JẸNẸSISI 6
6
Ìwà Burúkú Eniyan
1Nígbà tí eniyan bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i lórí ilẹ̀, tí wọ́n sì ń bí ọmọbinrin, 2nígbà náà ni àwọn ẹ̀dá ọ̀run lọkunrin ṣe akiyesi pé àwọn ọmọbinrin tí eniyan ń bí lẹ́wà gidigidi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ èyí tí ó wù wọ́n lára wọn. 3OLUWA bá wí pé, “N kò ní jẹ́ kí eniyan wà láàyè títí lae, nítorí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n. Ọgọfa (120) ọdún ni wọn yóo máa gbé láyé.” 4Àwọn òmìrán wà láyé ní ayé ìgbà náà, wọ́n tilẹ̀ tún wà láyé fún àkókò kan lẹ́yìn rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọkunrin Ọlọrun fẹ́ aya láàrin àwọn ọmọ eniyan, àwọn ọmọ tí wọ́n bí ni àwọn òmìrán wọnyi. Àwọn ni wọ́n jẹ́ akọni ati olókìkí nígbà náà.#Job 1:6; 2:1. #Nọm 13:33; Sir 16:7; Bar 3:26.
5Nígbà tí OLUWA rí i pé ìwà burúkú eniyan ti pọ̀ jù láyé, ati pé kìkì ibi ni èrò inú wọn nígbà gbogbo, 6inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi pé ó dá eniyan sí ayé, ó sì dùn ún, 7tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wí pé, “N óo pa àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo dá run lórí ilẹ̀ ayé, ati eniyan ati ẹranko ati àwọn ohun tí ń fàyà fà káàkiri lórí ilẹ̀, ati ẹyẹ, gbogbo wọn ni n óo parun, nítorí ó bà mí ninu jẹ́ pé mo dá wọn.” 8Ṣugbọn Noa rí ojurere OLUWA.#Mat 24:37; Luk 17:26; 1 Pet 3:20.
Ìtàn Noa
9Ìtàn ìran Noa nìyí: Noa jẹ́ olódodo, òun nìkan ṣoṣo ni eniyan pípé ní àkókò tirẹ̀, ó sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu OLUWA.#Sir 44:17-18; 2 Pet 2:5. 10Ó bí ọmọkunrin mẹta tí orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣemu, Hamu, ati Jafẹti.
11Ayé kún fún ìwà ìbàjẹ́ lójú Ọlọrun, ìwà jàgídíjàgan sì gba gbogbo ayé. 12Ọlọrun rí i pé ayé ti bàjẹ́, nítorí pé ìwà ìbàjẹ́ ni gbogbo eniyan ń hù.
13Ọlọrun bá sọ fún Noa pé, “Mo ti pinnu láti pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run, nítorí ìwà ipá wọn ti gba gbogbo ayé, àtàwọn àtayé ni n óo parun. 14Nítorí náà, fi igi goferi kan ọkọ̀ ojú omi fún ara rẹ. Ṣe ọpọlọpọ yàrá sinu rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà kùn ún ninu ati lóde. 15Bí o óo ti kan ọkọ̀ náà nìyí: kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ọọdunrun (300) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ, gíga rẹ̀ yóo jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ. 16Kan òrùlé sí orí ọkọ̀ náà, ṣugbọn fi ààyè sílẹ̀ láàrin orí rẹ̀ ati ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yíká, tí yóo jẹ́ ìwọ̀n igbọnwọ kan. Kí o kan ọkọ̀ náà ní ìpele mẹta, kí o sì ṣe ẹnu ọ̀nà sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. 17N óo jẹ́ kí ìkún omi bo gbogbo ayé, yóo pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run, gbogbo ohun ẹlẹ́mìí tí ó wà láyé ni yóo kú. 18Ṣugbọn n óo bá ọ dá majẹmu, o óo wọ inú ọkọ̀ náà, ìwọ pẹlu aya rẹ ati àwọn ọmọkunrin rẹ ati àwọn aya wọn. 19Kí o sì mú meji meji ninu gbogbo ohun alààyè, kí wọ́n lè wà láàyè pẹlu rẹ, takọ-tabo ni kí o mú wọn. 20Meji meji yóo tọ̀ ọ́ wá ninu oríṣìíríṣìí àwọn ẹyẹ, ati oríṣìíríṣìí àwọn ẹran ọ̀sìn, ati oríṣìíríṣìí àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, kí o lè mú kí wọ́n wà láàyè pẹlu rẹ. 21Kí o sì kó oniruuru oúnjẹ sinu ọkọ̀ náà fún ara rẹ ati fún wọn.” 22Noa bá ṣe gbogbo ohun tí Ọlọrun pàṣẹ fún un.#Heb 11:17.
Currently Selected:
JẸNẸSISI 6: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: