YouVersion Logo
Search Icon

Eks 20

20
1ỌLỌRUN si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi pe,
2Emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ jade lati ilẹ Egipti, lati oko-ẹrú jade wá.
3Iwọ kò gbọdọ lí Ọlọrun miran pẹlu mi.
4Iwọ kò gbọdọ yá ere fun ara rẹ, tabi aworan ohun kan ti mbẹ loke ọrun, tabi ti ohun kan ti mbẹ ni isalẹ ilẹ, tabi ti ohun kan ti mbẹ ninu omi ni isalẹ̀ ilẹ.
5Iwọ kò gbọdọ tẹ̀ ori ara rẹ ba fun wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn: nitori emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, Ọlọrun owú ni mi, ti mbẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, lati irandiran kẹta ati ẹkẹrin ninu awọn ti o korira mi;
6Emi a si ma fi ãnu hàn ẹgbẹgbẹrun awọn ti o fẹ́ mi, ti nwọn si npa ofin mi mọ́.
7Iwọ kò gbọdọ pè orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ lasan; nitoriti OLUWA ki yio mu awọn ti o pè orukọ rẹ̀ lasan bi alailẹ̀ṣẹ li ọrùn.
8Ranti ọjọ́ isimi, lati yà a simimọ́.
9Ọjọ́ mẹfa ni iwọ o ṣiṣẹ, ti iwọ o si ṣe iṣẹ rẹ gbogbo:
10Ṣugbọn ọjọ́ keje li ijọ́ isimi OLUWA Ọlọrun rẹ: ninu rẹ̀ iwọ kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ohunọ̀sin rẹ, ati alejò rẹ̀ ti mbẹ ninu ibode rẹ:
11Nitori ni ijọ́ mẹfa li OLUWA dá ọrun on aiye, okun ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn, o si simi ni ijọ́ keje: nitorina li OLUWA ṣe busi ijọ́ keje, o si yà a si mimọ́.
12Bọ̀wọ fun baba on iya rẹ: ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ ni ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.
13Iwọ kò gbọdọ pania.
14Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga.
15Iwọ kò gbọdọ jale.
16Iwọ kò gbọdọ jẹri eke si ẹnikeji rẹ.
17Iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si ile ẹnikeji rẹ, iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si aya ẹnikeji rẹ, tabi si ọmọ-ọdọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ-ọdọ rẹ̀ obinrin, akọmalu rẹ̀, kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, tabi ohun gbogbo ti iṣe ti ẹnikeji rẹ.
18Gbogbo awọn enia na si ri ãrá na, ati mànamána na, ati ohùn ipè na, nwọn ri oke na nṣe ẽfi: nigbati awọn enia si ri i, nwọn ṣí, nwọn duro li òkere rére.
19Nwọn si wi fun Mose pe, Iwọ ma bá wa sọ̀rọ̀, awa o si gbọ́: ṣugbọn máṣe jẹ ki Ọlọrun ki o bá wa sọ̀rọ, ki awa ki o má ba kú.
20Mose si wi fun awọn enia pe, Ẹ má bẹ̀ru: nitoriti Ọlọrun wá lati dan nyin wò, ati ki ẹ̀ru rẹ̀ ki o le ma wà li oju nyin, ki ẹnyin ki o máṣe ṣẹ̀.
21Awọn enia si duro li òkere rére, Mose si sunmọ ibi òkunkun ṣiṣu na nibiti Ọlọrun gbé wà.
22OLUWA si wi fun Mose pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin ri bi emi ti bá nyin sọ̀rọ lati ọrun wá.
23Ẹnyin kò gbọdọ ṣe ọlọrun miran pẹlu mi; Ẹnyin kò gbọdọ ṣe ọlọrun fadaka, tabi ọlọrun wurà, fun ara nyin.
24Pẹpẹ erupẹ ni ki iwọ mọ fun mi, lori rẹ̀ ni ki iwọ ki o ma ru ẹbọ sisun rẹ, ati ẹbọ alafia rẹ, agutan rẹ, ati akọmalu rẹ: ni ibi gbogbo ti mo ba gbé fi iranti orukọ mi si, emi o ma tọ̀ ọ wá, emi o si ma bukún fun ọ.
25Bi iwọ o ba si mọ pẹpẹ okuta fun mi, iwọ kò gbọdọ fi okuta gbigbẹ́ mọ ọ: nitori bi iwọ ba gbé ohun-ọnà rẹ lé ori rẹ̀, iwọ sọ ọ di aimọ́.
26Iwọ kò si gbọdọ ba àkasọ gùn ori pẹpẹ mi, ki ìhoho rẹ ki o máṣe hàn lori rẹ̀.

Currently Selected:

Eks 20: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in