Isa 23
23
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Tire
1Ọ̀RỌ-ìmọ niti Tire. Hu, ẹnyin ọkọ̀ Tarṣiṣi; nitoriti a o sọ ọ di ahoro, tobẹ̃ ti kò si ile, kò si ibi wiwọ̀: a fi hàn fun wọn lati ilẹ Kittimu.
2Ẹ duro jẹ, ẹnyin olugbé erekùṣu; iwọ ẹniti awọn oniṣowo Sidoni, ti nre okun kọja ti kún.
3Ati nipa omi nla iru Sihori, ikorè odò, ni owo ọdun rẹ̀; on ni ọjà awọn orilẹ-ède.
4Ki oju ki o tì ọ, Iwọ Sidoni: nitori okun ti sọ̀rọ, ani agbara okun, wipe, Emi kò rọbi, bẹ̃ni emi kò bi ọmọ, bẹ̃li emi kò tọ́ ọdọmọkunrin dàgba, bẹ̃ni emi kò tọ́ wundia dàgba.
5Gẹgẹ bi ihìn niti Egipti, bẹ̃ni ara yio ro wọn goro ni ihìn Tire.
6Ẹ kọja si Tarṣiṣi; hu, ẹnyin olugbé erekùṣu.
7Eyi ha ni ilu ayọ̀ fun nyin, ti o ti wà lati ọjọ jọjọ? ẹsẹ on tikara rẹ̀ yio rù u lọ si ọna jijìn rére lati ṣe atipó.
8Tali o ti gbìmọ yi si Tire, ilu ade, awọn oniṣòwo ẹniti o jẹ ọmọ-alade, awọn alajapá ẹniti o jẹ ọlọla aiye?
9Oluwa awọn ọmọ-ogun ti pete rẹ̀, lati sọ irera gbogbo ogo di aimọ́, lati sọ gbogbo awọn ọlọla aiye di ẹ̀gan.
10La ilẹ rẹ ja bi odò, iwọ ọmọbinrin Tarṣiṣi: àmure kò si mọ́.
11O nà ọwọ́ rẹ̀ jade si oju okun, o mì awọn ijọba: Oluwa ti pa aṣẹ niti Kenaani, lati run agbàra inu rẹ̀.
12On si wipe, Iwọ kò gbọdọ yọ̀ mọ, iwọ wundia ti a ni lara, ọmọbinrin Sidoni; dide rekọja lọ si Kittimu, nibẹ pẹlu iwọ kì yio ri isimi.
13Wò ilẹ awọn ara Kaldea; awọn enia yi kò ti si ri, titi awọn ara Assiria tẹ̀ ẹ dó fun awọn ti ngbe aginju: nwọn kọ́ ile-iṣọ́ inu rẹ̀, nwọn si kọ́ ãfin inu rẹ̀; on si pa a run.
14Hu, ẹnyin ọkọ̀ Tarṣiṣi: nitori a sọ agbara nyin di ahoro.
15Yio si ṣe li ọjọ na, ni a o gbagbe Tire li ãdọrin ọdun, gẹgẹ bi ọjọ ọba kan: lẹhin ãdọrin ọdun ni Tire yio kọrin bi panṣaga obinrin.
16Mu harpu kan, kiri ilu lọ, iwọ panṣaga obinrin ti a ti gbagbe; dá orin didùn: kọ orin pupọ̀ ki a le ranti rẹ.
17Yio si ṣe li ẹhìn ãdọrin ọdun, ni Oluwa yio bẹ̀ Tire wò, yio si yipadà si ọ̀ya rẹ̀, yio si ba gbogbo ijọba aiye yi ti o wà lori ilẹ ṣe àgbere.
18Ọjà rẹ̀ ati ọ̀ya rẹ̀ yio jẹ mimọ́ si Oluwa: a kì yio fi ṣura, bẹ̃li a ki yio tò o jọ; nitori ọjà rẹ̀ yio jẹ ti awọn ti ngbe iwaju Oluwa, lati jẹ ajẹtẹrùn, ati fun aṣọ daradara.
Currently Selected:
Isa 23: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: