Isa 39
39
Ọba Babiloni kọ ìwé kí Hesekaya
1LI akoko na ni Merodaki-baladani, ọmọ Baladani, ọba Babiloni, rán iwe ati ọrẹ si Hesekiah: nitori o ti gbọ́ pe o ti ṣaisàn, o si ti sàn.
2Inu Hesekiah si dùn si wọn, o si fi ile iṣura hàn wọn, fadaka, ati wura, ati nkan olõrun didùn, ati ikunra iyebiye, ati ile gbogbo ìhamọra rẹ̀, ati ohun gbogbo ti a ri ninu iṣura rẹ̀: kò si si nkankan ti Hesekiah kò fi hàn wọn ninu ile rẹ̀, tabi ni ijọba rẹ̀.
3Nigbana ni wolĩ Isaiah wá sọdọ Hesekiah ọba, o si wi fun u pe, Kini awọn ọkunrin wọnyi wi? ati lati ibo ni nwọn ti wá sọdọ rẹ? Hesekiah si wi pe, Lati ilẹ jijin ni nwọn ti wá sọdọ mi, ani lati Babiloni.
4O si wipe, Kini nwọn ri ni ile rẹ? Hesekiah si dahùn pe, Ohun gbogbo ti o wà ni ile mi ni nwọn ti ri: kò si nkankan ti emi kò fi hàn wọn ninu iṣura mi.
5Nigbana ni Isaiah wi fun Hesekiah pe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa awọn ọmọ-ogun:
6Kiyesi i, ọjọ na dé, ti a o kó ohun gbogbo ti o wà ni ile rẹ, ati ohun ti awọn baba rẹ ti kojọ titi di oni, lọ si Babiloni: kò si nkankan ti yio kù, li Oluwa wi.
7Ati ninu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti yio ti inu rẹ jade, ti iwọ o bi, ni nwọn o kó lọ: nwọn o si jẹ́ iwẹ̀fa ni ãfin ọba Babiloni.
8Nigbana ni Hesekiah wi fun Isaiah pe, Rere ni ọ̀rọ Oluwa ti iwọ ti sọ. O si wi pẹlu pe, Alafia ati otitọ́ yio sa wà li ọjọ mi.
Currently Selected:
Isa 39: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: