1
Ìṣe àwọn Aposteli 16:31
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Wọ́n sì wí fún un pé, “Gbá Jesu Kristi Olúwa gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là, ìwọ àti àwọn ará ilé rẹ pẹ̀lú.”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Ìṣe àwọn Aposteli 16:31
2
Ìṣe àwọn Aposteli 16:25-26
Ṣùgbọ́n láàrín ọ̀gànjọ́ Paulu àti Sila ń gbàdúrà, wọ́n sì ń kọrin ìyìn si Ọlọ́run: àwọn ara túbú sì ń tẹ́tí sí wọn. Lójijì ilẹ̀ mímì ńlá sì mi, tó bẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé túbú mì tìtì: lọ́gán, gbogbo ìlẹ̀kùn sì ṣí, ìdè gbogbo wọn sì tú sílẹ̀.
Ṣàwárí Ìṣe àwọn Aposteli 16:25-26
3
Ìṣe àwọn Aposteli 16:30
Ó sì mú wọn jáde, ó ní, “Alàgbà, kín ni ki èmi ṣe ki n lè là?”
Ṣàwárí Ìṣe àwọn Aposteli 16:30
4
Ìṣe àwọn Aposteli 16:27-28
Nígbà tí onítúbú si tají, tí o sì ri pé, àwọn ìlẹ̀kùn túbú tí ṣí sílẹ̀, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì fẹ́ pa ara rẹ̀, ó ṣe bí àwọn ara túbú ti sálọ. Ṣùgbọ́n Paulu gbé ohun rẹ̀ sókè, wí pé, “Má ṣe pa ara rẹ lára: nítorí gbogbo wa ń bẹ níhìn-ín yìí!”
Ṣàwárí Ìṣe àwọn Aposteli 16:27-28
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò