10
1Gẹ́gẹ́ bí òkú eṣinṣin tí ń fún òróró ìkunra ní òórùn búburú,
bẹ́ẹ̀ náà ni òmùgọ̀ díẹ̀ ṣe ń bo ọgbọ́n àti ọlá mọ́lẹ̀.
2Ọkàn ọlọ́gbọ́n a máa ṣí sí ohun tí ó tọ̀nà,
ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ sí ohun tí kò dára.
3Kódà bí ó ti ṣe ń rìn láàrín ọ̀nà,
òmùgọ̀ kò ní ọgbọ́n
a sì máa fihan gbogbo ènìyàn bí ó ti gọ̀ tó.
4Bí ìbínú alákòóso bá dìde lòdì sí ọ,
ma ṣe fi ààyè rẹ sílẹ̀;
ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ le è tú àṣìṣe ńlá.
5Ohun ibi kan wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn,
irú àṣìṣe tí ó dìde láti ọ̀dọ̀ alákòóso.
6A gbé aṣiwèrè sí ọ̀pọ̀ ipò tí ó ga jùlọ,
nígbà tí ọlọ́rọ̀ gba àwọn ààyè tí ó kéré jùlọ.
7Mo ti rí ẹrú lórí ẹṣin,
nígbà tí ọmọ-aládé ń fi ẹsẹ̀ rìn bí ẹrú.
8Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ó le è ṣubú sínú rẹ̀;
ẹnikẹ́ni tí ó bá la inú ògiri, ejò le è ṣán an.
9Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbe òkúta le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn;
ẹnikẹ́ni tí ó bá la ìtì igi le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn.
10Bí àáké bá kú
tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kò sì sí ní pípọ́n;
yóò nílò agbára púpọ̀
ṣùgbọ́n ọgbọ́n orí ni yóò mú àṣeyọrí wá.
11Bí ejò bá ṣán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀,
kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀.
12Ọ̀rọ̀ tí ó wá láti ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa ní oore-ọ̀fẹ́
ṣùgbọ́n ètè òmùgọ̀ fúnrarẹ̀ ni yóò parun.
13Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀;
ìparí rẹ̀ sì jẹ́ ìsínwín búburú.
14Wèrè a sì máa ṣàfikún ọ̀rọ̀.
Kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ó ń bọ̀
ta ni ó le è sọ fún un ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀?
15Iṣẹ́ aṣiwèrè a máa dá a lágara
kò sì mọ ojú ọ̀nà sí ìlú.
16Ègbé ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ tí ọba ń ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀
àti tí àwọn ọmọ-aládé ń ṣe àsè ní òwúrọ̀.
17Ìbùkún ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ èyí tí ọba rẹ̀ jẹ́
ọmọ ọlọ́lá, àti tí àwọn ọmọ-aládé ń jẹun ní àsìkò tí ó yẹ,
fún ìlera, tí kì í ṣe fún ìmutípara.
18Bí ènìyàn bá ń lọ́ra, àjà ilé a máa jì
bí ọwọ́ rẹ̀ bá ń ṣe ọ̀lẹ, ilé a máa jó.
19Ẹ̀rín rínrín ni a ṣe àsè fún,
wáìnì a máa mú ayé dùn,
ṣùgbọ́n owó ni ìdáhùn sí ohun gbogbo.
20Ma ṣe bú ọba, kódà nínú èrò rẹ,
tàbí kí o ṣépè fún ọlọ́rọ̀ ní ibi ibùsùn rẹ,
nítorí pé ẹyẹ ojú ọ̀run le è gbé ọ̀rọ̀ rẹ
ẹyẹ tí ó sì ní ìyẹ́ apá le è fi ẹjọ́ ohun tí o sọ sùn.