YouVersion Logo
Search Icon

Matiu Ìfáàrà

Ìfáàrà
Matiu jẹ́ agbowó òde, Jesu pè é kí ó tẹ̀lé òun ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìhìnrere ìta gbangba rẹ̀. Nítorí náà, ó jẹ́ ẹlẹ́rìí ìbí Jesu láti inú Maria wúńdíá ìtẹ̀bọmi rẹ̀ àti ìdánwò rẹ̀ nínú aginjù. Jesu wá wàásù ìjọba Ọlọ́run tó jẹ́ ọ̀nà sí ìyè àìnípẹ̀kun, èyí tí a le ní nípa ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Matiu ṣe àkójọpọ̀ gbogbo ìkọ́ni Jesu nínú àkòrí ọ̀rọ̀ márùn-ún nínú èyí ti a ti le rí ẹ̀kọ́ ìwà rere, ìkéde, àkàwé, ìdàpọ̀ àti ìjọba. Ikú àti àjíǹde Jesu ni òpin ìhìnrere náà pẹ̀lú ìpàṣẹ láti lọ sínú ayé pẹ̀lú ìhìnrere Jesu Kristi.
Ète Matiu nípa kíkọ ìhìnrere rẹ̀ ni láti fihàn pé Jesu ṣe ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run nínú májẹ̀mú láéláé. Fún ìdí yìí, ó fi Jesu hàn bí ìran ọba Dafidi àti ti Abrahamu (1.1). Àti pé Matiu ṣe àmúlò ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àti àyọlò láti inú Májẹ̀mú láéláé láti fi ṣàlàyé ìgbé ayé Jesu. Jesu wá láti jẹ́ olùgbàlà àwọn Júù (1.12), ti ìkọlà (4.13-16), àti ti gbogbo ayé (28.19). Ẹ̀kọ́ ìwà rere tí a fẹ́ fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìjọba Ọlọ́run ni a rí nínú ìwàásù rẹ orí òkè (5–7) níbi tí ohun tó ní iye lórí láyé ti di ohun ìkọ̀sílẹ̀, tí ìjọba Ọlọ́run àti ògo rẹ̀ sì di ohun tó dára jùlọ.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Jesu 1.1–4.25.
ii. Ìwàásù ní orí òkè 5.2–7.29.
iii. Ìkọ́ni àpapọ̀, àwọn àkàwé àti àwọn ìwàásù 8.1–18.35.
iv. Ìrìnàjò sí Jerusalẹmu àti ìkìlọ̀ ìgbẹ̀yìn 19.1–23.39.
v. Ìsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tó ń bọ̀ 24.1–25.46.
vi. Ikú àti àjíǹde 26.2–28.20.

Currently Selected:

Matiu Ìfáàrà: YCB

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in