A. Oni 17
17
Ère Mika
1ỌKUNRIN kan si wà ni ilẹ òke Efraimu, orukọ ẹniti ijẹ Mika.
2On si wi fun iya rẹ̀ pe, Ẹdẹgbẹfa owo fadakà ti a kólọ lọwọ rẹ, nitori eyiti iwọ gegún, ti iwọ si sọ̀rọ rẹ̀ li etí mi pẹlu, kiyesi i, fadakà na wà li ọwọ́ mi; emi li o kó o. Iya rẹ̀ si wipe, Alabukún ti OLUWA ni ọmọ mi.
3On si kó ẹdẹgbẹfa owo fadakà na fun iya rẹ̀ pada, iya rẹ̀ si wipe, Patapata ni mo yà fadakà wọnni sọ̀tọ fun OLUWA kuro li ọwọ́ mi, fun ọmọ mi, lati fi ṣe ere fifin ati ere didà: njẹ nitorina emi o fun ọ pada.
4Ṣugbọn o kó owo na pada fun iya rẹ̀; iya rẹ̀ si mú igba owo fadakà, o si fi i fun oniṣọnà, ẹniti o fi i ṣe ere fifin ati ere didà: o si wà ni ile Mika.
5Ọkunrin na Mika si ní ile-oriṣa kan, o si ṣe efodu, ati terafimu, o si yà ọkan ninu awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin sọtọ̀, ẹniti o si wa di alufa rẹ̀.
6Li ọjọ́ wọnni ọba kan kò sí ni Israeli: olukuluku enia nṣe eyiti o tọ́ li oju ara rẹ̀.
7Ọmọkunrin kan si ti Beti-lehemu-juda wá, ti iṣe idile Juda, ẹniti iṣe ẹ̀ya Lefi, on si ṣe atipo nibẹ̀.
8Ọkunrin na si ti ilu Beti-lehemu-juda lọ, lati ṣe atipo nibikibi ti o ba ri: on si dé ilẹ òke Efraimu si ile Mika, bi o ti nlọ.
9Mika si wi fun u pe, Nibo ni iwọ ti wá? On si wi fun u pe, Ẹ̀ya Lefi ti Beti-lehemu-juda li emi iṣe, emi si nlọ ṣe atipo nibikibi ti emi ba ri.
10Mika si wi fun u pe, Bá mi joko, ki iwọ ki o ma ṣe baba ati alufa fun mi, emi o ma fi owo fadakà mẹwa fun ọ li ọdún, adápe aṣọ kan, ati onjẹ rẹ. Bẹ̃ni ọmọ Lefi na si wọle.
11O si rọ̀ ọmọ Lefi na lọrùn lati bá ọkunrin na joko; ọmọkunrin na si wà lọdọ rẹ̀ bi ọkan ninu awọn ọmọ rẹ̀.
12Mika si yà ọmọ Lefi na sọ̀tọ, ọmọkunrin na si wa di alufa rẹ̀, o si wà ninu ile Mika.
13Mika si wipe, Njẹ nisisiyi li emi tó mọ̀ pe, OLUWA yio ṣe mi li ore, nitoriti emi li ọmọ Lefi kan li alufa mi.
Currently Selected:
A. Oni 17: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: