1
1 Tẹsalonika 5:16-18
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo nínú ipòkípò tí o wù kí ẹ wà; nítorí pé, èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún yin nínú Kristi Jesu nítòótọ́.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí 1 Tẹsalonika 5:16-18
2
1 Tẹsalonika 5:23-24
Kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀, Ọlọ́run àlàáfíà, sọ yín di mímọ́ pátápátá. Kí Ọlọ́run pa ẹ̀mí àti ọkàn pẹ̀lú ara yín mọ́ pátápátá ní àìlábùkù, títí di ìgbà wíwá Jesu Kristi Olúwa wa. Olóòtítọ́ ni ẹni tí ó pè yín, yóò sì ṣe.
Ṣàwárí 1 Tẹsalonika 5:23-24
3
1 Tẹsalonika 5:15
Ẹ rí i pé kò sí ẹni tí ó fi búburú san búburú, ṣùgbọ́n ẹ máa lépa èyí tí í ṣe rere láàrín ara yín àti sí ènìyàn gbogbo.
Ṣàwárí 1 Tẹsalonika 5:15
4
1 Tẹsalonika 5:11
Nítorí náà, ẹ máa gba ara yín níyànjú, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe.
Ṣàwárí 1 Tẹsalonika 5:11
5
1 Tẹsalonika 5:14
Ẹ̀yin ará mi, ẹ kìlọ̀ fún àwọn ọ̀lẹ ti ó wà láàrín yín, ẹ gba àwọn tí ẹ̀rù ń bà ní ìyànjú, ẹ tọ́jú àwọn aláìlera pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí ẹ sì ní sùúrù pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.
Ṣàwárí 1 Tẹsalonika 5:14
6
1 Tẹsalonika 5:9
Nítorí pé, Ọlọ́run kò yàn wa láti da ìbínú rẹ̀ gbígbóná sí orí wa, ṣùgbọ́n ó yàn láti gbà wá là nípasẹ̀ Olúwa wa, Jesu Kristi.
Ṣàwárí 1 Tẹsalonika 5:9
7
1 Tẹsalonika 5:5
Nítorí gbogbo yín ni ọmọ ìmọ́lẹ̀ àti ọmọ ọ̀sán gangan. Ẹ kì í ṣe tí òru tàbí tí òkùnkùn mọ́.
Ṣàwárí 1 Tẹsalonika 5:5
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò