Gẹn 32
32
Jakọbu Múra láti Pàdé Esau
1JAKOBU si nlọ li ọ̀na rẹ̀, awọn angeli Ọlọrun si pade rẹ̀.
2Nigbati Jakobu si ri wọn, o ni, Ogun Ọlọrun li eyi: o si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Mahanaimu.
3Jakobu si ranṣẹ siwaju rẹ̀ si Esau, arakunrin rẹ̀, si ilẹ Seiri, pápa oko Edomu.
4O si rán wọn wipe, Bayi ni ki ẹnyin ki o wi fun Esau, oluwa mi; Bayi ni Jakobu iranṣẹ rẹ wi, Mo ti ṣe atipo lọdọ Labani, mo si ti ngbé ibẹ̀ titi o fi di isisiyi:
5Mo si ní malu, ati kẹtẹkẹtẹ, ati agbo-ẹran, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin: mo si ranṣẹ wá wi fun oluwa mi, ki emi ki o le ri ore-ọfẹ li oju rẹ.
6Awọn onṣẹ si pada tọ̀ Jakobu wá, wipe, Awa dé ọdọ Esau, arakunrin rẹ, o si mbọ̀wá kò ọ, irinwo ọkunrin li o si wà pẹlu rẹ̀.
7Nigbana li ẹ̀ru bà Jakobu gidigidi, ãjo si mú u, o si pín awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀, ati awọn ọwọ́-ẹran, awọn ọwọ́-malu, ati awọn ibakasiẹ, si ipa meji;
8O si wipe, bi Esau ba kàn ẹgbẹ kan, ti o si kọlù u, njẹ ẹgbẹ keji ti o kù yio là.
9Jakobu si wipe, Ọlọrun Abrahamu baba mi, ati Ọlọrun Isaaki baba mi, OLUWA ti o wi fun mi pe, pada lọ si ilẹ rẹ, ati sọdọ awọn ara rẹ, emi o si ṣe ọ ni rere:
10Emi kò yẹ si kikini ninu gbogbo ãnu, ati ninu gbogbo otitọ, ti iwọ fihàn fun ọmọ-ọdọ rẹ, nitori pe, kìki ọpá mi ni mo fi kọja Jordani yi; nisisiyi emi si di ẹgbẹ meji.
11Emi bẹ̀ ọ, gbà mi lọwọ arakunrin mi, lọwọ Esau: nitori ti mo bẹ̀ru rẹ̀, ki o má ba wá lati kọlù mi, ti iya ti ọmọ.
12Iwọ si wipe, Nitõtọ emi o ṣe ọ ni rere, emi o si ṣe irú-ọmọ rẹ bi iyanrin okun, ti a kò le kà fun ọ̀pọlọpọ.
13O si sùn nibẹ̀ li alẹ ijọ́ na; o si mú ninu ohun ti o tẹ̀ ẹ li ọwọ li ọrẹ fun Esau, arakunrin rẹ̀;
14Igba ewurẹ, on ogún obukọ, igba agutan, on ogún àgbo,
15Ọgbọ̀n ibakasiẹ ti o ní wàra, pẹlu awọn ọmọ wọn, ogojì abo-malu on akọ-malu mẹwa, ogún abo-kẹtẹkẹtẹ, on ọmọ-kẹtẹkẹtẹ mẹwa.
16O si fi wọn lé ọwọ́ awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ni ọ̀wọ́ kọkan; o si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Ẹnyin ṣaju mi, ki ẹ si fi àlàfo si agbedemeji ọwọ́-ọwọ.
17O si fi aṣẹ fun eyiti o tète ṣaju wipe, Nigbati Esau, arakunrin mi, ba pade rẹ, ti o si bi ọ wipe, Ti tani iwọ? nibo ni iwọ si nrè? ati ti tani wọnyi niwaju rẹ?
18Nigbana ni ki iwọ ki o wipe, Ti Jakobu iranṣẹ rẹ ni; ọrẹ ti o rán si Esau oluwa mi ni: si kiyesi i, on tikalarẹ̀ si mbẹ lẹhin wa.
19Bẹ̃li o si fi aṣẹ fun ekeji, ati fun ẹkẹta, ati fun gbogbo awọn ti o tẹle ọwọ́ wọnni wipe, Bayibayi ni ki ẹnyin ki o wi fun Esau nigbati ẹnyin ba ri i.
20Ki ẹnyin ki o wi pẹlu pe, Kiyesi i, Jakobu iranṣẹ rẹ mbọ̀ lẹhin wa. Nitori ti o wipe, Emi o fi ọrẹ ti o ṣaju mi tù u loju, lẹhin eyini emi o ri oju rẹ̀, bọya yio tẹwọgbà mi.
21Bẹ̃li ọrẹ na si kọja lọ niwaju rẹ̀: on tikalarẹ̀ si sùn li oru na ninu awọn ẹgbẹ.
Jakọbu jìjàkadì ní Penieli
22O si dide li oru na, o si mú awọn aya rẹ̀ mejeji, ati awọn iranṣẹbinrin rẹ̀ mejeji, ati awọn ọmọ rẹ̀ mọkọkanla, o si kọja iwọdò Jabboku.
23O si mú wọn, o si rán wọn si oke odò na, o si rán ohun ti o ní kọja si oke odò.
24O si kù Jakobu nikan; ọkunrin kan si mbá a jijakadi titi o fi di afẹmọ́jumọ.
25Nigbati o si ri pe on kò le dá a, o fọwọkàn a ni ihò egungun itan rẹ̀; ihò egungun itan Jakobu si yẹ̀ li orike, bi o ti mbá a jijakadi.
26O si wipe, Jẹ ki emi ki o lọ nitori ti ojúmọ mọ́ tán. On si wipe, Emi ki yio jẹ ki iwọ ki o lọ, bikoṣepe iwọ ba sure fun mi.
27O si bi i pe, Orukọ rẹ? On si dahùn pe, Jakobu.
28O si wipe, A ki yio pè orukọ rẹ ni Jakobu mọ́, bikoṣe Israeli: nitoripe, iwọ ti ba Ọlọrun ati enia jà, iwọ si bori.
29Jakobu si bi i o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, sọ orukọ rẹ fun mi. On si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi mbère orukọ mi? o si sure fun u nibẹ̀.
30Jakobu si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Penieli: o ni, Nitori ti mo ri Ọlọrun li ojukoju, a si dá ẹmi mi si.
31Bi o si ti nkọja Penieli, õrùn là bá a, o si nmukun ni itan rẹ̀.
32Nitori na li awọn ọmọ Israeli ki iṣe ijẹ iṣan ti ifà, ti o wà ni kòto itan, titi o fi di oni-oloni: nitori ti o fọwọkàn kòto egungun itan Jakobu ni iṣan ti ifà.
Currently Selected:
Gẹn 32: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: