Luk 18
18
Òwe Nípa Opó Kan ati Onidajọ
1O si pa owe kan fun wọn nitori eyiyi pe, o yẹ ki a mã gbadura nigbagbogbo, ki a má si ṣãrẹ̀;
2Wipe, Onidajọ́ kan wà ni ilu kan, ti kò bẹ̀ru Ọlọrun, ti kò si ṣe ojusaju enia:
3 Opó kan si wà ni ilu na; o si ntọ̀ ọ wá, wipe, Gbẹsan mi lara ọtá mi.
4 Kò si ṣu si i nigba sã kan: ṣugbọn nikẹhin o wi ninu ara rẹ̀ pe, Bi emi kò tilẹ bẹ̀ru Ọlọrun, ti emi ko si ṣe ojuṣãju enia;
5 Ṣugbọn nitoriti opó yi nyọ mi lẹnu, emi o gbẹsan rẹ̀, ki o má ba fi wíwa rẹ̀ nigbakugba da mi lagãra.
6Oluwa si wipe, Ẹ gbọ́ bi alaiṣõtọ onidajọ ti wi.
7 Ọlọrun kì yio ha si gbẹsan awọn ayanfẹ rẹ̀, ti nfi ọsán ati oru kigbe pè e, ti o si mu suru fun wọn?
8 Mo wi fun nyin, yio gbẹsan wọn kánkán. Ṣugbọn nigbati Ọmọ-enia ba de yio ha ri igbagbọ́ li aiye?
Òwe Nípa Farisi Kan ati Agbowó-odè
9O si pa owe yi fun awọn kan ti nwọn gbẹkẹle ara wọn pe, awọn li olododo, ti nwọn si ngàn awọn ẹlomiran:
10Pe, Awọn ọkunrin meji goke lọ si tẹmpili lati gbadura; ọkan jẹ Farisi, ekeji si jẹ agbowode.
11 Eyi Farisi dide, o si ngbadura ninu ara rẹ̀ bayi pe, Ọlọrun, mo dupẹ lọwọ rẹ, nitoriti emi kò ri bi awọn ara iyokù, awọn alọnilọwọgba, alaiṣõtọ, panṣaga, tabi emi kò tilẹ ri bi agbowode yi.
12 Emi ngbàwẹ li ẹrinmeji li ọ̀sẹ, mo nsan idamẹwa ohun gbogbo ti mo ni.
13 Ṣugbọn agbowode duro li òkere, kò tilẹ jẹ gbé oju rẹ̀ soke ọrun, ṣugbọn o lù ara rẹ̀ li õkan-àiya, o wipe, Ọlọrun ṣãnu fun mi, emi ẹlẹṣẹ.
14 Mo wi fun nyin, ọkunrin yi sọkalẹ lọ si ile rẹ̀ ni idalare jù ekeji lọ: nitori ẹnikẹni ti o ba gbé ara rẹ̀ ga, on li a o rẹ̀ silẹ; ẹniti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ on li a o gbéga.
Jesu Súre fún Àwọn Ọmọde
(Mat 19:13-15; Mak 10:13-16)
15Nwọn si gbé awọn ọmọ-ọwọ tọ̀ ọ wá pẹlu, ki o le fi ọwọ́ le wọn; ṣugbọn nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ri i, nwọn mba wọn wi.
16Ṣugbọn Jesu pè wọn sọdọ rẹ̀, o si wipe, Ẹ jẹ ki awọn ọmọ kekere wá sọdọ mi, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun: nitoriti irú wọn ni ijọba Ọlọrun.
17 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti kò ba gbà ijọba Ọlọrun bi ọmọ kekere, kì yio wọ̀ inu rẹ̀ bi o ti wù ki o ri.
18Ijoye kan si bère lọwọ rẹ̀, wipe, Olukọni rere, kili emi o ṣe ti emi o fi jogún iye ainipẹkun?
19Jesu si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi npè mi li ẹni rere? ẹni rere kan kò si, bikoṣe ẹnikan, eyini li Ọlọrun.
20 Iwọ mọ̀ ofin wọnni, Máṣe ṣe panṣaga, máṣe pania, máṣe jale, máṣe jẹri eke, bọ̀wọ fun baba on iya rẹ.
21O si wipe, Gbogbo nkan wọnyi li emi ti pamọ lati igba ewe mi wá.
22Nigbati Jesu si gbọ́ eyi, o wi fun u pe, Ohun kan li o kù fun ọ sibẹ: lọ ità ohun gbogbo ti o ni, ki o si pín i fun awọn talakà, iwọ o si ni iṣura li ọrun: si wá, ki o mã tọ̀ mi lẹhin.
23Nigbati o si gbọ́ eyi, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi: nitoriti o li ọrọ̀ pipo.
24Nigbati Jesu ri i pe, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi, o ni, Yio ti ṣoro to fun awọn ti o li ọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun!
25 Nitori o rọrun fun ibakasiẹ lati gbà oju abẹrẹ wọle, jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ.
26Awọn ti o si gbọ́ wipe, Njẹ tali o ha le là?
27O si wipe, Ohun ti o ṣoro lọdọ enia, kò ṣoro lọdọ Ọlọrun.
28Peteru si wipe, Sawõ, awa ti fi tiwa silẹ, a si tọ̀ ọ lẹhin.
29O si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Kò si ẹniti o fi ile, tabi aya, tabi ará, tabi õbi, tabi ọmọ silẹ, nitori ijọba Ọlọrun,
30 Ti kì yio gba ilọpo pipọ si i li aiye yi, ati li aiye ti mbọ̀ ìye ainipẹkun.
Jesu Tún Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀ Lẹẹkẹta
(Mat 20:17-19; Mak 10:32-34)
31Nigbana li o pè awọn mejila sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Sawõ, awa ngòke lọ si Jerusalemu, a o si mu ohun gbogbo ṣẹ, ti a ti kọ lati ọwọ́ awọn woli wá, nitori Ọmọ-enia.
32 Nitori a o fi i le awọn Keferi lọwọ, a o fi i ṣe ẹlẹyà, a o si fi i ṣe ẹsin, a o si tutọ́ si i lara:
33 Nwọn o si nà a, nwọn o si pa a: ni ijọ kẹta yio si jinde.
34Ọkan ninu nkan wọnyi kò si yé wọn: ọ̀rọ yi si pamọ́ fun wọn, bẹ̃ni nwọn ko si mọ̀ ohun ti a wi.
Jesu Wo Afọ́jú Alágbe Sàn Ní Jẹriko
(Mat 20:29-34; Mak 10:46-52)
35O si ṣe, bi on ti sunmọ Jeriko, afọju kan joko lẹba ọ̀na o nṣagbe:
36Nigbati o gbọ́ ti ọpọ́ enia nkọja lọ, o bère pe, kili ã le mọ̀ eyi si.
37Nwọn si wi fun u pe, Jesu ti Nasareti li o nkọja lọ.
38O si kigbe pe, Jesu, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi.
39Awọn ti nlọ niwaju ba a wi pe, ki o pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣugbọn on si kigbe si i kunkun pe, Iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi.
40Jesu si dẹṣẹ duro, o ni, ki a mu u tọ̀ on wá: nigbati o si sunmọ ọ, o bi i,
41Wipe, Kini iwọ nfẹ ti emi iba ṣe fun o? O si wipe, Oluwa, ki emi ki o le riran.
42Jesu si wi fun u pe, Riran: igbagbọ́ rẹ gbà ọ là.
43Lojukanna o si riran, o si ntọ̀ ọ lẹhin, o nyìn Ọlọrun logo: ati gbogbo enia nigbati nwọn ri i, nwọn fi iyìn fun Ọlọrun.
Currently Selected:
Luk 18: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: