YouVersion Logo
Search Icon

RUTU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ní àkókò jàgídíjàgan, tí àwọn nǹkan tí a kà ninu Ìwé Àwọn Adájọ́ ṣẹlẹ̀, ni àwọn nǹkan tí a kà ninu Ìwé Rutu náà ṣẹlẹ̀. Onírẹ̀lẹ̀, obinrin gidi, ará ilẹ̀ Moabu ni Rutu; ó fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli tí ń gbé ilẹ̀ Moabu nígbà náà. Nígbà tí ọkọ rẹ̀ kú, Rutu fi ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn rẹ̀ hàn, ó sì dúró gbọningbọnin ti ìyá ọkọ rẹ̀, tí òun jẹ́ ará ilẹ̀ Israẹli, kò sì yẹsẹ̀ ninu sísin Ọlọrun Israẹli. Níkẹyìn, ó fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ẹbí ọkọ rẹ̀, nípasẹ̀ ọkọ rẹ̀ yìí, ọmọ ọmọ rẹ̀ bí Dafidi, tí ó wá di ọba tí ó ṣe pataki jùlọ ninu àwọn ọba Israẹli.
Àwọn ìtàn inú Ìwé Àwọn Adájọ́ jẹ́ àkójọpọ̀ ìjìyà tí ó bá àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọn kò tẹ̀lé ọ̀nà Ọlọrun; ṣugbọn ìtàn Rutu fihàn bí àjèjì tí ó tẹ̀lé ọ̀nà Ọlọrun Israẹli ṣe rí ọpọlọpọ ibukun gbà, tí ó sì di ọ̀kan ninu àwọn eniyan Ọlọrun.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Naomi pada sí Bẹtilẹhẹmu pẹlu Rutu 1:1-22
Rutu pàdé Boasi 2:1–3:18
Boasi fẹ́ Rutu 4:1-22

Currently Selected:

RUTU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in