1
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:1
Yoruba Bible
Gbogbo nǹkan láyé yìí ló ní àkókò ati ìgbà tirẹ̀
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:1
2
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:2-3
àkókò bíbí wà, àkókò kíkú sì wà; àkókò gbígbìn wà, àkókò kíkórè ohun tí a gbìn sì wà. Àkókò pípa wà, àkókò wíwòsàn sì wà, àkókò wíwó lulẹ̀ wà, àkókò kíkọ́ sì wà.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:2-3
3
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:4-5
Àkókò ẹkún wà, àkókò ẹ̀rín sì wà; àkókò ọ̀fọ̀ wà, àkókò ijó sì wà. Àkókò fífọ́n òkúta ká wà, àkókò kíkó òkúta jọ sì wà; àkókò ìkónimọ́ra wà, àkókò àìkónimọ́ra sì wà.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:4-5
4
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:7-8
Àkókò fífa nǹkan ya wà, àkókò rírán nǹkan pọ̀ sì wà; àkókò dídákẹ́ wà, àkókò ọ̀rọ̀ sísọ sì wà. Àkókò láti fi ìfẹ́ hàn wà àkókò láti kórìíra sì wà; àkókò ogun wà, àkókò alaafia sì wà.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:7-8
5
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:6
Àkókò wíwá nǹkan wà, àkókò sísọ nǹkan nù wà; àkókò fífi nǹkan pamọ́ wà, àkókò dída nǹkan nù sì wà.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:6
6
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:14
Mo mọ̀ pé gbogbo ohun tí Ọlọrun ṣe, yóo wà títí lae. Kò sí ohun tí ẹ̀dá lè fi kún un, tabi tí ẹ̀dá lè yọ kúrò níbẹ̀, Ọlọrun ni ó dá a bẹ́ẹ̀ kí eniyan lè máa bẹ̀rù rẹ̀.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:14
7
ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:17
Mo wí ní ọkàn ara mi pé, Ọlọrun yóo dájọ́ fún olódodo ati fún eniyan burúkú; nítorí ó ti yan àkókò fún ohun gbogbo ati fún iṣẹ́ gbogbo.
Ṣàwárí ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:17
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò