Luk 20
20
Ìbéèrè Nípa Àṣẹ Tí Jesu Ń Lò
(Mat 21:23-27; Mak 11:27-33)
1O si ṣe, ni ijọ kan li ọjọ wọnni, bi o ti nkọ́ awọn enia ni tẹmpili ti o si nwasu ihinrere, awọn olori alufa, ati awọn pẹlu awọn agbagbà dide sí i,
2Nwọn si wi fun u pe, Sọ fun wa, aṣẹ wo ni iwọ fi nṣe nkan wọnyi? tabi tali o fun ọ li aṣẹ yi?
3O si dahùn o si wi fun wọn pe, Emi pẹlu yio si bi nyin lẽre ọ̀rọ kan; ẹ sọ fun mi.
4 Baptismu ti Johanu, lati ọrun wá ni tabi lọdọ enia?
5Nwọn si ba ara wọn gbèro wipe, Bi awa ba wipe, Lati ọrun wá ni; on o wipe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi gbà a gbọ́?
6Ṣugbọn bi awa ba si wipe, Lati ọdọ enia; gbogbo enia ni yio sọ wa li okuta; nitori nwọn gbagbọ pe, woli ni Johanu.
7Nwọn si dahùn wipe, nwọn kò mọ̀ ibiti o ti wá.
8Jesu si wi fun wọn pe, Njẹ emi ki yio wi fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi.
Òwe Àwọn Alágbàro Kan ati Ọgbà Àjàrà
(Mat 21:33-46; Mak 12:1-12)
9Nigbana li o bẹ̀rẹ si ipa owe yi fun awọn enia pe: Ọkunrin kan gbìn ọgba ajara kan, o si fi ṣe agbatọju fun awọn àgbẹ, o si lọ si àjo fun igba pipẹ.
10 Nigbati o si di akokò, o rán ọmọ-ọdọ rẹ̀ kan si awọn àgbẹ na, ki nwọn ki o le fun u ninu eso ọgba ajara na: ṣugbọn awọn àgbẹ lù u, nwọn si rán a pada lọwọ ofo.
11 O si tún rán ọmọ-ọdọ miran: nwọn si lù u pẹlu, nwọn si jẹ ẹ nìya, nwọn si rán a pada lọwọ ofo.
12 O si tún rán ẹkẹta: nwọn si ṣá a lọgbẹ pẹlu, nwọn si tì i jade.
13 Nigbana li oluwa ọgba ajara wipe, Ewo li emi o ṣe? emi o rán ọmọ mi ayanfẹ lọ: bọya nigbati nwọn ba ri i, nwọn o ṣojuṣaju fun u.
14 Ṣugbọn nigbati awọn àgbẹ na ri i, nwọn ba ara wọn gbèro pe, Eyi li arole: ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki ogún rẹ̀ ki o le jẹ ti wa.
15 Bẹ̃ni nwọn si ti i jade sẹhin ọgba ajara, nwọn si pa a. Njẹ kili oluwa ọgba ajara na yio ṣe si wọn?
16 Yio wá, yio si pa awọn àgbẹ wọnni run, yio si fi ọgba ajara na fun awọn ẹlomiran. Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn ni, Ki a má rí i.
17Nigbati o si wò wọn, o ni, Ewo ha li eyi ti a ti kọwe pe, Okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ, on na li a sọ di pàtaki igun ile?
18 Ẹnikẹni ti o ba ṣubu lù okuta na yio fọ́; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ṣubu lù, yio lọ̀ ọ lulú.
19Awọn olori alufa ati awọn akọwe nwá ọna ati mu u ni wakati na; ṣugbọn nwọn bẹ̀ru awọn enia: nitoriti nwọn mọ̀ pe, o pa owe yi mọ wọn.
Owó-Orí fún Kesari
(Mat 22:15-22; Mak 12:13-17)
20Nwọn si nṣọ ọ, nwọn si rán awọn amí ti nwọn jẹ ẹlẹtan fi ara wọn pe olõtọ enia, ki nwọn ki o le gbá ọ̀rọ rẹ̀ mu, ki nwọn ki o le fi i le agbara ati aṣẹ Bãlẹ.
21Nwọn si bi i, wipe, Olukọni, awa mọ̀ pe, iwọ a ma sọrọ fun ni, iwọ a si ma kọ́-ni bi o ti tọ, bẹ̃ni iwọ kì iṣojuṣaju ẹnikan ṣugbọn iwọ nkọ́-ni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ.
22O tọ́ fun wa lati mã san owode fun Kesari, tabi kò tọ́?
23Ṣugbọn o kiyesi arekereke wọn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò?
24 Ẹ fi owo-idẹ kan hàn mi. Aworan ati akọle ti tani wà nibẹ? Nwọn si da a lohùn pe, Ti Kesari ni.
25O si wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun.
26Nwọn kò si le gbá ọ̀rọ rẹ̀ mu niwaju awọn enia: ẹnu si yà wọn si idahùn rẹ̀, nwọn si pa ẹnu wọn mọ́.
Ìbéèrè nípa Ajinde Òkú
(Mat 22:23-33; Mak 12:18-27)
27Awọn Sadusi kan si tọ̀ ọ wá, awọn ti nwọn nwipe ajinde okú kò si: nwọn si bi i,
28Wipe, Olukọni, Mose kọwe fun wa pe, Bi arakunrin ẹnikan ba kú, li ailọmọ, ti o li aya, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o le gbe iru dide fun arakunrin rẹ̀.
29Njẹ awọn arakunrin meje kan ti wà: ekini gbé iyawo, o si kú li ailọmọ.
30Ekeji si ṣu u lopó, on si kú li ailọmọ.
31Ẹkẹta si ṣu u lopó; gẹgẹ bẹ̃ si li awọn mejeje pẹlu: nwọn kò si fi ọmọ silẹ, nwọn si kú.
32Nikẹhin gbogbo wọn, obinrin na kú pẹlu.
33Njẹ li ajinde okú, aya titani yio ha ṣe ninu wọn? nitori awọn mejeje li o sá ni i li aya.
34Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Awọn ọmọ aiye yi a ma gbeyawo, nwọn a si ma fà iyawo fun-ni.
35 Ṣugbọn awọn ti a kà yẹ lati jogún aiye na, ati ajinde kuro ninu okú, nwọn kì igbeyawo, nwọn kì si ifà iyawo fun-ni:
36 Nitori nwọn kò le kú mọ́; nitoriti nwọn ba awọn angẹli dọgba; awọn ọmọ Ọlọrun si ni nwọn, nitori nwọn di awọn ọmọ ajinde.
37 Niti pe a njí awọn okú dide, Mose tikararẹ̀ si ti fihàn ni igbẹ́, nigbati o pè Oluwa ni Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu.
38 Bẹni on kì iṣe Ọlọrun awọn okú, bikoṣe ti awọn alãye: nitori gbogbo wọn wà lãye fun u.
39Nigbana li awọn kan ninu awọn akọwe da a lohùn, wipe, Olukọni iwọ wi rere.
40Nwọn kò si jẹ bi i lẽre òrọ kan mọ́.
Ìbéèrè Nípa Ọmọ Dafidi
(Mat 22:41-46; Mak 12:35-37)
41O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti nwọn fi nwipe, Ọmọ Dafidi ni Kristi?
42 Dafidi tikararẹ̀ si wi ninu iwe Psalmu pe, OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi,
43 Titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ.
44 Njẹ bi Dafidi ba pè e li Oluwa; on ha si ti ṣe jẹ ọmọ rẹ̀?
Jesu Bá Àwọn Akọ̀wé Wí
(Mat 23:1-36; Mak 12:38-40)
45O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ li etí gbogbo enia pe,
46 Ẹ mã kiyesara lọdọ awọn akọwe, ti nwọn fẹ lati mã rìn li aṣọ gigùn, ti nwọn si fẹ ikí-ni li ọjà, ati ibujoko ọlá ninu sinagogu, ati ipò ọla ni ibi àse;
47 Awọn ti o jẹ ile awọn opó run, ti nwọn si ngbadura gìgun fun aṣehàn: awọn wọnyi na ni yio jẹbi pọ̀ju.
Currently Selected:
Luk 20: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: