LUKU 21:25-27

LUKU 21:25-27 YCE

“Àmì yóo yọ ní ojú oòrùn ati ní ojú òṣùpá ati lára àwọn ìràwọ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo dààmú nígbà tí wọ́n bá gbọ́ tí òkun ń hó, tí ó ń ru sókè. Àwọn eniyan yóo kú sára nítorí ìbẹ̀rù, nígbà tí wọ́n bá rí ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ayé. Nítorí gbogbo ẹ̀dá ojú ọ̀run ni a óo mì tìtì. Nígbà náà ni wọn óo rí Ọmọ-Eniyan tí óo máa bọ̀ ninu ìkùukùu pẹlu agbára ati ògo ńlá.

Llegeix LUKU 21