I. Sam 22
22
Saulu Pa Àwọn Àlùfáà
1DAFIDI si kuro nibẹ, o si sa si iho Adullamu; nigbati awọn arakunrin rẹ̀ ati idile baba rẹ̀ si gbọ́ ọ, nwọn si sọkalẹ tọ̀ ọ nibẹ.
2Olukuluku ẹniti o ti wà ninu ipọnju, ati olukuluku ẹniti o ti jẹ gbesè, ati olukuluku ẹniti o wà ninu ibanujẹ, si ko ara wọn jọ sọdọ rẹ̀, on si jẹ olori wọn: awọn ti o wà lọdọ rẹ̀ si to iwọn irinwo ọmọkunrin.
3Dafidi si ti ibẹ̀ na lọ si Mispe ti Moabu: on si wi fun ọba Moabu pe, Jẹ ki baba ati iya mi, emi bẹ̀ ọ, wá ba ọ gbe, titi emi o fi mọ̀ ohun ti Ọlọrun yio ṣe fun mi.
4O si mu wọn wá siwaju ọba Moabu; nwọn si ba a gbe ni gbogbo ọjọ ti Dafidi fi wà ninu ihò na.
5Gadi woli si wi fun Dafidi pe, Máṣe gbe inu ihò na; yẹra, ki o si lọ si ilẹ Juda. Nigbana ni Dafidi si yẹra, o si lọ sinu igbo Hareti.
6Saulu si gbọ́ pe a ri Dafidi ati awọn ọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀; Saulu si ngbe ni Gibea labẹ igi kan ni Rama; ọkọ̀ rẹ̀ si mbẹ lọwọ rẹ̀, ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ si duro tì i;
7Nigbana ni Saulu wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o duro tì i, pe, Njẹ, ẹ gbọ́, ẹnyin ara Benjamini, ọmọ Jesse yio ha fun olukuluku nyin ni oko ati ọgba ajara bi, ki o si sọ gbogbo nyin di olori ẹgbẹgbẹrun ati olori ọrọrun bi?
8Ti gbogbo nyin fi dimọlù si mi, ti kò fi si ẹnikan ti o sọ ọ li eti mi pe, ọmọ mi ti ba ọmọ Jesse mulẹ, bẹ̃ni kò si si ẹnikan ninu nyin ti o ṣanu mi, ti o si sọ ọ li eti mi pe, ọmọ mi mu ki iranṣẹ mi dide si mi lati ba dè mi, bi o ti ri loni?
9Doegi ara Edomu ti a fi jẹ olori awọn iranṣẹ Saulu, si dahun wipe, Emi ri ọmọ Jesse, o wá si Nobu, sọdọ Ahimeleki ọmọ Ahitubu.
10On si bere lọdọ̀ Oluwa fun u, o si fun u li onjẹ o si fun u ni idà Goliati ara Filistia.
11Ọba si ranṣẹ pe Ahimeleki alufa, ọmọ Ahitubu ati gbogbo idile baba rẹ̀, awọn alufa ti o wà ni Nobu: gbogbo wọn li o si wá sọdọ ọba.
12Saulu si wipe, Njẹ gbọ́, iwọ ọmọ Ahitubu. On si wipe, Emi nĩ, oluwa mi.
13Saulu si wi fun u pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi dimọlù si mi, iwọ ati ọmọ Jesse, ti iwọ fi fun u li akara, ati idà, ati ti iwọ fi bere fun u lọdọ Ọlọrun, ki on ki o le dide si mi, lati ba dè mi, bi o ti ri loni?
14Ahimeleki si da ọba lohun, o si wipe, Tali oluwa rẹ̀ ti o ṣe enia re ninu gbogbo awọn iranṣẹ rẹ bi Dafidi, ẹniti iṣe ana ọba, ẹniti o ngbọ́ tirẹ, ti o si li ọla ni ile rẹ?
15Oni li emi o ṣẹṣẹ ma bere li ọwọ́ Ọlọrun fun u bi? ki eyini jinà si mi: ki ọba ki o máṣe ka nkankan si iranṣẹ rẹ̀ lọrùn, tabi si gbogbo idile baba mi: nitoripe iranṣẹ rẹ kò mọ̀ kan ninu gbogbo nkan yi, diẹ tabi pupọ.
16Ọba si wipe, Ahimeleki, kikú ni iwọ o kú, iwọ, ati gbogbo idile baba rẹ.
17Ọba si wi fun awọn aṣaju ti ima sare niwaju ọba, ti o duro tì i, pe, Yipada ki ẹ si pa awọn alufa Oluwa; nitoripe ọwọ́ wọn wà pẹlu Dafidi, ati nitoripe, nwọn mọ̀ igbati on sa, nwọn kò si sọ ọ li eti mi. Ṣugbọn awọn iranṣẹ ọba ko si jẹ fi ọwọ́ wọn le awọn alufa Oluwa lati pa wọn.
18Ọba si wi fun Doegi pe, Iwọ, yipada, ki o si pa awọn alufa. Doegi ara Edomu si yipada, o si kọlu awọn alufa, o si pa li ọjọ na, àrunlelọgọrin enia ti nwọ aṣọ ọgbọ̀ Efodu.
19O si fi oju ida pa ara Nobu, ilu awọn alufa na ati ọkunrin ati obinrin, ọmọ wẹrẹ, ati awọn ti o wà li ẹnu ọmu, ati malu, ati kẹtẹkẹtẹ, ati agutan.
20Ọkan ninu awọn ọmọ Ahimeleki ọmọ Ahitubu ti a npè ni Abiatari si bọ́; o si sa asala tọ Dafidi lọ.
21Abiatari si fi han Dafidi pe, Saulu pa awọn alufa Oluwa tan.
22Dafidi si wi fun Abiatari pe, emi ti mọ̀ ni ijọ na, nigbati Doegi ara Edomu nì ti wà nibẹ̀ pe, nitotọ yio sọ fun Saulu: nitori mi li a ṣe pa gbogbo idile baba rẹ.
23Iwọ joko nihin lọdọ mi, máṣe bẹ̀ru, nitoripe ẹniti nwá ẹmi mi, o nwá ẹmi rẹ: ṣugbọn lọdọ mi ni iwọ o wà li ailewu.
Currently Selected:
I. Sam 22: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: