YouVersion Logo
Search Icon

Marku Ìfáàrà

Ìfáàrà
Marku ajíhìnrere jẹ́ alábáṣiṣẹ́ aposteli Paulu. Ó fi ìlú Romu ṣe ibùjókòó ní ìgbẹ̀yìn, ní ibi tí ó ti ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí ó rántí nípa aposteli Peteru. Nítorí náà, ìhìnrere Marku tan ìmọ́lẹ̀ sí iṣẹ́ ìhìnrere bí ẹlẹ́rìí ojúkorojú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ń ṣàpèjúwe. Ète Marku ni láti ṣe àkópọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìhìnrere tí kò papọ̀ tẹ́lẹ̀. Èyí mú kí ó sọ nípa iṣẹ́ Jesu ju àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ. Èyí sì mú kí iṣẹ́ rẹ̀ ṣe àkódélẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní ọ̀sẹ̀ tó gbẹ̀yìn nínú ìgbé ayé Jesu. Ìhìnrere Marku bẹ̀rẹ̀ lórí iṣẹ́ ìwàásù ìta gbangba Jesu àti ìkọ́ni nípa ìjọba Ọlọ́run. Ó ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ ikú Jesu tí ó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ (8.31; 9.31; 10.33,35) àti pé Jesu lọ sórí àgbélébùú láti kú fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ayé.
Marku ṣe àpèjúwe Jesu bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó wá ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Àwọn iṣẹ́ ìyanu, ìwòsàn, ìṣẹ́gun lórí ẹ̀mí àìmọ́ àti àgbààyanu agbára tí ó fihàn gbogbo ayé pé Jesu kì í ṣe ìránṣẹ́ kan lásán. Ṣùgbọ́n nítòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ni (15.31). Àjíǹde Jesu jẹ́ ẹ̀rí tòótọ́ sí gbogbo iṣẹ́ àṣeyọrí rẹ̀. Nísinsin yìí a dúró de ìpadàbọ̀ rẹ̀ nínú ògo láti ọ̀run wá. Marku kọ ìwé yìí láti mú àwọn onígbàgbọ́ Romu lọ́kàn le ní àkókò inúnibíni.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Iṣẹ́ Johanu onítẹ̀bọmi àti ìtẹ̀bọmi Jesu 1.1–1.13.
ii. Iṣẹ́ ìhìnrere Jesu ní Galili 1.14–9.50.
iii. Ìrìnàjò Jesu sí Jerusalẹmu 10.1–11.26.
iv. Wàhálà Jesu nínú ìlú 11.27–12.44.
v. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nǹkan tó ń bọ̀ 13.1-27.
vi. Ikú àti àjíǹde Jesu 14.1–16.8.

Currently Selected:

Marku Ìfáàrà: YCB

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in