Isa 48
48
Ọlọrun ni OLUWA Ọjọ́ Iwájú
1GBỌ́ eyi, ẹnyin ile Jakobu, ti a nfi orukọ Israeli pè, ti o si ti inu omi Juda wọnni jade wá, ti o nfi orukọ Oluwa bura, ti o si ndarukọ Ọlọrun Israeli, ṣugbọn ki iṣe li otitọ, tabi li ododo.
2Nitori nwọn npè ara wọn ni ti ilu mimọ́ nì, nwọn si gbé ara wọn le Ọlọrun Israeli: Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.
3Emi ti sọ nkan ti iṣãju wọnni lati ipilẹṣẹ; nwọn si ti jade lati ẹnu mi lọ, emi si fi wọn hàn; emi ṣe wọn lojijì, nwọn si ti ṣẹ.
4Nitori emi mọ̀ pe olori-lile ni iwọ, ọrùn rẹ jẹ iṣan irin, iwaju rẹ si jẹ idẹ.
5Li atetekọṣe ni mo tilẹ ti sọ fun ọ; ki o to de ni emi ti fihàn ọ: ki iwọ má ba wipe, Oriṣa mi li o ṣe wọn, ati ere mi gbigbẹ́, ati ere mi didà li o ti pa wọn li aṣẹ.
6Iwọ ti gbọ́, wò gbogbo eyi; ẹnyin kì yio ha sọ ọ? Emi ti fi ohun titun hàn ọ lati igba yi lọ, ani nkan ti o pamọ́, iwọ kò si mọ̀ wọn.
7Nisisiyi li a dá wọn, ki isi ṣe li atetekọṣe; ani ṣaju ọjọ na ti iwọ kò gbọ́ wọn; ki iwọ má ba wipe, Kiyesi i, emi mọ̀ wọn.
8Lõtọ, iwọ kò gbọ́; lõtọ, iwọ kò mọ̀; lõtọ lati igba na eti rẹ̀ kò ṣi: nitori ti emi mọ̀ pe, iwọ o hùwa arekerekè, gidigidi li a si pè ọ li olurekọja lati inu wá.
9Nitori orukọ mi emi o mu ibinu mi pẹ, ati nitori iyìn mi, emi o fàsẹhin nitori rẹ, ki emi má ba ké ọ kuro.
10Wò o, emi ti dà ọ, ṣugbọn ki iṣe bi fadaka; emi ti yan ọ ninu iná ileru wahala.
11Nitori emi tikalami, ani nitori ti emi tikala mi, li emi o ṣe e, nitori a o ha ṣe bà orukọ mi jẹ? emi kì yio si fi ogo mi fun ẹlomiran.
Kirusi Alákòóso tí OLUWA Yàn
12Gbọ́ ti emi, iwọ Jakobu, ati Israeli, ẹni-ipè mi; Emi na ni; emi li ẹni-ikini, ati ẹni-ikẹhin.
13Ọwọ́ mi pẹlu li o si ti fi ipilẹ aiye sọlẹ, atẹlẹwọ ọ̀tun mi li o si na awọn ọrun: nigbati mo pè wọn, nwọn jumọ dide duro.
14Gbogbo nyin, ẹ pejọ, ẹ si gbọ́; tani ninu wọn ti o ti sọ nkan wọnyi? Oluwa ti fẹ́ ẹ: yio si ṣe ifẹ rẹ̀ ni Babiloni, apá rẹ̀ yio si wà lara awọn ara Kaldea.
15Emi, ani emi ti sọ ọ; lõtọ emi ti pè e: emi ti mu u wá, on o si mu ọ̀na rẹ̀ ṣe dẽde.
16Ẹ sunmọ ọdọ mi, ẹ gbọ́ eyi; lati ipilẹ̀ṣẹ emi kò sọ̀rọ ni ikọ̀kọ; lati igbati o ti wà, nibẹ ni mo wà; ati nisisiyi Oluwa Jehofa, on Ẹmi rẹ̀, li o ti rán mi.
Ìlànà Ọlọrun fún Àwọn Eniyan Rẹ̀
17Bayi li Oluwa wi, Olurapada rẹ, Ẹni-Mimọ Israeli: Emi li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o kọ́ ọ fun èrè, ẹniti o tọ́ ọ li ọ̀na ti iwọ iba ma lọ.
18Ibaṣepe iwọ fi eti si ofin mi! nigbana ni alafia rẹ iba dabi odo, ati ododo rẹ bi ìgbi-omi okun.
19Iru-ọmọ rẹ pẹlu iba dabi iyanrìn, ati ọmọ-bibi inu rẹ bi tãra rẹ̀; a ki ba ti ke orukọ rẹ̀ kuro, bẹ̃ni a kì ba pa a run kuro niwaju mi.
20Ẹ jade kuro ni Babiloni, ẹ sá kuro lọdọ awọn ara Kaldea, ẹ fi ohùn orin sọ ọ, wi eyi, sọ ọ jade titi de opin aiye; ẹ wipe, Oluwa ti rà Jakobu iranṣẹ rẹ̀ pada.
21Ongbẹ kò si gbẹ wọn, nigbati o mu wọn là aginjù wọnni ja; o mu omi ṣàn jade lati inu apata fun wọn, o sán apáta pẹlu, omi si tú jade.
22Alafia kò si fun awọn enia buburu, li Oluwa wi.
Currently Selected:
Isa 48: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: