Joh 12
12
Maria Tú Òróró Dà Sára Jesu ní Bẹtani
(Mat 26:6-13; Mak 14:3-9)
1NITORINA nigbati ajọ irekọja kù ijọ mẹfa, Jesu wá si Betani, nibiti Lasaru wà, ẹniti o ti kú, ti Jesu ji dide kuro ninu okú.
2Nwọn si se ase-alẹ fun u nibẹ: Marta si nṣe iranṣẹ: ṣugbọn Lasaru jẹ ọkan ninu awọn ti o joko nibi tabili pẹlu rẹ̀.
3Nigbana ni Maria mu ororo ikunra nardi, oṣuwọn litra kan, ailabùla, olowo iyebiye, o si nfi kùn Jesu li ẹsẹ, o si nfi irun ori rẹ̀ nù ẹsẹ rẹ̀ nù: ile si kún fun õrùn ikunra na.
4Nigbana li ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni, ẹniti yio fi i hàn, wipe,
5Ẽṣe ti a kò tà ororo ikunra yi ni ọ̃durun owo idẹ ki a si fifun awọn talakà?
6Ṣugbọn o wi eyi, ki iṣe nitoriti o náni awọn talakà; ṣugbọn nitoriti iṣe olè, on li o si ni àpo, a si ma gbé ohun ti a fi sinu rẹ̀.
7Nigbana ni Jesu wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀, o ṣe e silẹ dè ọjọ sisinku mi.
8 Nigbagbogbo li ẹnyin sá ni talakà pẹlu nyin; ṣugbọn emi li ẹ kò ni nigbagbogbo.
Ọ̀tẹ̀ láti Pa Lasaru
9Nitorina ijọ enia ninu awọn Ju li o mọ̀ pe o wà nibẹ̀: nwọn si wá, kì iṣe nitori Jesu nikan, ṣugbọn ki nwọn le ri Lasaru pẹlu, ẹniti o ti jí dide kuro ninu okú.
10Ṣugbọn awọn olori alufa gbìmọ ki nwọn le pa Lasaru pẹlu;
11Nitoripe nipasẹ rẹ̀ li ọ̀pọ ninu awọn Ju jade lọ, nwọn si gbà Jesu gbọ́.
Jesu Wọ Jerusalẹmu Pẹlu Ẹ̀yẹ
(Mat 21:1-11; Mak 11:1-11; Luk 19:28-40)
12Ni ijọ keji nigbati ọ̀pọ enia ti o wá si ajọ gbọ́ pe, Jesu mbọ̀ wá si Jerusalemu,
13Nwọn mu imọ̀-ọ̀pẹ, nwọn si jade lọ ipade rẹ̀, nwọn si nkigbe pe, Hosanna: Olubukun li ẹniti mbọ̀wá li orukọ Oluwa, Ọba Israeli.
14Nigbati Jesu si ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan, o gùn u; gẹgẹ bi a ti kọwe pe,
15Má bẹ̀ru, ọmọbinrin Sioni: wo o, Ọba rẹ mbọ̀ wá, o joko lori ọmọ kẹtẹkẹtẹ.
16Nkan wọnyi kò tète yé awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: ṣugbọn nigbati a ṣe Jesu logo, nigbana ni nwọn ranti pe, a kọwe nkan wọnyi niti rẹ̀, ati pe, on ni nwọn ṣe nkan wọnyi si.
17Nitorina ijọ enia ti o wà lọdọ rẹ̀, nigbati o pè Lasaru jade ninu iboji rẹ̀, ti o si jí i dide kuro ninu okú, nwọn jẹri.
18Nitori eyi ni ijọ enia si ṣe lọ ipade rẹ̀, nitoriti nwọn gbọ́ pe o ti ṣe iṣẹ àmi yi.
19Nitorina awọn Farisi wi fun ara wọn pe, Ẹ kiyesi bi ẹ kò ti le bori li ohunkohun? ẹ wò bi gbogbo aiye ti nwọ́ tọ̀ ọ.
Àwọn Hellene Fẹ́ Rí Jesu
20Awọn Hellene kan si wà ninu awọn ti o gòke wá lati sìn nigba ajọ:
21Awọn wọnyi li o tọ̀ Filippi wá, ẹniti iṣe ará Betsaida ti Galili, nwọn si mbère lọwọ rẹ̀, wipe, Alàgba, awa nfẹ ri Jesu.
22Filippi wá, o si sọ fun Anderu; Anderu ati Filippi wá, nwọn si sọ fun Jesu.
23Jesu si da wọn lohùn wipe, Wakati na de, ti a o ṣe Ọmọ-enia logo.
24 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bikoṣepe wóro alikama ba bọ́ si ilẹ̀, ti o ba si kú, o wà on nikan: ṣugbọn bi o ba kú, a si so ọ̀pọlọpọ eso.
25 Ẹniti o ba fẹ ẹmí rẹ̀ yio sọ ọ nù; ẹniti o ba si korira ẹmi rẹ̀ li aiye yi ni yio si pa a mọ́ titi fi di ìye ainipẹkun.
26 Bi ẹnikẹni ba nsìn mi, ki o ma tọ̀ mi lẹhin: ati nibiti emi ba wà, nibẹ̀ ni iranṣẹ mi yio wà pẹlu: bi ẹnikẹni ba nsìn mi, on ni Baba yio bù ọlá fun.
A Níláti Gbé Ọmọ-Eniyan Sókè
27 Nisisiyi li a npọ́n ọkàn mi loju; kili emi o si wi? Baba, gbà mi kuro ninu wakati yi: ṣugbọn nitori eyi ni mo ṣe wá si wakati yi.
28 Baba, ṣe orukọ rẹ logo. Nitorina ohùn kan ti ọrun wá, wipe, Emi ti ṣe e logo na, emi o si tún ṣe e logo.
29Nitorina ijọ enia ti o duro nibẹ̀, ti nwọn si gbọ́ ọ, wipe, Ãrá nsán: awọn ẹlomiran wipe, Angẹli kan li o mba a sọrọ.
30Jesu si dahùn wipe, Ki iṣe nitori mi li ohùn yi ṣe wá, bikoṣe nitori nyin.
31 Nisisiyi ni idajọ aiye yi de: nisisiyi li a o lé alade aiye yi jade.
32 Ati emi, bi a ba gbé mi soke kuro li aiye, emi o fà gbogbo enia sọdọ ara mi.
33Ṣugbọn o wi eyi, o nṣapẹrẹ irú ikú ti on o kú.
34Nitorina awọn ijọ enia da a lohùn wipe, Awa gbọ́ ninu ofin pe, Kristi wà titi lailai: iwọ ha ṣe wipe, A kò le ṣaima gbé Ọmọ-enia soke? Tani iṣe Ọmọ-enia yi?
35Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Nigba diẹ si i ni imọlẹ wà lãrin nyin. Ẹ mã rìn nigbati ẹnyin ni imọlẹ, ki òkunkun máṣe ba le nyin: ẹniti o ba si nrìn li òkunkun kò mọ̀ ibiti on gbé nlọ.
36 Nigbati ẹnyin ni imọlẹ, ẹ gbà imọlẹ gbọ́, ki ẹ le jẹ ọmọ imọlẹ. Nkan wọnyi ni Jesu sọ, o si jade lọ, o fi ara pamọ́ fun wọn.
Àwọn Juu Kò Gbàgbọ́
37Ṣugbọn bi o ti ṣe ọ̀pọlọpọ iṣẹ ami to bayi li oju wọn, nwọn kò gbà a gbọ́;
38Ki ọ̀rọ woli Isaiah lè ṣẹ, eyiti o sọ pe, Oluwa, tali o gbà iwasu wa gbọ́? ati tali a si fi apá Oluwa hàn fun?
39Nitori eyi ni nwọn kò fi le gbagbọ́, nitori Isaiah si tún sọ pe,
40O ti fọ́ wọn loju, o si ti se àiya wọn le; ki nwọn má ba fi oju wọn ri, ki nwọn má ba fi ọkàn wọn mọ̀, ki nwọn má ba yipada, ki emi má ba mu wọn larada.
41Nkan wọnyi ni Isaiah wi, nitori o ti ri ogo rẹ̀, o si sọ̀rọ rẹ̀.
42Sibẹ ọ̀pọ ninu awọn olori gbà a gbọ́ pẹlu; ṣugbọn nitori awọn Farisi nwọn kò jẹwọ rẹ̀, ki a má bà yọ wọn kuro ninu sinagogu:
43Nitori nwọn fẹ iyìn enia jù iyìn ti Ọlọrun lọ.
Ọ̀rọ̀ Jesu ń dá Eniyan Lẹ́jọ́
44Jesu si kigbe o si wipe, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, emi kọ li o gbàgbọ́, ṣugbọn ẹniti o rán mi.
45 Ẹniti o ba si ri mi, o ri ẹniti o rán mi.
46 Emi ni imọlẹ ti o wá si aiye, ki ẹnikẹni ti o ba gbà mi gbọ́ ki o máṣe wà li òkunkun.
47 Bi ẹnikẹni ba si gbọ́ ọ̀rọ mi, ti kò si pa wọn mọ, emi kì yio ṣe idajọ rẹ̀: nitoriti emi kò wá lati ṣe idajọ aiye, bikoṣe lati gbà aiye là.
48 Ẹniti o ba kọ̀ mi, ti kò si gbà ọ̀rọ mi, o ni ẹnikan ti nṣe idajọ rẹ̀: ọ̀rọ ti mo ti sọ, on na ni yio ṣe idajọ rẹ̀ ni igbẹhin ọjọ.
49 Nitori emi kò dá ọrọ sọ fun ara mi, ṣugbọn Baba ti o rán mi, on li o ti fun mi li aṣẹ, ohun ti emi o sọ, ati eyiti emi o wi.
50 Emi si mọ̀ pe ìye ainipẹkun li ofin rẹ̀: nitorina, ohun wọnni ti mo ba wi, gẹgẹ bi Baba ti sọ fun mi, bẹ̀ni mo wi.
Currently Selected:
Joh 12: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: