Gẹn 42
42
Àwọn Arakunrin Josẹfu Lọ Ra Ọkà ní Ijipti
1NIGBATI Jakobu si ri pe ọkà wà ni Egipti, Jakobu wi fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eṣe ti ẹnyin fi nwò ara nyin li oju?
2O si wipe, Wò o, mo gbọ́ pe ọkà mbẹ ni Egipti: ẹ sọkalẹ lọ sibẹ̀, ki ẹ si rà fun wa lati ibẹ̀ wá; ki awa ki o le yè, ki a máṣe kú.
3Awọn arakunrin Josefu mẹwẹwa si sọkalẹ lọ lati rà ọkà ni Egipti.
4Ṣugbọn Jakobu kò rán Benjamini arakunrin Josefu pẹlu awọn arakunrin rẹ̀; nitori ti o wipe, Ki ibi ki o má ba bá a.
5Awọn ọmọ Israeli si wá irà ọkà ninu awọn ti o wá: nitori ìyan na mú ni ilẹ Kenaani.
6Josefu li o si ṣe balẹ ilẹ na, on li o ntà fun gbogbo awọn enia ilẹ na; awọn arakunrin Josefu si wá, nwọn si tẹ̀ ori wọn ba fun u, nwọn dojubolẹ.
7Josefu si ri awọn arakunrin rẹ̀, o si mọ̀ wọn, ṣugbọn o fi ara rẹ̀ ṣe àjeji fun wọn, o si sọ̀rọ akọ si wọn: o si wi fun wọn pe, Nibo li ẹnyin ti wá? nwọn si wipe, Lati ilẹ Kenaani lati rà onjẹ.
8Josefu si mọ̀ awọn arakunrin rẹ̀, ṣugbọn awọn kò mọ̀ ọ.
9Josefu si ranti alá wọnni ti o ti lá si wọn, o si wi fun wọn pe, Amí li ẹnyin; lati ri ìhoho ilẹ yi li ẹnyin ṣe wá.
10Nwọn si wi fun u pe, Bẹ̃kọ, oluwa mi, ṣugbọn lati rà onjẹ li awọn iranṣẹ rẹ ṣe wá.
11Ọmọ ẹnikan na ni gbogbo wa iṣe; olõtọ enia li awa, awa iranṣẹ rẹ ki iṣe amí.
12O si wi fun wọn pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn lati ri ìhoho ilẹ li ẹ ṣe wá.
13Nwọn si wipe, Arakunrin mejila li awa iranṣẹ rẹ, ọmọ ẹnikan na ni ilẹ Kenaani: si wò o, eyi abikẹhin si wà lọdọ baba wa loni-oloni, ọkan kò si sí.
14Josefu si wi fun wọn pe, On na li eyiti mo wi fun nyin pe, Amí li ẹnyin:
15Eyi bayi li a o fi ridi nyin, nipa ẹmi Farao bi ẹnyin o ti lọ nihin, bikoṣepe arakunrin abikẹhin nyin wá ihinyi.
16Ẹ rán ẹnikan ninu nyin, ki o si mú arakunrin nyin wá, a o si pa nyin mọ́ ninu túbu, ki a le ridi ọ̀rọ nyin, bi otitọ wà ninu nyin: bikoṣe bẹ̃, ẹmi Farao bi amí ki ẹnyin iṣe.
17O si kó gbogbo wọn pọ̀ sinu túbu ni ijọ́ mẹta.
18Josefu si wi fun wọn ni ijọ́ kẹta pe, Ẹ ṣe eyi ki ẹ si yè; nitori emi bẹ̀ru Ọlọrun.
19Bi ẹnyin ba ṣe olõtọ enia, ki a mú ọkan ninu awọn arakunrin nyin dè ni ile túbu nyin: ẹ lọ, ẹ mú ọkà lọ nitori ìyan ile nyin.
20Ṣugbọn ẹ mú arakunrin nyin abikẹhin fun mi wá; bẹ̃li a o si mọ̀ ọ̀rọ nyin li otitọ, ẹ ki yio si kú. Nwọn si ṣe bẹ̃.
21Nwọn si wi fun ara wọn pe, Awa jẹbi nitõtọ nipa ti arakunrin wa, niti pe, a ri àrokan ọkàn rẹ̀, nigbati o bẹ̀ wa, awa kò si fẹ́ igbọ́; nitorina ni iyọnu yi ṣe bá wa.
22Reubeni si da wọn li ohùn pe, Emi kò wi fun nyin pe, Ẹ máṣe ṣẹ̀ si ọmọde na; ẹ kò si fẹ̀ igbọ́? si wò o, nisisiyi, a mbère ẹ̀jẹ rẹ̀.
23Nwọn kò si mọ̀ pe Josefu gbède wọn; nitori gbedegbẹyọ li o fi mba wọn sọ̀rọ.
24O si yipada kuro lọdọ wọn, o si sọkun; o si tun pada tọ̀ wọn wá, o si bá wọn sọ̀rọ, o si mú Ṣimeoni ninu wọn, o si dè e li oju wọn.
Àwọn Arakunrin Josẹfu Pada sí Kenaani
25Nigbana ni Josefu paṣẹ ki nwọn fi ọkà kún inu àpo wọn, ki nwọn si mú owo olukuluku pada sinu àpo rẹ̀, ki nwọn ki o si fun wọn li onjẹ ọ̀na; bayi li o si ṣe fun wọn.
26Nwọn si dì ọkà lé kẹtẹkẹtẹ wọn, nwọn si lọ kuro nibẹ̀.
27Bi ọkan ninu wọn si ti tú àpo rẹ̀ ni ile-èro lati fun kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ li onjẹ, o kofiri owo rẹ̀; si wò o, o wà li ẹnu àpo rẹ̀.
28O si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Nwọn mú owo mi pada; si wò o, o tilẹ wà li àpo mi: àiya si fò wọn, ẹ̀ru si bà wọn, nwọn nwi fun ara wọn pe, Kili eyiti Ọlọrun ṣe si wa yi?
29Nwọn si dé ọdọ Jakobu baba wọn ni ilẹ Kenaani, nwọn si ròhin ohun gbogbo ti o bá wọn fun u wipe,
30Ọkunrin na ti iṣe oluwa ilẹ na, sọ̀rọ lile si wa, o si fi wa pè amí ilẹ na.
31A si wi fun u pe, Olõtọ, enia li awa; awa ki iṣe amí:
32Arakunrin mejila li awa, ọmọ baba wa; ọkan kò sí, abikẹhin si wà lọdọ baba wa ni ilẹ Kenaani loni-oloni.
33Ọkunrin na, oluwa ilẹ na, si wi fun wa pe, Nipa eyi li emi o fi mọ̀ pe olõtọ enia li ẹnyin; ẹ fi ọkan ninu awọn arakunrin nyin silẹ lọdọ mi, ki ẹ si mú onjẹ nitori ìyan ile nyin, ki ẹ si ma lọ.
34Ẹ si mú arakunrin nyin abikẹhin nì tọ̀ mi wá: nigbana li emi o mọ̀ pe ẹnyin ki iṣe amí, bikoṣe olõtọ enia: emi o si fi arakunrin nyin lé nyin lọwọ, ẹnyin o si ma ṣòwo ni ilẹ yi.
35O si ṣe, bi nwọn ti ndà àpo wọn, wò o, ìdi owo olukuluku wà ninu àpo rẹ̀: nigbati awọn ati baba wọn si ri ìdi owo wọnni, ẹ̀ru bà wọn.
36Jakobu baba wọn si wi fun wọn pe, Emi li ẹnyin gbà li ọmọ: Josefu kò sí; Simeoni kò si sí; ẹ si nfẹ́ mú Benjamini lọ: lara mi ni gbogbo nkan wọnyi pọ̀ si.
37Reubeni si wi fun baba rẹ̀ pe, Pa ọmọ mi mejeji bi emi kò ba mú u fun ọ wá: fi i lé mi lọwọ, emi o si mú u pada fun ọ wá.
38On si wipe, Ọmọ mi ki yio bá nyin sọkalẹ lọ; nitori arakunrin rẹ̀ ti kú, on nikan li o si kù: bi ibi ba bá a li ọ̀na ti ẹnyin nlọ, nigbana li ẹnyin o fi ibinujẹ mú ewú mi lọ si isà-okú.
Currently Selected:
Gẹn 42: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: