YouVersion Logo
Search Icon

Iṣe Apo 4

4
A Mú Peteru ati Johanu Wá siwaju Ìgbìmọ̀ Àwọn Juu
1BI nwọn si ti mba awọn enia sọrọ, awọn alufa ati olori ẹṣọ́ tẹmpili ati awọn Sadusi dide si wọn.
2Inu bi wọn, nitoriti nwọn nkọ́ awọn enia, nwọn si nwasu ajinde kuro ninu okú ninu Jesu.
3Nwọn si nawọ́ mu wọn, nwọn si há wọn mọ́ ile tubu titi o fi di ijọ keji: nitoriti alẹ lẹ tan.
4Ṣugbọn ọ̀pọ awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na gbagbọ́; iye awọn ọkunrin na si to ẹgbẹ̃dọgbọn.
5O si ṣe nijọ keji, awọn olori wọn ati awọn alagba ati awọn akọwe, pejọ si Jerusalemu,
6Ati Anna olori alufa, ati Kaiafa, ati Johanu, ati Aleksanderu, ati iye awọn ti iṣe ibatan olori alufa.
7Nigbati nwọn si mu wọn duro li ãrin, nwọn bère pe, Agbara tabi orukọ wo li ẹnyin fi ṣe eyi?
8Nigbana ni Peteru kún fun Ẹmí Mimọ́, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin olori awọn enia, ati ẹnyin àgbagbà.
9Bi o ba ṣe pe a nwadi wa loni niti iṣẹ rere ti a ṣe lara abirùn na, bi a ti ṣe mu ọkunrin yi laradá;
10Ki eyi ki o yé gbogbo nyin ati gbogbo enia Israeli pe, li orukọ Jesu Kristi ti Nasareti, ti ẹnyin kàn mọ agbelebu, ti Ọlọrun gbé dide kuro ninu okú, nipa rẹ̀ li ọkunrin yi fi duro niwaju nyin ni dida ara ṣaṣa.
11Eyi li okuta ti a ti ọwọ́ ẹnyin ọmọle kọ̀ silẹ, ti o si di pàtaki igun ile.
12Kò si si igbala lọdọ ẹlomiran: nitori kò si orukọ miran labẹ ọrun ti a fifunni ninu enia, nipa eyiti a le fi gbà wa là.
13Nigbati nwọn si kiyesi igboiya Peteru on Johanu, ti nwọn si mọ̀ pe, alaikẹkọ ati òpe enia ni nwọn, ẹnu yà wọn; nwọn si woye wọn pe, nwọn a ti ma ba Jesu gbé.
14Nigbati nwọn si nwò ọkunrin na ti a mu larada, ti o ba wọn duro, nwọn kò ri nkan wi si i.
15Ṣugbọn nigbati nwọn si paṣẹ pe ki nwọn jade kuro ni igbimọ, nwọn ba ara wọn gbèro,
16Wipe, Kili a o ti ṣe awọn ọkunrin wọnyi? ti pe iṣẹ àmi ti o daju ti ọwọ́ wọn ṣe, o hàn gbangba fun gbogbo awọn ti ngbé Jerusalemu; awa kò si le sẹ́ ẹ.
17Ṣugbọn ki o má bà tàn kalẹ siwaju mọ́ lãrin awọn enia, ẹ jẹ ki a kìlọ fun wọn pe, lati isisiyi lọ ki nwọn ki o máṣe fi orukọ yi sọ̀rọ fun ẹnikẹni mọ́.
18Nigbati nwọn si pè wọn, nwọn paṣẹ fun wọn, ki nwọn máṣe sọ̀rọ rara, bẹni ki nwọn máṣe kọ́ni li orukọ Jesu mọ́.
19Ṣugbọn Peteru on Johanu dahùn, nwọn si wi fun wọn pe, Bi o ba tọ́ li oju Ọlọrun lati gbọ́ ti nyin jù ti Ọlọrun lọ, ẹ gbà a rò,
20Awa kò sá le ṣaima sọ ohun ti awa ti ri, ti a si ti gbọ́.
21Nigbati nwọn si kìlọ fun wọn si i, nwọn jọwọ wọn lọwọ lọ, nigbati nwọn kò ti ri nkan ti nwọn iba fi jẹ wọn ni ìya, nitori awọn enia: nitori gbogbo wọn ni nyìn Ọlọrun logo fun ohun ti a ṣe.
22Nitori ọkunrin na jù ẹni-ogoji ọdún lọ, lara ẹniti a ṣe iṣẹ àmi dida ara yi.
Àwọn Onigbagbọ Gbadura fún Ìgboyà
23Nigbati nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ, nwọn lọ sọdọ awọn ẹgbẹ wọn, nwọn si ròhin ohun gbogbo ti awọn olori alufa ati awọn agbàgba sọ fun wọn.
24Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn fi ọkàn kan gbé ohùn wọn soke si Ọlọrun nwọn si wipe, Oluwa, ìwọ ti o da ọrun on aiye, ati okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn:
25Iwọ nipa Ẹmi Mimọ́ ti o ti ẹnu Dafidi baba wa iranṣẹ rẹ wipe, Ẽṣe ti awọn keferi fi mbinu, ati ti awọn enia ngbero ohun asan?
26Awọn ọba aiye dide, ati awọn ijoye kó ara wọn jọ si Oluwa, ati si Kristi rẹ̀;
27Nitõtọ sá ni, si Jesu Ọmọ mimọ́ rẹ, ẹniti iwọ ti fi oróro yàn, ati Herodu, ati Pontiu Pilatu, pẹlu awọn keferi, ati awọn enia Israeli pejọ si,
28Lati ṣe ohunkohun ti ọwọ́ rẹ ati imọ rẹ ti pinnu ṣaju pe yio ṣẹ.
29Njẹ nisisiyi, Oluwa, kiyesi ikilọ wọn: ki o si fifun awọn ọmọ-ọdọ rẹ lati mã fi igboiya gbogbo sọ ọ̀rọ rẹ.
30Ki iwọ si fi ninà ọwọ́ rẹ ṣe dida ara, ati ki iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu ki o mã ṣe li orukọ Jesu Ọmọ mimọ́ rẹ.
31Nigbati nwọn gbadura tan, ibi ti nwọn gbé pejọ si mi titi; gbogbo wọn si kún fun Ẹmí Mimọ́, nwọn si nfi igboiya sọ ọ̀rọ Ọlọrun.
32Ijọ awọn ti o gbagbọ́ si wà li ọkàn kan ati inu kan: kò si si ẹnikan ti o pè ohun kan ninu ohun ini rẹ̀ ni ti ara rẹ̀: ṣugbọn gbogbo nwọn ni gbogbo nkan ṣọkan.
33Agbara nla li awọn aposteli si fi njẹri ajinde Jesu Oluwa; ore-ọfẹ pipọ si wà lori gbogbo wọn.
34Nitori kò si ẹnikan ninu wọn ti o ṣe alaini: nitori iye awọn ti o ni ilẹ tabi ile tà wọn, nwọn si mu owo ohun ti nwọn tà wá.
35Nwọn si fi i lelẹ li ẹsẹ awọn aposteli: nwọn si npín fun olukuluku, gẹgẹ bi o ti ṣe alaini si.
36Ati Josefu, ti a ti ọwọ awọn aposteli sọ apele rẹ̀ ni Barnaba (itumọ̀ eyi ti ijẹ Ọmọ-Itùnu), ẹ̀ya Lefi, ati ara Kipru.
37O ni ilẹ kan, o tà a, o mu owo rẹ̀ wá, o si fi i lelẹ li ẹsẹ awọn aposteli.

Currently Selected:

Iṣe Apo 4: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in