Iṣe Apo 1
1
Jesu Ṣe Ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́
1TEOFILU, ìhìn iṣaju ni mo ti rò, niti ohun gbogbo ti Jesu bẹ̀rẹ si iṣe, ati si ikọ́,
2Titi o fi di ọjọ ti a gbà a lọ soke, lẹhin ti o ti ti ipa Ẹmi Mimọ́ paṣẹ fun awọn aposteli ti o yàn:
3Awọn ẹniti o si farahàn fun lãye lẹhin ìjiya rẹ̀ nipa ẹ̀rí pupọ ti o daju, ẹniti a ri lọdọ wọn li ogoji ọjọ ti o nsọ ohun ti iṣe ti ijọba Ọlọrun:
4Nigbati o si ba wọn pejọ, o paṣẹ fun wọn, ki nwọn ki o máṣe kuro ni Jerusalemu, ṣugbọn ki nwọn ki o duro dè ileri Baba, eyiti, o wipe, ẹnyin ti gbọ́ li ẹnu mi:
5 Nitori nitotọ ni Johanu fi omi baptisi; ṣugbọn a o fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin, kì iṣe ọjọ pupọ lati oni lọ.
Jesu Gòkè Re Ọ̀run
6Nitorina nigbati nwọn si pejọ, nwọn bi i lere pe, Oluwa, lati igbayi lọ iwọ ó ha mu ijọba pada fun Israeli bi?
7O si wi fun wọn pe, Kì iṣe ti nyin lati mọ̀ akoko tabi ìgba, ti Baba ti yàn nipa agbara on tikararẹ̀.
8 Ṣugbọn ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmí Mimọ́ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalemu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye.
9Nigbati o si ti wi nkan wọnyi, bi nwọn ti nwò, a gbé e soke; awọsanma si gbà a kuro li oju wọn.
10Bi nwọn si ti tẹ̀jumọ́ oju ọrun bi o ti nrè oke, kiyesi i, awọn ọkunrin meji alaṣọ àla duro leti ọdọ wọn;
11Ti nwọn si wipe, Ẹnyin ará Galili, ẽṣe ti ẹ fi duro ti ẹ nwò oju ọrun? Jesu na yi, ti a gbà soke ọrun kuro lọwọ nyin, yio pada bẹ̃ gẹgẹ bi ẹ ti ri i ti o nlọ si ọrun.
A Yan Ẹlòmíràn Dípò Judasi
12Nigbana ni nwọn pada ti ori òke ti a npè ni Olifi lọ si Jerusalemu, ti o sunmọ Jerusalemu ni ìwọn ìrin ọjọ isimi kan.
13Nigbati nwọn si wọle, nwọn lọ si yara oke, nibiti Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, ati Anderu, ati Filippi, ati Tomasi, Bartolomeu, ati Matiu, Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Simoni Selote, ati Juda arakunrin Jakọbu, gbe wà.
14Gbogbo awọn wọnyi fi ọkàn kan duro si adura ati si ẹ̀bẹ, pẹlu awọn obinrin, ati Maria iya Jesu ati awọn arakunrin rẹ̀ pẹlu.
15Ni ijọ wọnni ni Peteru si dide duro li awujọ awọn ọmọ-ẹhin (iye awọn enia gbogbo ninu ijọ jẹ ọgọfa,) o ni,
16Ẹnyin ará, Iwe-mimọ́ kò le ṣe ki o má ṣẹ, ti Ẹmi Mimọ́ ti sọtẹlẹ lati ẹnu Dafidi niti Judasi, ti o ṣe amọ̀na fun awọn ti o mu Jesu.
17Nitori a kà a kún wa, o si ni ipin ninu iṣẹ iranṣẹ yi.
18Njẹ ọkunrin yi sá ti fi ere aiṣõtọ rà ilẹ kan; nigbati o si ṣubu li ògedengbé, o bẹ́ li agbedemeji, gbogbo ifun rẹ̀ si tú jade.
19O si di mimọ̀ fun gbogbo awọn ti ngbe Jerusalemu; nitorina li a fi npè igbẹ́ na ni Akeldama li ède wọn, eyini ni, Igbẹ́ ẹ̀jẹ.
20A sá kọ ọ ninu Iwe Psalmu pe, Jẹ ki ibujoko rẹ̀ ki o di ahoro, ki ẹnikan ki o má si ṣe gbé inu rẹ̀, ati oyè rẹ̀, ni ki ẹlomiran gbà.
21Nitorina ninu awọn ọkunrin wọnyi ti nwọn ti mba wa rìn ni gbogbo akoko ti Jesu Oluwa nwọle, ti o si njade lãrin wa,
22Bẹ̀rẹ lati igba baptismu Johanu wá, titi o fi di ọjọ na ti a gbé e lọ soke kuro lọdọ wa, o yẹ ki ọkan ninu awọn wọnyi ṣe ẹlẹri ajinde rẹ̀ pẹlu wa.
23Nwọn si yàn awọn meji, Josefu ti a npè ni Barsabba, ẹniti a sọ apele rẹ̀ ni Justu, ati Mattia.
24Nwọn si gbadura, nwọn si wipe, Iwọ, Oluwa, olumọ̀ ọkàn gbogbo enia, fihàn ninu awọn meji yi, ewo ni iwọ yàn,
25Ki o le gbà ipò ninu iṣẹ iranṣẹ yi ati iṣẹ aposteli, eyiti Judasi ṣubu kuro ninu rẹ̀ ki o le lọ si ipò ti ara rẹ̀.
26Nwọn si dìbo fun wọn; ìbo si mu Mattia; a si kà a mọ awọn aposteli mọkanla.
Currently Selected:
Iṣe Apo 1: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: