YouVersion Logo
Search Icon

Mak Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Gbolohun tí Ìhìn Rere Marku fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé: èyí ni àkọsílẹ̀ nípa “ìyìn rere Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun.” Marku fi Jesu hàn bí oníṣẹ́ ati aláṣẹ. Àṣẹ rẹ̀ hàn ninu ìkọ́ni rẹ̀, ati ninu agbára tí ó ní lórí àwọn ẹ̀mí èṣù. Ó sì tún hàn ninu bí ó ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan jì wọ́n. Jesu pe ara rẹ̀ ní Ọmọ-Eniyan tí ó wá láti fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ kí ó lè gba àwọn eniyan kalẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.
Gaaraga ni Marku sọ ìtàn Jesu, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì gúnni lọ́kàn. Àwọn ohun tí Jesu ṣe ni Marku tẹnumọ́ pupọ ju ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ lọ. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ iṣaaju díẹ̀ tí ó sọ nípa Johanu Onítẹ̀bọmi ati nípa ìrìbọmi ati ìdánwò Jesu, kíá ni ẹni tí ó kọ ìhìn rere yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí sọ nípa iṣẹ́ ìwòsàn ati ti ìkọ́ni tí Jesu ṣe. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́ sí i ni ohun tí Jesu ń ṣe bẹ̀rẹ̀ sí yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí i, ṣugbọn inú túbọ̀ ń bí àwọn ọ̀tá rẹ̀ sí i ni. Orí bíi mélòó kan tí ó parí ìwé yìí sọ nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ninu ọ̀sẹ̀ ìkẹyìn ìgbé-ayé Jesu, pataki jùlọ nípa ìkàn-mọ́-àgbélébùú rẹ̀ ati ajinde rẹ̀.
Ó dàbí ẹni pé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ẹni tí ó kọ ọ̀rọ̀ ìparí kinni ati ekeji tí ó wà ní ìpẹ̀kun ìwé yìí.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ìbẹ̀rẹ̀ ìhìn rere 1:1-13
Iṣẹ́ gbangba tí Jesu ṣe ní Galili 1:14—9:50
Láti Galili dé Jerusalẹmu 10:1-52
Ọ̀sẹ̀ ìkẹyìn ní ìgboro Jerusalẹmu ati ní agbègbè rẹ̀ 11:1—15:47
Ajinde Jesu 16:1-8
Ìfarahàn ati Ìgòkè-re-ọ̀run Oluwa tí ó jinde 16:9-20

Currently Selected:

Mak Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in