YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 21

21
Orin Ìṣẹ́gun
1ỌBA yio ma yọ̀ li agbara rẹ, Oluwa; ati ni igbala rẹ, yio ti yọ̀ pọ̀ to!
2Iwọ ti fi ifẹ ọkàn rẹ̀ fun u, iwọ kò si dù u ni ibère ẹnu rẹ̀.
3Nitori iwọ ti fi ibukún ore kò o li ọ̀na, iwọ fi ade kiki wura de e li ori.
4O tọrọ ẹmi lọwọ rẹ, iwọ si fi fun u, ani ọjọ gigùn lai ati lailai.
5Ogo rẹ̀ pọ̀ ni igbala rẹ: iyìn ati ọlánla ni iwọ fi si i lara.
6Nitori iwọ ti ṣe e li ẹni-ibukún fun jùlọ titi aiye: iwọ si fi oju rẹ mu u yọ̀ gidigidi.
7Nitori ti ọba gbẹkẹle Oluwa, ati nipa ãnu Ọga-ogo kì yio ṣipò pada.
8Ọwọ rẹ yio wá gbogbo awọn ọta rẹ ri: ọwọ ọtún rẹ ni yio wá awọn ti o korira rẹ ri.
9Iwọ o ṣe wọn bi ileru onina ni igba ibinu rẹ: Oluwa yio gbé wọn mì ni ibinu rẹ̀, iná na yio si jó wọn pa.
10Eso wọn ni iwọ o run kuro ni ilẹ, ati irú-ọmọ wọn kuro ninu awọn ọmọ enia.
11Nitori ti nwọn nrò ibi si ọ: nwọn ngbìro ete ìwa-ibi, ti nwọn kì yio le ṣe.
12Nitorina ni iwọ o ṣe mu wọn pẹhinda, nigbati iwọ ba fi ọfà rẹ kàn ọsán si oju wọn.
13Ki iwọ ki ó ma leke, Oluwa, li agbara rẹ; bẹ̃li awa o ma kọrin, ti awa o si ma yìn agbara rẹ.

Currently Selected:

O. Daf 21: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in