1
Gẹnẹsisi 15:6
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
BMYO
Abramu gba OLúWA gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.
Compara
Explorar Gẹnẹsisi 15:6
2
Gẹnẹsisi 15:1
Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ OLúWA tọ Abramu wá lójú ìran pé, “Abramu má ṣe bẹ̀rù. Èmi ni ààbò rẹ, Èmi sì ni èrè ńlá rẹ.”
Explorar Gẹnẹsisi 15:1
3
Gẹnẹsisi 15:5
OLúWA sì mú Abramu jáde sí ìta ó sì wí fún un pé, “Gbé ojú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀ bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú-ọmọ rẹ yóò rí.”
Explorar Gẹnẹsisi 15:5
4
Gẹnẹsisi 15:4
Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tún tọ̀ ọ́ wá pé, “Ọkùnrin yìí kọ́ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ bí kò ṣe ọmọ tí ìwọ bí fúnra rẹ̀ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ.”
Explorar Gẹnẹsisi 15:4
5
Gẹnẹsisi 15:13
Nígbà náà ni OLúWA wí fún Abramu pé, “Mọ èyí dájú pé, irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì, wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irinwó (400) ọdún.
Explorar Gẹnẹsisi 15:13
6
Gẹnẹsisi 15:2
Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “OLúWA Olódùmarè, kí ni ìwọ yóò fi fún mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò bímọ, Elieseri ará Damasku ni yóò sì jogún mi,”
Explorar Gẹnẹsisi 15:2
7
Gẹnẹsisi 15:18
Ní ọjọ́ náà gan an ni OLúWA dá májẹ̀mú pẹ̀lú Abramu, ó sì wí pé, “Àwọn ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ejibiti dé odò ńlá Eufurate
Explorar Gẹnẹsisi 15:18
8
Gẹnẹsisi 15:16
Ní ìran kẹrin àwọn ìran rẹ yóò padà wá sí ibi. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò ì tí ì kún òsùwọ̀n.”
Explorar Gẹnẹsisi 15:16