YouVersion Logo
Search Icon

Ìṣe àwọn Aposteli Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ẹni tó kọ ìwé yìí kò dárúkọ ara rẹ̀, ṣùgbọ́n a lè ti ipa ohun tí a rí kà tọ́ka sí Luku gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó kọ ọ́. Ìwé yìí jẹ́ ìtẹ̀síwájú ìhìnrere Luku níbi tí Luku ti fi yé wa pé ohun tí Jesu bẹ̀rẹ̀ nínú ayé náà ni ó ń ṣe nínú ìgbé ayé àwọn ọmọ Ọlọ́run. Ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìwé yìí bẹ̀rẹ̀ níbi tí àwọn aposteli ti kún fún agbára Ọlọ́run àti ìwàásù tó so èso púpọ̀, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ènìyàn ni a gbà lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ní ọjọ́ kan (2.41). Ìgbé ayé ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, ìtànkálẹ̀ ìhìnrere ní Samaria, iṣẹ́ ìhìnrere aposteli Peteru àti bí inúnibíni sí àwọn onígbàgbọ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ ni a ṣe àpèjúwe. Àkíyèsí wa darí sí orí aposteli Paulu àti iṣẹ́ ìhìnrere rẹ̀ ní àwọn ilẹ̀ tí kì í ṣe Júù. Ìrìnàjò iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni ó ní àkọsílẹ̀ kíkún, èyí tó parí pẹ̀lú ìrìnàjò rẹ sí Romu níbi tí ìwé náà parí sí.
A kọ ìwé Ìṣe àwọn Aposteli láti fi ṣe àfihàn ìtànkálẹ̀ iṣẹ́ ìhìnrere láti ọ̀dọ̀ àwọn Júù dé ilẹ̀ àwọn tí kì í ṣe Júù (1.8). Ìròyìn ayọ̀ pé Jesu kú, ó sì jí dìde yóò di mí mọ̀ ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé. Ọlọ́run gbé agbára wọ àwọn ènìyàn rẹ̀ kí wọn ba à lè ṣe iṣẹ́ wọn ní àṣeyọrí. Ẹ̀mí Mímọ́ ni agbára náà. Ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run hàn lórí ohun gbogbo, èyí tó mú iṣẹ́ ìhìnrere borí ìbọ̀rìṣà àti inúnibíni. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ni yóò torí èyí jẹ ìyà púpọ̀, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Peteru àti Paulu nínú Ìṣe àwọn Aposteli jẹ́ àpẹẹrẹ ìṣẹ́gun tó dájú ni a ṣe ìlérí láti ipasẹ̀ Jesu Ọlọ́run wa.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìjọ Ọlọ́run ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ wá 1.1–5.42.
ii. Inúnibíni àti ìtẹ̀síwájú ìhìnrere 6.1–9.32.
iii. Iṣẹ́ ìránṣẹ́ Peteru 9.32–12.25.
iv. Ìrìnàjò Paulu kìn-ín-ní 13.1–14.28.
v. Àjọ ìgbìmọ̀ Jerusalẹmu 15.1-41.
vi. Ìrìnàjò Paulu kejì 16.1–18.22.
vii. Ìrìnàjò Paulu kẹta 18.23–21.14.
viii. Fífi àṣẹ ọba mú Paulu àti ìrìnàjò lọ sí Romu 21.15–28.31.

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in