YouVersion Logo
Search Icon

Gẹn 25

25
Àwọn Ọmọ Mìíràn Tí Abrahamu Bí
(I. Kro 1:32-33)
1ABRAHAMU si tun fẹ́ aya kan, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Ketura.
2O si bí Simrani, ati Jokṣani, ati Medani, ati Midiani, ati Iṣbaku, ati Ṣua fun u.
3Jokṣani si bí Ṣeba, ati Dedani. Awọn ọmọ Dedani si ni Aṣurimu, ati Letuṣimu, ati Leumimu.
4Ati awọn ọmọ Midiani; Efa, ati Eferi, ati Hanoku, ati Abida, ati Eldaa. Gbogbo awọn wọnyi li ọmọ Ketura.
5Abrahamu si fi gbogbo ohun ti o ni fun Isaaki.
6Ṣugbọn awọn ọmọ àle ti Abrahamu ni, Abrahamu bùn wọn li ẹ̀bun, o si rán wọn lọ kuro lọdọ Isaaki, ọmọ rẹ̀, nigbati o wà lãye, si ìha ìla-õrùn, si ilẹ ìla-õrùn.
Ikú ati Ìsìnkú Abrahamu
7Iwọnyi si li ọjọ́ ọdún aiye Abrahamu ti o wà, arun dí lọgọsan ọdún.
8Abrahamu si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o si kú li ogbologbo, arugbo, o kún fun ọjọ́; a si kó o jọ pẹlu awọn enia rẹ̀.
9Awọn ọmọ rẹ̀, Isaaki ati Iṣmaeli si sin i ni ihò Makpela, li oko Efroni, ọmọ Sohari enia Hitti, ti o wà niwaju Mamre;
10Oko ti Abrahamu rà lọwọ awọn ọmọ Heti: nibẹ̀ li a gbé sin Abrahamu, ati Sara, aya rẹ̀.
11O si ṣe lẹhin ikú Abrahamu li Ọlọrun bukún fun Isaaki, ọmọ rẹ̀; Isaaki si joko leti kanga Lahai-roi.
Àwọn Ìran Iṣimaeli
(I. Kro 1:28-31)
12Iwọnyi si ni iran Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu, ti Hagari, ara Egipti, ọmọbinrin ọdọ Sara bí fun Abrahamu:
13Iwọnyi si li orukọ awọn ọmọkunrin Iṣmaeli, nipa orukọ wọn, ni iran idile wọn: akọ́bi Iṣmaeli, Nebajotu; ati Kedari, ati Adbeeli, ati Mibsamu,
14Ati Miṣma, ati Duma, ati Masa;
15Hadari, ati Tema, Jeturi, Nafiṣi, ati Kedema:
16Awọn wọnyi li awọn ọmọ Iṣmaeli, iwọnyi si li orukọ wọn, li ori-ori ilu wọn, li ori-ori ile odi wọn; ijoye mejila li orilẹ-ède wọn.
17Iwọnyi si li ọdún aiye Iṣmaeli, ẹtadilogoje ọdún: o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o si kú; a si kó o jọ pọ̀ pẹlu awọn enia rẹ.
18Nwọn si tẹ̀dó lati Hafila lọ titi o fi de Ṣuri, ti o wà niwaju Egipti, bi iwọ ti nlọ sìha Assiria: o si kú niwaju awọn arakonrin rẹ̀ gbogbo.
Ìbí Esau ati Jakọbu
19Iwọnyi si ni iran Isaaki, ọmọ Abrahamu: Abrahamu bí Isaaki:
20Isaaki si jẹ ẹni ogoji ọdún, nigbati o mu Rebeka, ọmọbinrin Betueli, ara Siria ti Padan-aramu, arabinrin Labani ara Siria, li aya.
21Isaaki si bẹ̀ OLUWA fun aya rẹ̀, nitoriti o yàgan: OLUWA si gbà ẹ̀bẹ rẹ̀, Rebeka, aya rẹ̀, si loyun.
22Awọn ọmọ si njàgudu ninu rẹ̀: o si wipe, bi o ba ṣe pe bẹ̃ni yio ri, ẽṣe ti mo fi ri bayi? O si lọ bère lọdọ OLUWA.
23OLUWA si wi fun u pe, orilẹ-ède meji ni mbẹ ninu rẹ, irú enia meji ni yio yà lati inu rẹ: awọn enia kan yio le jù ekeji lọ; ẹgbọ́n ni yio si ma sìn aburo.
24Nigbati ọjọ́ rẹ̀ ti yio bí si pé, si kiyesi i, ibeji li o wà ninu rẹ̀.
25Akọ́bi si jade wá, o pupa, ara rẹ̀ gbogbo ri bí aṣọ onirun; nwọn si sọ orukọ rẹ̀ ni Esau.
26Ati lẹhin eyini li arakunrin rẹ̀ jade wá, ọwọ́ rẹ̀ si dì gigĩsẹ Esau mu; a si sọ orukọ rẹ̀ ni Jakobu: Isaaki si jẹ ẹni ọgọta ọdún nigbati Rebeka bí wọn.
Esau Ta Ipò Àgbà Rẹ̀
27Awọn ọmọdekunrin na si dàgba: Esau si ṣe ọlọgbọ́n ọdẹ, ara oko; Jakobu si ṣe ọbọrọ́ enia, a ma gbé inu agọ́.
28Isaaki si fẹ́ Esau, nitori ti o njẹ ninu ẹran-ọdẹ rẹ̀: ṣugbọn Rebeka fẹ́ Jakobu.
29Jakobu si pa ìpẹtẹ: Esau si ti inu igbẹ́ dé, o si rẹ̀ ẹ:
30Esau si wi fun Jakobu pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ìpẹtẹ rẹ pupa nì bọ́ mi; nitori ti o rẹ̀ mi: nitori na li a ṣe npè orukọ rẹ̀ ni Edomu.
31Jakobu si wipe, Tà ogún-ibí rẹ fun mi loni.
32Esau si wipe, Sa wò o na, emi ni nkú lọ yi: ore kini ogún-ibí yi yio si ṣe fun mi?
33Jakobu si wipe, Bura fun mi loni; o si bura fun u: o si tà ogún-ibí rẹ̀ fun Jakobu.
34Nigbana ni Jakobu fi àkara ati ìpẹtẹ lentile fun Esau; o si jẹ, o si mu, o si dide, o si ba tirẹ̀ lọ: bayi ni Esau gàn ogún-ibí rẹ̀.

Currently Selected:

Gẹn 25: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in