Iṣe Apo 28
28
Ohun tí Paulu Ṣe ní Erékùṣù Mẹlita
1NIGBATI gbogbo wa si yọ tan ni awa mọ̀ pe, Melita li a npè erekuṣu na.
2Kì si iṣe ore diẹ li awọn alaigbede na ṣe fun wa: nitoriti nwọn daná, nwọn si gbà gbogbo wa si ọdọ nitori òjo igba na, ati itori otutù.
3Nigbati Paulu si ṣà ìdi iwọ́nwọ́n igi jọ, ti o si kó o sinu iná, pamọlẹ kan ti inu oru jade, o dì mọ́ ọ li ọwọ́.
4Bi awọn alaigbede na si ti ri ẹranko oloró na ti dì mọ́ ọ li ọwọ́, nwọn ba ara wọn sọ pe, Dajudaju apania li ọkunrin yi, ẹniti o yọ ninu okun tan, ṣugbọn ti ẹsan kò si jẹ ki o wà lãye.
5On si gbọ̀n ẹranko na sinu iná, ohunkohun kan kò ṣe e.
6Ṣugbọn nwọn nwoye igbati yio wú, tabi ti yio si ṣubu lulẹ kú lojiji: nigbati nwọn wò titi, ti nwọn kò si ri nkankan ki o ṣe e, nwọn pa iyè da pe, oriṣa kan li ọkunrin yi.
7Li àgbegbe ibẹ̀ ni ilẹ ọkunrin ọlọlá erekuṣu na wà, orukọ ẹniti a npè ni Publiu; ẹniti o gbà wa si ọdọ, ti o si fi inu rere mu wa wọ̀ ni ijọ mẹta.
8O si ṣe, baba Publiu dubulẹ arùn ibà ati ọ̀rin: ẹniti Paulu wọle tọ̀ lọ, ti o si gbadura fun, nigbati o si fi ọwọ́ le e, o mu u larada.
9Nigbati eyi si ṣe tan, awọn iyokù ti o li arùn li erekuṣu na, tọ̀ ọ wá, o si mu wọn larada:
10Awọn ẹniti o bù ọlá pipọ fun wa; nigbati awa si nlọ, nwọn dì nkan gbogbo rù wa ti a ba ṣe alaini.
Paulu Dé Romu
11Ati lẹhin oṣù mẹta awa wọ̀ ọkọ Aleksandria kan, ti o lo akoko otutu li erekuṣu na, àmi eyi ti iṣe Kastoru on Poluksu.
12Nigbati awa gúnlẹ ni Sirakuse, awa gbé ibẹ̀ ni ijọ mẹta.
13Lati ibẹ̀ nigbati awa lọ yiká, awa de Regioni: ati lẹhin ijọ kan afẹfẹ gusù dide, ni ijọ keji rẹ̀ awa si de Puteoli,
14Nibiti a gbé ri awọn arakunrin, ti nwọn si bẹ̀ wa lati ba wọn gbé ni ijọ meje: bẹ̃li awa si lọ si ìha Romu.
15Ati lati ibẹ nigbati awọn arakunrin gburó wa, nwọn wá titi nwọn fi de Apii Foroni, ati Arojẹ mẹta, lati pade wa: nigbati Paulu si ri wọn, o dupẹ lọwọ Ọlọrun, o mu ọkàn le.
Paulu Waasu ní Romu
16Nigbati awa si de Romu, balogun ọrún fi awọn ondè le olori ẹṣọ́ lọwọ: ṣugbọn nwọn jẹ ki Paulu ki o mã dagbe fun ara rẹ̀ pẹlu ọmọ-ogun ti ṣọ́ ọ.
17O si ṣe, lẹhin ijọ mẹta, Paulu pè awọn olori Ju jọ: nigbati nwọn si pejọ, o wi fun wọn pe, Ará, biotiṣe pe emi kò ṣe ohun kan lòdi si awọn enia, tabi si iṣe awọn baba wa, sibẹ nwọn fi mi le awọn ara Romu lọwọ li ondè lati Jerusalemu wá.
18Nigbati nwọn si wádi ọ̀ran mi, nwọn fẹ jọwọ mi lọwọ lọ, nitoriti kò si ọ̀ran ikú lara mi.
19Ṣugbọn nigbati awọn Ju sọ̀rọ lòdi si i, eyi sún mi lati fi ọ̀ran mi lọ Kesari; kì iṣe pe mo ni nkan lati fi orilẹ-ède mi sùn si.
20Njẹ nitori ọ̀ran yi ni mo ṣe ranṣẹ pè nyin, lati ri nyin, ati lati ba nyin sọ̀rọ: nitoripe nitori ireti Israeli li a ṣe fi ẹ̀wọn yi dè mi.
21Nwọn si wi fun u pe, Awa kò ri iwe gbà lati Judea wá nitori rẹ, bẹ̃li ẹnikan ninu awọn arakunrin ti o ti ibẹ̀ wá kò rohin, tabi ki o sọ̀rọ ibi kan si ọ.
22Ṣugbọn awa nfẹ gbọ́ li ẹnu rẹ ohun ti iwọ rò: nitori bi o ṣe ti ìsin iyapa yi ni, awa mọ̀ pe, nibigbogbo li a nsọ̀rọ lòdi si i.
23Nigbati nwọn dá ọjọ fun u, ọ̀pọlọpọ wọn li o tọ̀ ọ wá ni ile àgbawọ rẹ̀; awọn ẹniti o sọ asọye ọrọ ijọba Ọlọrun fun, o nyi wọn lọkàn pada sipa ti Jesu, lati inu ofin Mose ati awọn woli wá, lati owurọ̀ titi o fi di aṣalẹ.
24Ẹlomiran si gbà ohun ti o nwi gbọ́, ẹlomiran kò si gbagbọ́.
25Nigbati ohùn wọn kò ṣọ̀kan lãrin ara wọn, nwọn tuká, lẹhin igbati Paulu sọ̀rọ kan pe, Otitọ li Ẹmí Mimọ́ sọ lati ẹnu woli Isaiah wá fun awọn baba wa,
26Wipe, Tọ̀ awọn enia wọnyi lọ, ki o si wipe, Ni gbigbọ́ ẹnyin ó gbọ́, kì yio si yé nyin; ati ni riri ẹnyin ó ri, ẹnyin kì yio si woye:
27Nitoriti àiya awọn enia yi sebọ, etí wọn si wuwo lati fi gbọ́, oju wọn ni nwọn si ti dì: nitori ki nwọn ki o má ba fi oju wọn ri, ki nwọn ki o má ba fi etí wọn gbọ́, ati ki nwọn ki o má ba fi ọkàn wọn mọ̀, ki nwọn ki o má ba yipada, ati ki emi ki o má ba mu wọn larada.
28Njẹ ki ẹnyin ki o mọ̀ eyi pe, a rán igbala Ọlọrun si awọn Keferi, nwọn ó si gbọ́.
29Nigbati o si ti sọ ọ̀rọ wọnyi fun wọn tan, awọn Ju lọ, nwọn ba ara wọn jiyàn pipọ.
30Paulu si gbe ile àgbawọ rẹ̀ lọdun meji tọ̀tọ, o si ngbà gbogbo awọn ti o wọle tọ̀ ọ wá,
31O nwasu ijọba Ọlọrun, o si nfi igboiya gbogbo kọ́ni li ohun wọnni ti iṣe ti Jesu Kristi Oluwa, ẹnikan kò da a lẹkun.
Currently Selected:
Iṣe Apo 28: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: