SAMUẸLI KINNI 30

30
Dafidi Bá Àwọn Ará Amaleki Jagun
1Nígbà tí Dafidi ati àwọn ọkunrin rẹ̀ pada dé Sikilagi ní ọjọ́ kẹta, wọ́n rí i pé àwọn ará Amaleki ti gbógun ti Nẹgẹbu ati Sikilagi, wọ́n ṣẹgun Sikilagi, wọ́n sì sun ìlú náà níná; 2wọ́n kó gbogbo obinrin ati àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ lẹ́rú, àtọmọdé, àtàgbà, wọn kò sì pa ẹnikẹ́ni. 3Nígbà tí Dafidi ati àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dé, wọ́n rí i pé wọ́n ti dáná sun ìlú náà, wọ́n sì ti kó àwọn aya wọn ati àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin lẹ́rú. 4Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sọkún títí tí ó fi rẹ̀ wọ́n. 5Wọ́n kó àwọn aya Dafidi mejeeji, Ahinoamu ará Jesireeli ati Abigaili opó Nabali lẹ́rú pẹlu.#1 Sam 25:42-43
6Dafidi sì wà ninu ìbànújẹ́, nítorí pé inú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bàjẹ́ nítorí àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì ń gbèrò láti sọ ọ́ ní òkúta pa. Ṣugbọn Dafidi túbọ̀ ní igbẹkẹle ninu OLUWA Ọlọrun rẹ̀. 7Dafidi sọ fún Abiatari alufaa, ọmọ Ahimeleki, pé kí ó mú efodu wá. Abiatari sì mú un wá.#1 Sam 22:20-23 8Dafidi bá bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “Ṣé kí n lépa àwọn ọmọ ogun náà? Ṣé n óo bá wọn?”
OLUWA sì dáhùn pé, “Lépa wọn, o óo bá wọn, o óo sì gba àwọn eniyan rẹ.”
9Dafidi ati àwọn ẹgbẹta (600) ọmọlẹ́yìn rẹ̀, bá lọ, nígbà tí wọ́n dé odò Besori, apá kan ninu wọn dúró ní etí odò náà. 10Dafidi ati irinwo (400) eniyan sì ń lépa wọn lọ, ṣugbọn àwọn igba (200) eniyan tí àárẹ̀ mú kò lè la odò náà kọjá, wọ́n sì dúró sí etí odò. 11Àwọn ọmọlẹ́yìn Dafidi rí ọmọkunrin ará Ijipti kan ninu oko, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Dafidi, wọ́n fún un ní oúnjẹ ati omi, 12èso ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ ati ìdì àjàrà meji. Nígbà tí ó jẹun tán, ó ní agbára nítorí pé kò tíì jẹun, kò sì mu omi fún ọjọ́ mẹta sẹ́yìn. 13Dafidi bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ta ni oluwa rẹ, níbo ni o sì ti wá?”
Ó dáhùn pé, “Ará Ijipti ni mí, ẹrú ará Amaleki kan. Ọjọ́ kẹta nìyí tí oluwa mi ti fi mí sílẹ̀ níhìn-ín, nítorí pé ara mi kò dá. 14A ti jagun ní Nẹgẹbu ní agbègbè Kereti ati ní agbègbè Juda ati ní agbègbè Nẹgẹbu ti Kalebu, a sì sun Sikilagi níná.”
15Dafidi bi í léèrè pé, “Ṣé o lè mú mi lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ogun náà?”
Ó dáhùn pé, “N óo mú ọ lọ, bí o bá ṣèlérí ní orúkọ Ọlọrun pé o kò ní pa mí, tabi kí o fi mí lé oluwa mi lọ́wọ́.” 16Ó mú Dafidi lọ bá wọn.
Àwọn ọmọ ogun náà fọ́n káàkiri, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń jó, nítorí ọpọlọpọ ìkógun tí wọ́n rí kó ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia ati Juda. 17Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Dafidi kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Kò sì sí ẹni tí ó là ninu wọn, àfi irinwo ọdọmọkunrin tí wọ́n gun ràkúnmí sá lọ. 18Dafidi sì gba àwọn eniyan rẹ̀ pada, ati gbogbo nǹkan tí àwọn ará Amaleki náà kó, ati àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji. 19Kò sí ohun kan tí ó nù, Dafidi gba gbogbo àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin rẹ̀ pada, ati gbogbo nǹkan tí àwọn ará Amaleki kó. 20Ó gba gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn pẹlu. Àwọn eniyan náà sì ń dá àwọn ẹran ọ̀sìn náà jọ níwájú Dafidi, wọ́n ń sọ pé, “Ìkógun Dafidi nìyí.”
21Dafidi lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn igba (200) eniyan tí àárẹ̀ mú pupọ, tí wọn kò lè kọjá odò, ṣugbọn tí wọ́n dúró lẹ́yìn odò Besori; àwọn náà wá pàdé Dafidi ati àwọn tí wọ́n bá a lọ. Dafidi sì kí wọn dáradára. 22Àwọn tí wọ́n jẹ́ eniyan burúkú ati òǹrorò láàrin àwọn tí wọ́n bá Dafidi lọ ní, “Nítorí pé wọn kò bá wa lọ, a kò ní fún wọn ninu ìkógun wa tí a gbà pada, àfi aya ati àwọn ọmọ wọn nìkan ni wọ́n lè gbà.”
23Ṣugbọn Dafidi dáhùn pé, “Ẹ̀yin arakunrin mi, ẹ ẹ̀ gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí gbogbo ohun tí OLUWA fifún wa. Òun ni ó pa wá mọ́ tí ó sì fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọmọ ogun tí wọ́n dojú ìjà kọ wá. 24Kò sí ẹni tí yóo fara mọ́ àbá yín yìí. Gbogbo wa ni a óo jọ pín ìkógun náà dọ́gba-dọ́gba, ati àwọn tí ó lọ ati àwọn tí ó dúró ti ẹrù.” 25Láti ọjọ́ náà ni ó ti sọ ọ́ di òfin ati ìlànà ní Israẹli, títí di òní olónìí.
26Nígbà tí Dafidi pada dé Sikilagi, ó fi ẹ̀bùn ranṣẹ sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olórí Juda; ó mú ninu ìkógun náà, ó ní, “Ẹ̀bùn yín nìyí lára ìkógun tí a kó láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá OLUWA.” 27Ó fi ranṣẹ sí àwọn tí wọ́n wà ní Bẹtẹli, ati àwọn tí wọ́n wà ní Ramoti ti Nẹgẹbu, ati Jatiri; 28ati àwọn tí wọ́n wà ní Aroeri, Sifimoti, ati ní Eṣitemoa; 29ní Rakali, ní àwọn ìlú Jerameeli, àwọn ìlú Keni, 30ní Homa, Boraṣani, ati ní Ataki, 31ní Heburoni ati ní gbogbo ìlú tí Dafidi ati àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti rìn kiri.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

SAMUẸLI KINNI 30: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀