1
Gẹnẹsisi 9:12-13
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ọlọ́run sì wí pé, “Èyí ni ààmì májẹ̀mú tí mo ń dá yìí láàrín èmi àti ẹ̀yin àti ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, májẹ̀mú àtìrandíran tó ń bọ̀: Mo ti fi òṣùmàrè sí àwọsánmọ̀, yóò sì jẹ́ ààmì májẹ̀mú láàrín èmi àti ayé.
Compara
Explorar Gẹnẹsisi 9:12-13
2
Gẹnẹsisi 9:16
Nígbàkígbà tí òṣùmàrè bá yọ ní àwọsánmọ̀, èmi yóò rí i, èmi yóò sì rántí májẹ̀mú ayérayé tí ń bẹ láàrín Ọlọ́run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń bẹ ní ayé.”
Explorar Gẹnẹsisi 9:16
3
Gẹnẹsisi 9:6
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀, láti ọwọ́ ènìyàn ni a ó gbà ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀. Nítorí ní àwòrán Ọlọ́run ni Ọlọ́run dá ènìyàn.
Explorar Gẹnẹsisi 9:6
4
Gẹnẹsisi 9:1
Ọlọ́run sì súre fún Noa àti àwọn ọmọ rẹ̀ wí pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì pọ̀ ní iye, kí ẹ sì kún ayé.
Explorar Gẹnẹsisi 9:1
5
Gẹnẹsisi 9:3
Gbogbo ohun tó wà láààyè tí ó sì ń rìn, ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín, bí mo ṣe fi ewéko fún un yín náà ni mo fi ohun gbogbo fún un yín.
Explorar Gẹnẹsisi 9:3
6
Gẹnẹsisi 9:2
Ẹ̀rù yín yóò mú ojo wà lára gbogbo ẹranko àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀; àti gbogbo ẹja Òkun; a fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.
Explorar Gẹnẹsisi 9:2
7
Gẹnẹsisi 9:7
Ṣùgbọ́n ní tiyín, ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ máa gbá yìn lórí ilẹ̀, kí ẹ sì pọ̀ sí i lórí rẹ̀.”
Explorar Gẹnẹsisi 9:7
Inici
La Bíblia
Plans
Vídeos