Eks 36
36
1BESALELI ati Oholiabu yio si ṣiṣẹ, ati olukuluku ọlọgbọ́n inu, ninu ẹniti OLUWA fi ọgbọn ati oyé si, lati mọ̀ bi a ti ṣiṣẹ onirũru iṣẹ ìsin ibi mimọ́ na, gẹgẹ bi gbogbo ohun ti OLUWA ti palaṣẹ.
2Mose si pè Besaleli ati Oholiabu, ati gbogbo ọkunrin ọlọgbọ́n inu, ninu ọkàn ẹniti OLUWA fi ọgbọ́n si, ani gbogbo ẹniti inu wọn ru soke lati wá si ibi iṣẹ na lati ṣe e:
3Nwọn si gbà gbogbo ọrẹ na lọwọ Mose, ti awọn ọmọ Israeli múwa fun iṣẹ ìsin ibi mimọ́ na, lati fi ṣe e. Sibẹ̀ nwọn si nmú ọrẹ ọfẹ fun u wá li orowurọ̀.
4Ati gbogbo awọn ọkunrin ọlọgbọ́n, ti o ṣe gbogbo isẹ ibi mimọ́ na, lọ olukuluku kuro ni ibi iṣẹ rẹ̀ ti nwọn ṣe;
5Nwọn si sọ fun Mose pe, Awọn enia múwa pupọ̀ju fun iṣẹ ìsin na, ti OLUWA palaṣẹ ni ṣiṣe.
6Mose si paṣẹ, nwọn si ṣe ki nwọn ki o kede yi gbogbo ibudó na ká, wipe, Máṣe jẹ ki ọkunrin tabi obinrin ki o tun ṣe iṣẹkiṣẹ fun ọrẹ ibi mimọ́ na mọ́. Bẹ̃li a da awọn enia lẹkun ati ma múwa.
7Nitoriti ohun-èlo ti nwọn ni o to fun gbogbo iṣẹ na, lati fi ṣe e, o si pọ̀ju.
8Ati olukuluku ọkunrin ọlọgbọ́n ninu awọn ti o ṣe iṣẹ agọ́ na, nwọn ṣiṣẹ aṣọ-tita mẹwa; ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ati ti aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, pẹlu awọn kerubu, iṣẹ-ọnà li on fi ṣe wọn.
9Ina aṣọ-tita kan jẹ́ igbọnwọ mejidilọgbọ̀n, ati ibò aṣọ-tita kan jẹ́ igbọnwọ mẹrin: gbogbo aṣọ-tita na jẹ́ ìwọn kanna.
10O si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn: ati aṣọ-tita marun keji li o si solù mọ́ ara wọn.
11O si pa ojóbo aṣọ-alaró li eti aṣọ-tita kan lati iṣẹti rẹ̀ wá ni ibi isolù; bẹ̃ gẹgẹ li o ṣe si ìha eti ikangun aṣọ-tita keji nibi isolù keji.
12Ãdọta ojóbo li o pa lara aṣọ-tita kan, ati ãdọta ojóbo li o si pa li eti aṣọ-tita ti o wà ni isolù keji: ojóbo na so aṣọ-tita kini mọ́ keji.
13O si ṣe ãdọta ikọ́ wurà, o si fi ikọ́ wọnni fi aṣọ-tita kan kọ́ ekeji: bẹ̃li o si di odidi agọ́.
14O si ṣe aṣọ-tita irun ewurẹ fun agọ́ na lori ibugbé na: aṣọ-tita mọkanla li o ṣe wọn.
15Ìna aṣọ-tita kan jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, ibò aṣọ-tita kan si jẹ́ igbọnwọ mẹrin: aṣọ-tita mọkọkanla jẹ́ ìwọn kanna.
16O si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn, ati aṣọ-tita mẹfa lù mọ́ ara wọn.
17O si pa ãdọta ojóbo si ìha eti ikangun aṣọ-tita na ni ibi isolù, ati ãdọta ojóbo li o si pa si eti aṣọ-tita ti o so ekeji lù.
18O si ṣe ãdọta ikọ́ idẹ lati so agọ́ na lù pọ̀, ki o le ṣe ọkan.
19O si ṣe ibori awọ àgbo ti a sè ni pupa fun agọ́ na, ati ibori awọ seali lori eyi.
20O si ṣe apáko igi ṣittimu fun agọ́ na li ogurodo.
21Gigùn apáko kan jẹ́ igbọnwọ mẹwa, ati ibú apáko kan jẹ́ igbọnwọ kan on àbọ.
22Apáko kan ni ìtẹbọ meji, nwọn jìna si ara wọn li ọgbọgba; bẹ̃li o ṣe sara gbogbo apáko agọ́ na.
23O si fi apáko ṣe agọ́ na; ogún apáko ni fun ìha ọtún, si ìha gusù:
24Ati ogoji ihò-ìtẹbọ fadakà li o ṣe nisalẹ ogún apáko wọnni; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan fun ìtẹbọ rẹ̀ meji, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀ meji nisalẹ apáko keji fun ìtẹbọ rẹ̀ meji.
25Ati fun ìha keji agọ́ na, ti o wà ni ìha ariwa, o ṣe ogún apáko,
26Ati ogoji ihò-ìtẹbọ wọn ti fadakà; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji.
27Ati fun ìha agọ́ na ni ìha ìwọ-õrùn o ṣe apáko mẹfa.
28Apáko meji li o ṣe fun igun agọ́ na ni ìha mejeji.
29A si so wọn lù nisalẹ, a si so wọn lù pọ̀ li ori rẹ̀, si oruka kan: bẹ̃li o ṣe si awọn meji ni igun mejeji.
30Apáko mẹjọ li o wà, ihò-ìtẹbọ wọn si jẹ́ ihò-ìtẹbọ mẹrindilogun ti fadakà; ìtẹbọ mejimeji li o wà nisalẹ apáko kọkan.
31O si ṣe ọpá igi ṣittimu; marun fun apáko ìha kan agọ́ na,
32Ati ọpá marun fun apáko ìha keji agọ́ na, ati ọpá marun fun apáko agọ́ na fun ìha ìwọ-õrùn.
33O si ṣe ọpá ãrin o yọ jade lara apáko wọnni, lati opin ekini dé ekeji.
34O si fi wurà bò apáko wọnni, o si fi wurà ṣe oruka wọn, lati ṣe ipò fun ọpá wọnni, o si fi wurà bò ọpá wọnni.
35O si fi aṣọ-alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ṣe aṣọ-ikele: iṣẹ ọlọnà li o fi ṣe e ti on ti awọn kerubu.
36O si ṣe opó igi ṣittimu mẹrin si i, o si fi wurà bò wọn: kọkọrọ wọn ti wurà ni, o si dà ihò-ìtẹbọ fadakà mẹrin fun wọn.
37O si ṣe aṣọ-isorọ̀ kan fun ẹnu-ọ̀na Agọ́ na, aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ti iṣẹ abẹ́rẹ;
38Ati opó rẹ̀ mararun ti on ti kọkọrọ wọn: o si fi wurà bò ọnà ori wọn, ati ọjá wọn: ṣugbọn idẹ ni ihò-ìtẹbọ wọn mararun.
Currently Selected:
Eks 36: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: