SAMUẸLI KINNI 26

26
Dafidi Dá Ẹ̀mí Saulu sí lẹẹkeji
1Àwọn ọkunrin kan, ará Sifi lọ sọ fún Saulu ní Gibea pé, “Dafidi farapamọ́ sí òkè Hakila tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jeṣimoni.”#O. Daf 54:Àkọlé 2Lẹsẹkẹsẹ, Saulu mú ẹgbẹẹdogun (3,000) akọni ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ wá Dafidi ninu aṣálẹ̀ Sifi. 3Wọ́n pabùdó wọn sí ẹ̀bá ọ̀nà ní òkè Hakila, Dafidi sì wà ninu aṣálẹ̀ náà. Nígbà tí Dafidi mọ̀ pé Saulu ń wá òun kiri, 4ó rán amí láti rí i dájú pé Saulu wà níbẹ̀. 5Dafidi lọ lẹsẹkẹsẹ láti rí ibi tí Saulu ati Abineri, ọmọ Neri, olórí ogun Saulu, dùbúlẹ̀ sí. Saulu wà ninu àgọ́, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì pàgọ́ yí i ká.
6Dafidi bá bèèrè lọ́wọ́ Ahimeleki, ará Hiti ati Abiṣai ọmọ Seruaya, arakunrin Joabu pé, “Ta ni yóo bá mi lọ sí ibùdó Saulu?”
Abiṣai dáhùn pé, “N óo bá ọ lọ.”
7Dafidi ati Abiṣai bá lọ sí ibùdó Saulu ní òru ọjọ́ náà, Saulu sì ń sùn ní ààrin àgọ́, ó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ gúnlẹ̀ lẹ́bàá ìrọ̀rí rẹ̀. Abineri ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì sùn yí i ká. 8Abiṣai bá sọ fún Dafidi pé, “Ọlọrun ti fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́ ní òní yìí, gbà mí láàyè kí n yọ ọ̀kọ̀, kí n sì gún un ní àgúnpa lẹ́ẹ̀kanṣoṣo.”
9Ṣugbọn Dafidi sọ fún Abiṣai pé, “O kò gbọdọ̀ ṣe é ní ibi kan, nítorí ẹni tí ó bá pa ẹni àmì òróró OLUWA yóo jẹ̀bi. 10Níwọ̀n ìgbà tí OLUWA wà láàyè, OLUWA yóo pa á; tabi kí ọjọ́ ikú rẹ̀ pé, tabi kí ó kú lójú ogun. 11Kí OLUWA má ṣe jẹ́ kí n pa ẹni àmì òróró rẹ̀. Nítorí náà, jẹ́ kí á mú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ati ìgò omi rẹ̀ kí á sì máa lọ.”#1 Sam 24:6 12Dafidi bá mú ọ̀kọ̀ ati ìgò omi Saulu ní ìgbèrí rẹ̀, òun pẹlu Abiṣai sì jáde lọ. Kò sí ẹnikẹ́ni ninu Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ tí ó mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, tabi tí ó jí nítorí OLUWA kùn wọ́n ní oorun.
13Dafidi kọjá sí òdìkejì àfonífojì ní orí òkè níbi tí ó jìnnà díẹ̀. 14Ó sì ké sí àwọn ọmọ ogun Saulu ati Abineri pé, “Abineri! Ǹjẹ́ ò ń gbọ́ ohùn mi bí!”
Abineri sì dáhùn pé, “Ìwọ ta ni ń pariwo! Tí o fẹ́ jí ọba?”
15Dafidi dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ìwọ kọ́ ni alágbára jùlọ ní Israẹli? Kí ló dé tí o kò dáàbò bo ọba, oluwa rẹ? Láìpẹ́ yìí ni ẹnìkan wọ inú àgọ́ yín láti pa oluwa rẹ. 16Ohun tí o ṣe yìí kò dára, mo fi OLUWA ṣe ẹ̀rí pé, ó yẹ kí o kú, nítorí pé o kò dáàbò bo oluwa rẹ, ẹni àmì òróró OLUWA. Níbo ni ọ̀kọ̀ ọba wà? Ibo sì ni ìgò omi tí ó wà ní ìgbèrí rẹ̀ wà pẹlu?”
17Saulu mọ̀ pé Dafidi ni ó ń sọ̀rọ̀, ó bá bèèrè pé, “Dafidi ọmọ mi, ṣé ìwọ ni ò ń sọ̀rọ̀?”
Dafidi dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, oluwa mi. 18Kí ló dé tí o fi ń lépa èmi iranṣẹ rẹ? Kí ni mo ṣe? Kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ mi? 19Oluwa mi, gbọ́ ohun tí èmi iranṣẹ rẹ fẹ́ sọ. Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni ó gbé ọ dìde sí mi, kí ó gba ẹbọ ẹ̀bẹ̀, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé eniyan ni, kí ègún OLUWA wá sórí olúwarẹ̀, nítorí wọ́n lé mi jáde, kí n má baà ní ìpín ninu ilẹ̀ ìní tí OLUWA fún àwọn eniyan rẹ̀. Wọ́n ń sọ fún mi pé kí n lọ máa bọ oriṣa. 20Má jẹ́ kí n kú sílẹ̀ àjèjì níbi tí OLUWA kò sí. Kí ló dé tí ọba Israẹli fi ń lépa èmi kékeré yìí, bí ẹni ń dọdẹ àparò lórí òkè?”
21Saulu dáhùn pé, “Mo ti ṣe ibi, máa bọ̀ Dafidi, ọmọ mi. N kò ní ṣe ọ́ ní ibi mọ́, nítorí pé ẹ̀mí mi níye lórí lójú rẹ lónìí. Mo ti hùwà òmùgọ̀, ohun tí mo ṣe burú pupọ.”
22Dafidi dáhùn pé, “Ọ̀kọ̀ rẹ nìyí, oluwa mi, jẹ́ kí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun rẹ wá gbà á. 23OLUWA a máa san ẹ̀san rere fún àwọn tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ ati olódodo. Lónìí, OLUWA fi ọ́ lé mi lọ́wọ́, ṣugbọn mo kọ̀ láti ṣe ọ́ ní ibi, nítorí pé ẹni àmì òróró OLUWA ni ọ́. 24Gẹ́gẹ́ bí mo ti dá ẹ̀mí rẹ sí lónìí, kí OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi, kí ó sì yọ mí kúrò ninu gbogbo ìṣòro.”
25Saulu dáhùn pé, “Ọlọ́run yóo bukun ọ, ọmọ mi, o óo máa ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí o bá ń ṣe.”
Dafidi bá bá tirẹ̀ lọ, Saulu sì pada sí ilé rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

SAMUẸLI KINNI 26: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀