YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 80

80
Fi Ojurere Wò Wá
1FI eti si ni, Oluṣọ-agutan Israeli, iwọ ti o ndà Josefu bi ọwọ́-agutan; iwọ ti o joko lãrin awọn kerubu tàn imọlẹ jade.
2Niwaju Efraimu ati Benjamini ati Manasse rú ipa rẹ soke ki o si wá fun igbala wa.
3Tún wa yipada, Ọlọrun, ki o si mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là.
4Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, iwọ o ti binu pẹ to si adura awọn enia rẹ?
5Iwọ fi onjẹ omije bọ́ wọn; iwọ si fun wọn li omije mu li ọ̀pọlọpọ.
6Iwọ sọ wa di ijà fun awọn aladugbo wa: awọn ọta wa si nrẹrin ninu ara wọn.
7Tún wa yipada, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ki o si mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là.
8Iwọ ti mu ajara kan jade ti Egipti wá: iwọ ti tì awọn keferi jade, iwọ si gbin i.
9Iwọ ṣe àye silẹ fun u, iwọ si mu u ta gbòngbo jinlẹ̀, o si kún ilẹ na.
10A fi ojiji rẹ̀ bò awọn òke mọlẹ, ati ẹka rẹ̀ dabi igi kedari Ọlọrun.
11O yọ ẹka rẹ̀ sinu okun, ati ọwọ rẹ̀ si odò nla nì.
12Ẽṣe ti iwọ ha fi ya ọgbà rẹ̀ bẹ̃, ti gbogbo awọn ẹniti nkọja lọ li ọ̀na nká a?
13Imado lati inu igbo wá mba a jẹ, ati ẹranko igbẹ njẹ ẹ run.
14Yipada, awa mbẹ ọ, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: wolẹ lati ọrun wá, ki o si wò o, ki o si bẹ àjara yi wò:
15Ati agbala-àjara ti ọwọ ọtún rẹ ti gbin, ati ọmọ ti iwọ ti mule fun ara rẹ.
16O jona, a ke e lulẹ: nwọn ṣegbe nipa ibawi oju rẹ.
17Jẹ ki ọwọ rẹ ki o wà lara ọkunrin ọwọ ọtún rẹ nì, lara ọmọ-enia ti iwọ ti mule fun ara rẹ.
18Bẹ̃li awa kì yio pada sẹhin kuro lọdọ rẹ: mu wa yè, awa o si ma pè orukọ rẹ.
19Tún wa yipada, Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là.

Currently Selected:

O. Daf 80: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in