YouVersion Logo
Search Icon

Joh 21:15-17

Joh 21:15-17 YBCV

Njẹ lẹhin igbati nwọn jẹun owurọ̀ tan, Jesu wi fun Simoni Peteru pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ mi jù awọn wọnyi lọ bi? O si wi fun u pe, Bẹ̃ni Oluwa; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. O wi fun u pe, Mã bọ́ awọn ọdọ-agutan mi. O tún wi fun u nigba keji pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ mi bi? O wi fun u pe, Bẹ̃ni Oluwa; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. O wi fun u pe, Mã bọ́ awọn agutan mi. O wi fun u nigba kẹta pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹràn mi bi? Inu Peteru bajẹ, nitoriti o wi fun u nigba ẹkẹta pe, Iwọ fẹràn mi bi? O si wi fun u pe, Oluwa, iwọ mọ̀ ohun gbogbo; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. Jesu wi fun u pe, Mã bọ́ awọn agutan mi.