Isa 20
20
Àmì Wolii tó Wà Níhòohò
1LI ọdun ti Tartani wá si Aṣdodi, (nigbati Sargoni ọba Assiria rán a,) ti o si ba Aṣdodi jà, ti o si kó o;
2Li akoko na li Oluwa wi nipa Isaiah ọmọ Amosi, pe, Lọ, bọ aṣọ-ọ̀fọ kuro li ẹgbẹ́ rẹ, si bọ́ bàta rẹ kuro li ẹsẹ rẹ. O si ṣe bẹ̃, o nrin nihòho ati laibọ̀ bàta.
3Oluwa si wipe, Gẹgẹ bi Isaiah iranṣẹ mi ti rìn nihòho ati laibọ̀ bàta li ọdun mẹta fun ami ati iyanu lori Egipti ati lori Etiopia;
4Bẹ̃li ọba Assiria yio kó awọn ara Egipti ni igbèkun ati awọn ara Etiopia ni igbèkun, ọmọde ati arugbo, nihòho ati laibọ̀ bàta, ani ti awọn ti idí wọn nihòho, si itiju Egipti.
5Ẹ̀ru yio si bà wọn, oju o si tì wọn fun Etiopia ireti wọn, ati fun Egipti ogo wọn.
6Awọn olugbé àgbegbe okun yio si wi li ọjọ na pe, Kiyesi i, iru eyi ni ireti wa, nibiti awa salọ fun iranlọwọ ki a ba le gbani là kuro li ọwọ́ ọba Assiria: ati bawo li a o si ṣe salà?
Currently Selected:
Isa 20: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: