YouVersion Logo
Search Icon

Esteri 4:13-14

Esteri 4:13-14 YCB

Nígbà náà ni Mordekai sọ kí a dá Esteri lóhùn pé; “Má ṣe rò nínú ara rẹ pé nítorí pé ìwọ wà ní ilé ọba ìwọ nìkan là láàrín gbogbo àwọn Júù. Nítorí bí ìwọ bá dákẹ́ ní àkókò yìí, ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ fún àwọn Júù yóò dìde láti ibòmíràn, ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ìdílé baba à rẹ yóò ṣègbé. Ta ni ó mọ̀ wí pé nítorí irú àkókò yìí ni o ṣe wà ní ipò ayaba?”