I. Sam 2
2
Adura Hana
1HANNA si gbadura pe, Ọkàn mi yọ̀ si Oluwa, iwo mi li a si gbe soke si Oluwa: ẹnu mi si gboro lori awọn ọta mi; nitoriti emi yọ̀ ni igbala rẹ.
2Kò si ẹniti o mọ́ bi Oluwa: kò si ẹlomiran boyẹ̀ ni iwọ; bẹ̃ni kò si apata bi Ọlọrun wa.
3Máṣe halẹ; má jẹ ki igberaga ki o ti ẹnu nyin jade: nitoripe Ọlọrun olùmọ̀ ni Oluwa, lati ọdọ rẹ̀ wá li ati iwọ̀n ìwa.
4Ọrun awọn alagbara ti ṣẹ, awọn ti o ṣe alailera li a fi agbara dì li amure.
5Awọn ti o yo fun onjẹ ti fi ara wọn ṣe alagbaṣe: awọn ti ebi npa kò si ṣe alaini: tobẹ̃ ti àgan fi bi meje: ẹniti o bimọ pipọ si di alailagbara.
6Oluwa pa, o si sọ di ayè: o mu sọkalẹ lọ si ibojì, o si gbe soke.
7Oluwa sọ di talaka, o si sọ di ọlọrọ̀: o rẹ̀ silẹ, o si gbe soke.
8O gbe talaka soke lati inu erupẹ wá, o gbe alagbe soke lati ori ãtan wá, lati ko wọn jọ pẹlu awọn ọmọ-alade, lati mu wọn jogun itẹ ogo: nitori pe ọwọ̀n aiye ti Oluwa ni, o si ti gbe aiye ka ori wọn.
9Yio pa ẹṣẹ awọn enia mimọ́ rẹ̀ mọ, awọn enia buburu ni yio dakẹ li okunkun; nipa agbara kò si ọkunrin ti yio bori.
10Ao fọ́ awọn ọta Oluwa tutu; lati ọrun wá ni yio san ãrá si wọn: Oluwa yio ṣe idajọ opin aiye; yio fi agbara fun ọba rẹ̀, yio si gbe iwo ẹni-amì-ororo rẹ̀ soke.
11Elkana si lọ si Rama si ile rẹ̀. Ọmọ na si nṣe iranṣẹ fun Oluwa niwaju Eli alufa.
Àwọn Ọmọ Eli
12Awọn ọmọ Eli si jẹ ọmọ Beliali; nwọn kò mọ̀ Oluwa.
13Iṣe awọn alufa pẹlu awọn enia ni, nigbati ẹnikan ba ṣe irubọ, iranṣẹ alufa a de, nigbati ẹran na nho lori iná, ti on ti ọpa-ẹran oniga mẹta li ọwọ́ rẹ̀.
14On a si fi gun inu apẹ, tabi kẹtili tabi òdu, tabi ikokò, gbogbo eyi ti ọpa-ẹran oniga na ba mu wá oke, alufa a mu u fun ara rẹ̀. Bẹ̃ni nwọn nṣe si gbogbo Israeli ti o wá si ibẹ̀ ni Ṣilo.
15Pẹlu ki nwọn ki o to sun ọra na, iranṣẹ alufa a de, a si wi fun ọkunrin ti on ṣe irubọ pe, Fi ẹran fun mi lati sun fun alufa; nitoriti kì yio gba ẹran sisè lọwọ rẹ, bikoṣe tutù.
16Ọkunrin na si wi fun u pe, Jẹ ki wọn sun ọra na nisisiyi, ki o si mu iyekiye ti ọkàn rẹ ba fẹ; nigbana li o da a lohun pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn ki iwọ ki o fi i fun mi nisisiyi: bikoṣe bẹ̃, emi o fi agbara gbà a.
17Ẹṣẹ awọn ọdọmọkunrin na si tobi gidigidi niwaju Oluwa: nitoriti enia korira ẹbọ Oluwa.
Samuẹli ní Ṣilo
18Ṣugbọn Samueli nṣe iranṣẹ niwaju Oluwa, o ṣe ọmọde, ti a wọ̀ ni efodi ọgbọ.
19Pẹlupẹlu iya rẹ̀ da aṣọ ileke penpe fun u, a ma mu fun u wá lọdọdun, nigbati o ba bá ọkọ rẹ̀ goke wá lati ṣe irubọ ọdun.
20Eli sure fun Elkana ati aya rẹ̀ pe ki Oluwa ki o ti ara obinrin yi fun ọ ni iru-ọmọ nipa ibere na ti o bere lọdọ Oluwa. Nwọn si lọ si ile wọn.
21Oluwa si boju wo Hanna, o si loyun, o bi ọmọkunrin mẹta ati ọmọbinrin meji. Samueli ọmọ na si ndagbà niwaju Oluwa.
Eli ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀
22Eli si di arugbo gidigidi, o si gbọ́ gbogbo eyi ti awọn ọmọ rẹ̀ ṣe si gbogbo Israeli; ati bi nwọn ti ima ba awọn obinrin sùn, ti nwọn ma pejọ li ẹnu ọ̀na agọ ajọ.
23O si wi fun wọn pe, Etiri ti emi fi ngbọ́ iru nkan bẹ̃ si nyin? nitoriti emi ngbọ́ iṣe buburu nyin lati ọdọ gbogbo enia yi wá.
24Bẹ̃kọ, ẹnyin ọmọ mi, nitori ki iṣe ihinrere li emi gbọ́: ẹnyin mu enia Ọlọrun dẹṣẹ̀.
25Bi ẹnikan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji, onidajọ yio ṣe idajọ rẹ̀: ṣugbọn bi ẹnikan ba ṣẹ̀ sí Oluwa, tani yio bẹ̀bẹ fun u? Nwọn kò si fi eti si ohùn baba wọn, nitoriti Oluwa nfẹ pa wọn.
26Ọmọ na Samueli ndagba, o si ri ojurere lọdọ Oluwa, ati enia pẹlu.
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìdílé Eli
27Ẹni Ọlọrun kan tọ Eli wá, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, Gbangba ki emi fi ara hàn ile baba rẹ, nigbati nwọn mbẹ ni Egipti ninu ile Farao?
28Emi ko si yàn a kuro larin gbogbo ẹya Israeli lati jẹ alufa mi, lati rubọ lori pẹpẹ mi, lati fi turari jona, lati wọ efodi niwaju mi, emi si fi gbogbo ẹbọ ti ọmọ Israeli ima fi iná sun fun idile baba rẹ?
29Eṣe ti ẹnyin fi tapa si ẹbọ ati ọrẹ mi, ti mo pa li aṣẹ ni ibujoko mi: iwọ si bu ọla fun awọn ọmọ rẹ jù mi lọ, ti ẹ si fi gbogbo ãyo ẹbọ Israeli awọn enia mi mu ara nyin sanra?
30Nitorina Oluwa Ọlọrun Israeli wipe, Emi ti wi nitotọ pe, ile rẹ ati ile baba rẹ, yio ma rin niwaju mi titi: ṣugbọn nisisiyi Oluwa wipe, ki a má ri i; awọn ti o bu ọla fun mi li emi o bu ọla fun, ati awọn ti kò kà mi si li a o si ṣe alaikasi.
31Kiye si i, ọjọ wọnni mbọ̀, ti emi o ke iru rẹ kurò, ati iru baba rẹ, kì yio si arugbo kan ninu ile rẹ.
32Iwọ o ri wahala ti Agọ, ninu gbogbo ọlà ti Ọlọrun yio fi fun Israeli: kì yio si si arugbo kan ninu ile rẹ lailai.
33Ọkunrin ti iṣe tirẹ, ẹniti emi kì yio ke kuro ni ibi pẹpẹ mi, yio wà lati ma pọn ọ loju, lati ma bà ọ ninu jẹ; gbogbo iru ọmọ ile rẹ ni yio kú li abọ̀ ọjọ wọn.
34Eyi li o jẹ àmi fun ọ, ti yio wá si ori ọmọ rẹ mejeji, si ori Hofni ati Finehasi, ni ọjọ kanna li awọn mejeji yio kú.
35Emi o gbe alufa olododo kan dide, ẹniti yio ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu mi, ati ọkàn mi; emi o si kọ ile kan ti yio duro ṣinṣin fun u; yio si ma rin niwaju ẹni-ororo mi li ọjọ gbogbo.
36Yio si ṣe, olukuluku ẹniti o ba kù ni ile rẹ yio wá tẹriba fun u nitori fadaka diẹ, ati nitori okele onjẹ, yio si wipe, Jọwọ fi mi sinu ọkan ninu iṣẹ awọn alufa, ki emi ki o le ma ri akara diẹ jẹ.
Currently Selected:
I. Sam 2: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: