ́ láti kéde rẹ̀ fún àwọn tí wọ́n wà ninu ayé, ninu gbogbo ẹ̀yà ati gbogbo orílẹ̀-èdè. 7Ó bá kígbe pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọrun kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí àkókò ìdájọ́ rẹ̀ dé! Ẹ júbà ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, òkun ati gbogbo orísun omi.”
8Angẹli mìíràn tẹ̀lé ti àkọ́kọ́, ó ní, “Ó ti tú! Babiloni ìlú ńlá nnì ti tú! Ìlú tí ó fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní ọtí àgbèrè rẹ̀ mu, tí ó mú ibinu Ọlọrun wá, ó ti tú!”#Ais 21:9; Jer 51:8; Ifi 18:2
9Angẹli kẹta wá tẹ̀lé wọn. Ó kígbe pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá júbà ẹranko náà ati ère rẹ̀, tí ó gba àmì rẹ̀ siwaju rẹ̀ tabi sí ọwọ́ rẹ̀, 10yóo mu ninu ògidì ọtí ibinu Ọlọrun, tí ó wà ninu ife ibinu rẹ̀. Olúwarẹ̀ yóo joró ninu iná àjóòkú níwájú àwọn angẹli mímọ́ ati Ọ̀dọ́ Aguntan.#a Ais 51:17; b Jẹn 19:24; Isi 38:22 11Èéfín iná oró àwọn tí wọ́n bá júbà ẹranko náà ati ère rẹ̀, tí wọ́n gba àmì orúkọ rẹ̀, yóo máa rú títí lae. Kò ní rọlẹ̀ tọ̀sán-tòru.”#Ais 34:10
12Èyí mú kí ó di dandan fún àwọn eniyan Ọlọrun, tí wọn ń pa àṣẹ Ọlọrun mọ́, tí wọ́n sì dúró ninu igbagbọ Jesu láti ní ìfaradà.
13Mo gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá tí ó sọ pé, “Kọ ọ́ sílẹ̀! Àwọn òkú tí wọ́n kú ninu Oluwa láti àkókò yìí lọ ṣe oríire.”
Ẹ̀mí jẹ́rìí sí i pé, “Bẹ́ẹ̀ ni dájúdájú, nítorí wọn yóo sinmi ninu làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn yóo máa tọ̀ wọ́n lẹ́yìn.”
Ìkórè Ayé
14Mo wá rí ìkùukùu funfun. Ẹnìkan tí ó dàbí ọmọ eniyan jókòó lórí ìkùukùu náà. Ó dé adé wúrà. Ó mú dòjé tí ó mú lọ́wọ́.#Dan 7:13 15Angẹli mìíràn jáde láti inú Tẹmpili wá, ó kígbe sí ẹni tí ó jókòó lórí ìkùukùu, pé, “Iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ fún dòjé rẹ; àkókò ìkórè tó: ilé ayé ti tó kórè.”#Joẹl 3:13 16Ẹni tí ó jókòó lórí ìkùukùu náà bá ti dòjé rẹ̀ bọ ilé ayé, ni ó bá kórè ayé.
17Angẹli mìíràn tún jáde wá láti inú Tẹmpili ní ọ̀run, tí òun náà tún mú dòjé mímú lọ́wọ́.
18Angẹli mìíràn wá ti ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ ìrúbọ wá, òun ni ó ní àṣẹ lórí iná. Ó kígbe sí angẹli tí ó ní dòjé mímú pé, “Iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ fún dòjé mímú rẹ. Kó èso àwọn igi eléso ilé ayé jọ, nítorí pé wọ́n ti pọ́n.” 19Ni angẹli tí ó ní dòjé náà bá ti dòjé rẹ̀ bọ inú ilé ayé, ó bá kó èso àjàrà ayé jọ, ó dà wọ́n sí ibi ìfúntí ibinu ńlá Ọlọrun. 20Lẹ́yìn odi ìlú ni ìfúntí náà wà. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹ èso ninu rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí yọ jáde láti inú ìfúntí náà. Jíjìn rẹ̀ mu ẹṣin dé ọrùn, ó sì gba ilẹ̀ lọ ní nǹkan bí igba ibùsọ̀.#Ais 63:3; Ẹk. Jer 1:15; Ifi 19:15
Currently Selected:
ÌFIHÀN 14: YCE
Highlight
Share
Copy
![None](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapistaging.com%2F58%2Fhttps%3A%2F%2Fweb-assets.youversion.com%2Fapp-icons%2Fen.png&w=128&q=75)
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: