ÌFIHÀN 2
2
Iṣẹ́ sí Ìjọ Efesu
1“Kọ ìwé yìí sí òjíṣẹ́ ìjọ Efesu:
“Ẹni tí ó di ìràwọ̀ meje mú ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, tí ó ń rìn láàrin àwọn ọ̀pá fìtílà wúrà meje wí báyìí pé, 2Mo mọ iṣẹ́ rẹ, ati làálàá rẹ, ati ìfaradà rẹ. Mo mọ̀ pé o kò jẹ́ gba àwọn eniyan burúkú mọ́ra. O ti dán àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọn kì í ṣe aposteli wò, o ti rí i pé òpùrọ́ ni wọ́n. 3O ní ìfaradà. O ti farada ìyà nítorí orúkọ mi, o kò sì jẹ́ kí àárẹ̀ mú ọ. 4Ṣugbọn mo ní nǹkan wí sí ọ. O ti kọ ìfẹ́ tí o ní nígbà tí o kọ́kọ́ gbàgbọ́ sílẹ̀. 5Nítorí náà, ranti bí o ti ga tó tẹ́lẹ̀ kí o tó ṣubú; ronupiwada, kí o sì ṣiṣẹ́ bíi ti àkọ́kọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, mò ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, bí o kò bá ronupiwada, n óo mú ọ̀pá fìtílà rẹ kúrò ní ipò rẹ̀. 6Ṣugbọn ò ń ṣe kinní kan tí ó dára: o kórìíra iṣẹ́ àwọn Nikolaiti, tí èmi náà kórìíra.
7“Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.
“Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo fún ní àṣẹ láti jẹ ninu èso igi ìyè tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun.#a Jẹn 2:9; 2Ẹsid 2:12; Ifi 22:2; b Isi 28:13; 31:8
Iṣẹ́ sí Ìjọ Simana
8“Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Simana:
“Báyìí ni ẹni kinni ati ẹni ìkẹyìn wí, ẹni tí ó kú, tí ó tún wà láàyè:#Ais 44:6; 48:12; Ifi 1:17; 22:13 9Mo mọ̀ pé o ní ìṣòro; ati pé o ṣe aláìní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́rọ̀ ni ọ́ ní ọ̀nà mìíràn. Mo mọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tí àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní Juu ń sọ, àwọn tí kì í sì í ṣe Juu; tí ó jẹ́ pé ilé ìpàdé Satani ni wọ́n. 10Má bẹ̀rù ohunkohun tí ò ń bọ̀ wá jìyà. Èṣù yóo gbé ẹlòmíràn ninu yín jù sinu ẹ̀wọ̀n láti fi dán yín wò. Fún ọjọ́ mẹ́wàá ẹ óo ní ìṣòro pupọ. Ṣugbọn jẹ́ olóòótọ́ dé ojú ikú, Èmi yóo sì fún ọ ní adé ìyè.
11“Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.
“Ẹni tí ó bá ṣẹgun kò ní kú ikú keji.#Ifi 20:14; 21:8
Iṣẹ́ sí Ìjọ Pẹgamu
12“Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Pẹgamu pé:
“Ẹni tí ó ní idà olójú meji tí ó mú ní: 13Mo mọ ibi tí ò ń gbé, ibẹ̀ ni Satani tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí. Sibẹ o di orúkọ mi mú, o kò bọ́hùn ninu igbagbọ ní ọjọ́ tí wọ́n pa Antipasi ẹlẹ́rìí òtítọ́ mi ní ìlú yín níbi tí Satani fi ṣe ilé. 14Ṣugbọn mo ní àwọn nǹkan díẹ̀ wí sí ọ. O ní àwọn kan láàrin ìjọ tí wọ́n gba ẹ̀kọ́ Balaamu, ẹni tí ó kọ́ Balaki láti fi ohun ìkọsẹ̀ siwaju àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n fi ń jẹ oúnjẹ ìbọ̀rìṣà, tí wọ́n tún ń ṣe àgbèrè.#a Nọm 22:5,7; 31:16; Diut 23:4; b Nọm 25:1-3 15O tún ní àwọn kan tí àwọn náà gba ẹ̀kọ́ àwọn Nikolaiti. 16Nítorí náà, ronupiwada. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ n óo wá láìpẹ́, n óo sì fi idà tí ó wà lẹ́nu mi bá wọn jà.
17“Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.
“Ẹni tí ó bá ṣẹgun, Èmi óo fún un ní mana tí a ti fi pamọ́. N óo tún fún un ní òkúta funfun kan tí a ti kọ orúkọ titun sí lára. Ẹnikẹ́ni kò mọ orúkọ titun yìí àfi ẹni tí ó bá gba òkúta náà.#a Eks 16:14-15; 16:33-34; Joh 6:48-50; b Ais 62:2; 65:15
Iṣẹ́ sí Ìjọ Tiatira
18“Kọ ìwé yìí sí ìjọ Tiatira pé:
“Ọmọ Ọlọrun, ẹni tí ojú rẹ̀ dàbí ọwọ́ iná, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ń dán bí idẹ. 19Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Mo mọ ìfẹ́ rẹ ati igbagbọ rẹ, mo mọ iṣẹ́ rere tí ò ń ṣe ati ìfaradà rẹ. Iṣẹ́ rẹ ti ìkẹyìn tilẹ̀ dára ju ti àkọ́kọ́ lọ. 20Ṣugbọn mo ní nǹkan wí sí ọ. O gba obinrin tí wọn ń pè ní Jesebẹli láàyè. Ó ń pe ara rẹ̀ ní aríran, ó ń tan àwọn iranṣẹ mi jẹ, ó ń kọ́ wọn láti ṣe àgbèrè ati láti jẹ oúnjẹ ìbọ̀rìṣà.#1 A. Ọba 16:31; 2 A. Ọba 9:22, 30 21Mo fún un ní àkókò kí ó ronupiwada, ṣugbọn kò fẹ́ ronupiwada kúrò ninu ìwà àgbèrè rẹ̀. 22N óo dá a dùbúlẹ̀ àìsàn. Ìṣòro pupọ ni yóo bá àwọn tí wọ́n bá bá a ṣe àgbèrè, àfi bí wọ́n bá rí i pé iṣẹ́ burúkú ni ó ń ṣe, tí wọn kò sì bá a lọ́wọ́ ninu rẹ̀ mọ́. 23N óo fi ikú pa àwọn ọmọ rẹ̀. Gbogbo àwọn ìjọ ni yóo wá mọ̀ pé Èmi ni Èmi máa ń wádìí ọkàn ati èrò ẹ̀dá, n óo sì fi èrè fún olukuluku yín gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.#a O. Daf 7:9 Jer 17:10; b O. Daf 62:12
24“Ṣugbọn ẹ̀yin yòókù ní Tiatira, ẹ̀yin tí ẹ kò gba ẹ̀kọ́ obinrin yìí, ẹ̀yin tí ẹ kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí wọn ń pè ní ohun ìjìnlẹ̀ Satani, n kò ní di ẹrù mìíràn rù yín mọ́. 25Ṣugbọn ṣá, ẹ di ohun tí ẹ ní mú ṣinṣin títí n óo fi dé. 26-28Ẹni tí ó bá ṣẹgun, tí ó forí tì í, tí ó ń ṣe iṣẹ́ mi títí dé òpin, òun ni n óo fún ní àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè, ọ̀pá irin ni yóo fi jọba lórí wọn, bí ìkòkò amọ̀ ni yóo fọ́ wọn túútúú. Irú àṣẹ tí mo gbà lọ́dọ̀ Baba mi ni n óo fún un. N óo tún fún un ní ìràwọ̀ òwúrọ̀.#O. Daf 2:8-9
29“Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.
Currently Selected:
ÌFIHÀN 2: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: