Luk 7
7
Jesu Wo Ọmọ Ọ̀dọ̀ Balogun Sàn
(Mat 8:5-13)
1NIGBATI o si pari gbogbo ọ̀rọ rẹ̀ li eti awọn enia, o wọ̀ Kapernaumu lọ.
2Ọmọ-ọdọ balogun ọrún kan, ti o ṣọwọn fun u, o ṣaisàn, o nkú lọ.
3Nigbati o si gburó Jesu, o rán awọn agbagba Ju si i, o mbẹ̀ ẹ pe, ki o máṣai wá mu ọmọ-ọdọ on larada.
4Nigbati nwọn si de ọdọ Jesu, nwọn fi itara bẹ̀ ẹ, wipe, O yẹ li ẹniti on iba ṣe eyi fun:
5Nitoriti o fẹran orilẹ-ede wa, o si ti kọ́ sinagogu kan fun wa.
6Jesu si mba wọn lọ. Nigbati kò si jìn si eti ile mọ́, balogun ọrún na rán awọn ọrẹ́ si i, wipe, Oluwa, má yọ ara rẹ lẹnu: nitoriti emi kò to ti iwọ iba fi wọ̀ abẹ orule mi:
7Nitorina emi kò si rò pe emi na yẹ lati tọ̀ ọ wá: ṣugbọn sọ ni gbolohùn kan, a o si mu ọmọ-ọdọ mi larada.
8Nitori emi na pẹlu jẹ ẹniti a fi si abẹ aṣẹ, ti o li ọmọ-ogun li ẹhin mi, mo wi fun ọkan pe, Lọ, a si lọ; ati fun omiran pe, Wá, a si wá; ati fun ọmọ-ọdọ mi pe, Ṣe eyi, a si ṣe e.
9Nigbati Jesu gbọ́ nkan wọnni, ẹnu yà a si i, o si yipada si ijọ enia ti ntọ̀ ọ lẹhin, o wipe, Mo wi fun nyin, emi kò ri irú igbagbọ́ nla bi eyi ninu awọn enia Israeli.
10Nigbati awọn onṣẹ si pada rè ile, nwọn ba ọmọ-ọdọ na ti nṣaisàn, ara rẹ̀ ti da.
Jesu Jí Ọmọ Opó Kan Dìde Ní Naini
11O si ṣe ni ijọ keji, o lọ sí ilu kan ti a npè ni Naini; awọn pipọ ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si mba a lọ ati ọ̀pọ ijọ enia.
12Bi o si ti sunmọ ẹnu bode ilu na, si kiyesi i, nwọn ngbé okú kan jade, ọmọ kanṣoṣo na ti iya rẹ̀, o si jẹ opó: ọ̀pọ ijọ enia ilu na si wà pẹlu rẹ̀.
13Nigbati Oluwa si ri i, ãnu rẹ̀ ṣe e, o si wi fun u pe, Má sọkun mọ́.
14O si wá, o si fi ọwọ́ tọ́ aga posi na: awọn ti si nrù u duro jẹ. O si wipe, Ọdọmọkunrin, mo wi fun ọ, Dide.
15Ẹniti o kú na si dide joko, o bẹ̀rẹ si ohùn ifọ̀. O si fà a le iya rẹ̀ lọwọ.
16Ẹ̀rù si ba gbogbo wọn: nwọn si nyìn Ọlọrun logo, wipe, Woli nla dide ninu wa; ati pe, Ọlọrun si wa ibẹ̀ awọn enia rẹ̀ wò.
17Okikí rẹ̀ si kàn ni gbogbo Judea, ati gbogbo àgbegbe ti o yiká.
Johanu Ranṣẹ Sí Jesu
(Mat 11:2-19)
18Awọn ọmọ-ẹhin Johanu si fi ninu gbogbo nkan wọnyi hàn fun u.
19Nigbati Johanu si pè awọn meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o rán wọn sọdọ Jesu, wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a ma reti ẹlomiran?
20Nigbati awọn ọkunrin na si de ọdọ rẹ̀, nwọn ni, Johanu Baptisti rán wa sọdọ rẹ, wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a ma reti ẹlomiran?
21Ni wakati na, o si ṣe dida ara ọpọlọpọ enia ninu aisan, ati arun, ati ẹmi buburu; o si fi iriran fun ọpọlọpọ awọn afọju.
22Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ, ẹ ròhin nkan ti ẹnyin ri, ti ẹnyin si gbọ́ fun Johanu: awọn afọju nriran, awọn amukun nrìn ṣaṣa, a sọ awọn adẹtẹ̀ di mimọ́, awọn aditi ngbọran, a njí awọn okú dide, ati fun awọn òtoṣi li a nwasu ihinrere.
23 Alabukun-fun si li ẹnikẹni ti ki yio kọsẹ̀ lara mi.
24Nigbati awọn onṣẹ Johanu pada lọ, o bẹ̀rẹ si isọ fun ijọ enia niti Johanu pe, Kili ẹnyin jade rè ijù lọ iwò? ifefe ti afẹfẹ nmì?
25 Ṣugbọn kili ẹnyin jade lọ iwò? ọkunrin ti a wọ̀ li aṣọ fẹlẹfẹlẹ? wò o, awọn ti a wọ̀ li aṣọ ogo, ti nwọn si njaiye, mbẹ li afin ọba.
26 Ṣugbọn kili ẹnyin jade lọ iwò? woli? lõtọ ni mo wi fun nyin, o si jù woli lọ.
27 Eyiyi li ẹniti a ti kọwe nitori rẹ̀ pe, Wò o, mo rán onṣẹ mi siwaju rẹ, ẹniti yio tún ọ̀na rẹ ṣe niwaju rẹ.
28 Mo wi fun nyin, ninu awọn ti a bí ninu obinrin, kò si woli ti o pọ̀ju Johanu Baptisti lọ: ṣugbọn ẹniti o kerejulọ ni ijọba Ọlọrun, o pọ̀ju u lọ.
29Gbogbo awọn enia ti o gbọ́ ati awọn agbowode, nwọn da Ọlọrun lare, nitori a ti fi baptismu Johanu baptisi wọn.
30Ṣugbọn awọn Farisi ati awọn amofin kọ ìmọ Ọlọrun fun ara wọn, a kò baptisi wọn lọdọ rẹ̀.
31Oluwa si wipe, Kili emi iba fi awọn enia iran yi wé? kini nwọn si jọ?
32 Nwọn dabi awọn ọmọ kekere ti o joko ni ibi ọjà, ti nwọn si nkọ si ara wọn, ti nwọn si nwipe, Awa fùn fère fun nyin, ẹnyin kò jó; awa si ṣọ̀fọ fun nyin, ẹnyin kò sọkun.
33 Nitori Johanu Baptisti wá, kò jẹ akara, bẹ̃ni kò si mu ọti-waini; ẹnyin si wipe, O li ẹmi èṣu.
34 Ọmọ-enia de, o njẹ, o si nmu; ẹnyin si wipe, Wò o, ọjẹun, ati ọmuti, ọrẹ́ awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ!
35 Ṣugbọn a da ọgbọ́n lare lati ọdọ awọn ọmọ rẹ̀ gbogbo wá.
Jesu Dárí Ji Obinrin Ẹlẹ́ṣẹ̀ Kan
36Farisi kan si rọ̀ ọ ki o wá ba on jẹun. O si wọ̀ ile Farisi na lọ o si joko lati jẹun.
37Si kiyesi i, obinrin kan wà ni ilu na, ẹniti iṣe ẹlẹṣẹ, nigbati o mọ̀ pe Jesu joko njẹun ni ile Farisi, o mu oruba alabastar ororo ikunra wá,
38O si duro tì i lẹba ẹsẹ rẹ̀ lẹhin, o nsọkun, o si bẹ̀rẹ si ifi omije wẹ̀ ẹ li ẹsẹ, o si nfi irun ori rẹ̀ nù u nù, o si nfi ẹnu kò o li ẹsẹ, o si nfi ororo kùn wọn.
39Nigbati Farisi ti o pè e si ri i, o wi ninu ara rẹ̀ pe, ọkunrin yi iba ṣe woli, iba mọ̀ ẹni ati irú ẹniti obinrin yi iṣe ti nfi ọwọ́ kan a: nitori ẹlẹṣẹ ni.
40Jesu si dahùn wi fun u pe, Simoni, Mo ni ohun kan isọ fun ọ. O si dahùn wipe, Olukọni, mã wi.
41 Onigbese kan wà ti o ni ajigbese meji: ọkan jẹ ẹ ni ẹdẹgbẹta owo idẹ, ekeji si jẹ ẹ ni adọta.
42 Nigbati nwọn kò si ni ti nwọn o san, o darijì awọn mejeji. Wi, ninu awọn mejeji tani yio fẹ ẹ jù?
43Simoni dahùn o si wipe, mo ṣebi ẹniti o darijì jù ni. O si wi fun u pe, O wi i 're.
44O si yipada si obinrin na, o wi fun Simoni pe, Iwọ ri obinrin yi? Emi wọ̀ ile rẹ, omi wiwẹ̀ ẹsẹ iwọ kò fifun mi: ṣugbọn on, omije li o fi nrọjo si mi li ẹsẹ, irun ori rẹ̀ li o fi nnù wọn nù.
45 Ifẹnukonu iwọ kò fi fun mi: ṣugbọn on, nigbati mo ti wọ̀ ile, ko dabọ̀ ẹnu ifi kò mi li ẹsẹ.
46 Iwọ kò fi oróro pa mi li ori: ṣugbọn on ti fi ororo pa mi li ẹsẹ.
47 Njẹ mo wi fun ọ, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o pọ̀ jì i; nitoriti o ni ifẹ pipọ: ẹniti a si dari diẹ jì, on na li o ni ifẹ diẹ.
48O si wi fun u pe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ.
49Awọn ti o bá a joko njẹun si bẹ̀rẹ si irò ninu ara wọn pe, Tali eyi ti ndari ẹ̀ṣẹ jì-ni pẹlu?
50O si dahùn wi fun obinrin na pe, Igbagbọ́ rẹ gbà ọ là; mã lọ li alafia.
Currently Selected:
Luk 7: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: