YouVersion Logo
Search Icon

A. Oni 12

12
Jẹfuta ati Àwọn Ará Efuraimu
1AWỌN ọkunrin Efraimu si kó ara wọn jọ, nwọn si kọja si ìha ariwa; nwọn si wi fun Jefta pe, Ẽṣe ti iwọ fi rekọja lati bá awọn ọmọ Ammoni jà, ti iwọ kò si pè wa ki awa ki o le bá ọ lọ? awa o fi iná kun ile rẹ mọ́ ọ lori.
2Jefta si wi fun wọn pe, Emi ati awọn enia mi ti mbá awọn ọmọ Ammoni jà gidigidi; nigbati emi kepè nyin, ẹnyin kò si gbà mi li ọwọ́ wọn.
3Nigbati emi si ri pe ẹnyin kò gbà mi, mo fi ẹmi mi wewu, emi si rekọja sọdọ awọn ọmọ Ammoni, OLUWA si fi nwọn lé mi li ọwọ́: nitori kini ẹnyin ha ṣe gòke tọ̀ mi wá li oni, lati bá mi jà?
4Nigbana ni Jefta kó gbogbo awọn ọkunrin Gileadi jọ, o si bá Efraimu jà: awọn ọkunrin Gileadi si kọlù Efraimu, nitoriti nwọn wipe, Isansa Efraimu li ẹnyin ara Gileadi iṣe, lãrin Efraimu, ati lãrin Manasse,
5Awọn ara Gileadi si gbà iwọdo Jordani ṣiwaju Efraimu: o si ṣe, nigbati awọn isansa Efraimu ba wipe, Jẹ ki emi ki o rekọja, awọn ọkunrin Gileadi a si wi fun u pe, Efraimu ki iwọ iṣe? Bi on ba si wipe, Rárá o!
6Nwọn a si wi fun u pe, Njẹ wi pe Ṣibboleti; on si wi pe Sibboleti, nitoripe on kò le pè e rere; nwọn a si mú u, nwọn a si pa a si iwọdo Jordani: awọn ti o si ṣubu li akokò na ninu awọn Efraimu jẹ́ ẹgbã mọkanlelogun enia.
7Jefta si ṣe idajọ Israeli li ọdún mẹfa. Jefta ara Gileadi si kú, a si sin i si ọ̀kan ninu awọn ilú Gileadi.
Ibsani, Elonii ati Abdoni
8Lẹhin rẹ̀ ni Ibsani ara Beti-lehemu ṣe idajọ Israeli.
9O si lí ọgbọ̀n ọmọkunrin, ati ọgbọ̀n ọmọbinrin ti on rán lọ si ode, o si fẹ́ ọgbọ̀n ọmọbinrin lati ode wá fi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀. On si ṣe idajọ Israeli li ọdún meje.
10Ibsani si kú, a si sin i ni Beti-lehemu.
11Lẹhin rẹ̀ ni Eloni ti ẹ̀ya Sebuluni ṣe idajọ Israeli; on si ṣe idajọ Israeli li ọdún mẹwa.
12Eloni ti ẹ̀ya Sebuluni si kú, a si sin i ni Aijaloni ni ilẹ Sebuluni.
13Lẹhin rẹ̀ ni Abdoni ọmọ Hilleli, ti Piratoni, ṣe idajọ Israeli.
14On si lí ogoji ọmọkunrin, ati ọgbọ̀n ọmọ ọmọ ti ngùn ãdọrin ọmọ kẹtẹkẹtẹ: on si ṣe idajọ Israeli li ọdún mẹjọ.
15Abdoni ọmọ Hilleli ti Piratoni si kú, a si sin i ni Piratoni ni ilẹ Efraimu, li òke awọn Amaleki.

Currently Selected:

A. Oni 12: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in