II. Tim Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìmọ̀ràn tí Paulu gba Timotiu gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àgbà sí ọ̀dọ́ ati olùrànlọ́wọ́ ni ó pọ̀ jù ninu ìwé rẹ̀ keji sí Timotiu. Kókó ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí ni ìforítì. Paulu gba Timotiu ní ìmọ̀ràn pé kí ó máa jẹ́rìí Jesu pẹlu òtítọ́, ati pé kí ó di ẹ̀kọ́ òtítọ́ ti Ìròyìn Ayọ̀ ati ti Majẹmu Laelae mú, kí ó sì ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bí olùkọ́ni ati bí ajíyìnrere, láàrin àtakò ati ìpọ́njú.
Paulu kìlọ̀ fún Timotiu gidigidi nípa bíbá wọn lọ́wọ́ sí iyàn jíjà tí kò mú ọgbọ́n lọ́wọ́, tí kò sì ṣe rere kan fún ẹnikẹ́ni, àfi kí ó máa pa àwọn tí ń gbọ́ ọ lára.
Ninu gbogbo rẹ̀, Paulu rán Timotiu létí irú àpẹẹrẹ tí òun alára jẹ́, ninu ìgbé-ayé òun, igbagbọ òun, ati sùúrù òun, ìfẹ́ òun ati ìforítì òun, ati bí òun ti rí ìpọ́njú ninu inúnibíni.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-2
Ọ̀rọ̀ ìyìn ati ìgbani-níyànjú 1:3—2:13
Ìmọ̀ràn ati ìkìlọ̀ 2:14—4:5
Àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí Paulu 4:6-18
Ọ̀rọ̀ ìparí 4:19-22
Currently Selected:
II. Tim Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.