YouVersion Logo
Search Icon

2 Kọrinti Ìfáàrà

Ìfáàrà
Lẹ́tà Paulu àkọ́kọ́ sí àwọn ará Kọrinti kò yanjú àwọn ìṣòro tó wà láàrín wọn tán. Ó mú èso rere wá, ṣùgbọ́n ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe ṣí kù sílẹ̀. Ní pàtàkì jùlọ, Paulu ní láti yanjú ìṣòro tó jẹ mọ́ àṣẹ tí ó ń lò. Àwọn ara Kọrinti sì ń ṣe iyèméjì lórí Paulu ṣùgbọ́n Paulu kọ̀wé pẹ̀lú ìtara láti fi ìdí agbára àti àṣẹ tí ó ní gẹ́gẹ́ bí aposteli múlẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Ó ṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn Kristi ní ibòmíràn tí wọ́n jẹ́ aláìní.
A rí ayọ̀ ìborí ìṣòro láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin ìwé yìí. A lè pè é ní lẹ́tà Paulu sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá sí. Bí Paulu ṣe ń sọ nípa wàhálà tí ó rí, àwọn ìyọrísí nínú iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristiani láti rí i bí agbára Ọlọ́run ṣe ń ṣiṣẹ́, tí ó yọ ohun rere láti inú ohun búburú. Nítòótọ́ èṣù ní agbára, ó ń wá ọ̀nà láti ba iṣẹ́ Ọlọ́run jẹ́, ṣùgbọ́n síbẹ̀ Ọlọ́run tóbi jù èṣù lọ, ó sì fi ẹsẹ̀ àwọn tó gbà á gbọ́ mulẹ̀.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Àwọn ìkíni Paulu 1.1-11.
ii. Àwọn ọ̀rọ̀ ṣókí nípa iṣẹ́ Paulu 1.12–2.13.
iii. Ìwàásù lórí ìríjú Kristiani 2.14–6.10.
iv. Àwọn àkíyèsí Paulu 6.11–7.16.
v. Ọrẹ fún aláìní Judea 8.1–9.15.
vi. Paulu sọ nípa àṣẹ tí ó ní gẹ́gẹ́ bí Aposteli 10.1–13.10.
vii. Ohun tó kíyèsi gbẹ̀yìn 13.11-14.

Currently Selected:

2 Kọrinti Ìfáàrà: YCB

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in