1
Oniwaasu 9:10
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, ṣe é pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ, nítorí kò sí iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ìpinnu tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú isà òkú níbi tí ò ń lọ.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Oniwaasu 9:10
2
Oniwaasu 9:11
Mo ti rí ohun mìíràn lábẹ́ oòrùn Eré ìje kì í ṣe fún ẹni tí ó yára tàbí ogun fún alágbára bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kò wà fún ọlọ́gbọ́n tàbí ọrọ̀ fún ẹni tí ó ní òye tàbí ojúrere fún ẹni tí ó ní ìmọ̀; ṣùgbọ́n ìgbà àti èsì ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.
Ṣàwárí Oniwaasu 9:11
3
Oniwaasu 9:9
Máa jẹ ayé pẹ̀lú ìyàwó rẹ, ẹni tí o fẹ́ràn, ní gbogbo ọjọ́ ayé àìní ìtumọ̀ yí tí Ọlọ́run ti fi fún ọ lábẹ́ oòrùn—gbogbo ọjọ́ àìní ìtumọ̀ rẹ. Nítorí èyí ni ìpín tìrẹ ní ayé àti nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ ní abẹ́ oòrùn.
Ṣàwárí Oniwaasu 9:9
4
Oniwaasu 9:7
Lọ jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ayọ̀, kí o sì mu ọtí wáìnì rẹ pẹ̀lú inú dídùn dé ọkàn, nítorí pé ìsinsin yìí ni Ọlọ́run ṣíjú àánú wo ohun tí o ṣe.
Ṣàwárí Oniwaasu 9:7
5
Oniwaasu 9:18
Ọgbọ́n dára ju ohun èlò ogun lọ, ṣùgbọ́n ẹnìkan tó dẹ́ṣẹ̀ a máa ba ohun dídára púpọ̀ jẹ́.
Ṣàwárí Oniwaasu 9:18
6
Oniwaasu 9:17
Ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa wà ní ìmúṣẹ ju igbe òmùgọ̀ alákòóso lọ.
Ṣàwárí Oniwaasu 9:17
7
Oniwaasu 9:5
Nítorí pé ẹni tí ó wà láààyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kú ṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kan wọn kò ní èrè kankan mọ́, àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé.
Ṣàwárí Oniwaasu 9:5
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò