Rut 4
4
Boasi Ṣú Rutu Lópó
1NIGBANA ni Boasi lọ si ẹnu-bode, o si joko nibẹ̀: si kiyesi i, ibatan na ẹniti Boasi sọ̀rọ rẹ̀ nkọja; o si pe, Iwọ alamọrin! yà, ki o si joko nihin. O si yà, o si joko.
2O si mú ọkunrin mẹwa ninu awọn àgba ilu, o si wipe, Ẹ joko nihin. Nwọn si joko.
3O si wi fun ibatan na pe, Naomi, ẹniti o ti ilẹ Moabu pada wa, o ntà ilẹ kan, ti iṣe ti Elimeleki arakunrin wa:
4Mo si rò lati ṣí ọ leti rẹ̀, wipe, Rà a niwaju awọn ti o joko nihin, ati niwaju awọn àlagba awọn enia mi. Bi iwọ o ba rà a silẹ, rà a silẹ: ṣugbọn bi iwọ ki yio ba rà a silẹ, njẹ wi fun mi, ki emi ki o le mọ̀: nitoriti kò sí ẹnikan lati rà a silẹ lẹhin rẹ; emi li o si tẹle ọ. On si wipe, Emi o rà a silẹ.
5Nigbana ni Boasi wipe, Li ọjọ́ ti iwọ ba rà ilẹ na li ọwọ́ Naomi, iwọ kò le ṣe àirà a li ọwọ́ Rutu ara Moabu pẹlu, aya ẹniti o kú, lati gbé orukọ okú dide lori ilẹ-iní rẹ̀.
6Ibatan na si wipe, Emi kò le rà a silẹ fun ara mi, ki emi má ba bà ilẹ-iní mi jẹ́: iwọ rà eyiti emi iba rà silẹ; nitori emi kò le rà a.
7Iṣe wọn nigbãni ni Israeli niti ìrasilẹ, ati niti iparọ si li eyi, lati fi idí ohun gbogbo mulẹ, ẹnikini a bọ́ bàta rẹ̀, a si fi i fun ẹnikeji rẹ̀: ẹrí li eyi ni Israeli,
8Bẹ̃ni ibatan na wi fun Boasi pe, Rà a fun ara rẹ. O si bọ́ bàta rẹ̀.
9Boasi si wi fun awọn àgbagba, ati fun gbogbo awọn enia pe, Ẹnyin li elẹri li oni, pe mo rà gbogbo nkan ti iṣe ti Elimeleki, ati gbogbo nkan ti iṣe ti Kilioni, ati ti Maloni, li ọwọ́ Naomi.
10Pẹlupẹlu Rutu ara Moabu, aya Maloni ni mo rà li aya mi, lati gbé orukọ okú dide lori ilẹ-iní rẹ̀, ki orukọ okú ki o má ba run ninu awọn arakunrin rẹ̀, ati li ẹnu-bode ilu rẹ̀: ẹnyin li ẹlẹri li oni.
11Gbogbo awọn enia ti o wà li ẹnu-bode, ati awọn àgbagba, si wipe, Awa ṣe ẹlẹri. Ki OLUWA ki o ṣe obinrin na ti o wọ̀ ile rẹ bi Rakeli ati bi Lea, awọn meji ti o kọ ile Israeli: ki iwọ ki o si jasi ọlọlá ni Efrata, ki o si jasi olokikí ni Betilehemu.
12Ki ile rẹ ki o si dabi ile Peresi, ẹniti Tamari bi fun Juda, nipa irú-ọmọ ti OLUWA yio fun ọ lati ọdọ ọmọbinrin yi.
Boasi ati Ìrandíran Rẹ̀
13Boasi si mú Rutu, on si di aya rẹ̀; nigbati o si wọle tọ̀ ọ, OLUWA si mu ki o lóyun, o si bi ọmọkunrin kan.
14Awọn obinrin si wi fun Naomi pe, Olubukun li OLUWA, ti kò fi ọ silẹ li ainí ibatan li oni, ki o si jẹ́ olokikí ni Israeli.
15On o si jẹ́ olumupada ẹmi rẹ, ati olutọju ogbó rẹ: nitori aya-ọmọ rẹ, ẹniti o fẹ́ ọ, ti o san fun ọ jù ọmọkunrin meje lọ, li o bi i.
16Naomi si gbé ọmọ na, o si tẹ́ ẹ si owókan-àiya rẹ̀, o si di alagbatọ́ rẹ̀.
17Awọn obinrin aladugbo rẹ̀ si sọ ọ li orukọ, wipe, A bi ọmọkunrin kan fun Naomi; nwọn si pè orukọ rẹ̀ ni Obedi: on ni baba Jesse, baba Dafidi.
18Wọnyi ni iran Peresi: Peresi bi Hesroni;
19Hesroni si bi Ramu, Ramu si bi Amminadabu;
20Amminadabu si bi Naṣoni, Naṣoni si bi Salmoni;
21Salmoni si bi Boasi, Boasi si bi Obedi;
22Obedi si bi Jesse, Jesse si bi Dafidi.
Currently Selected:
Rut 4: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: