JOBU 23

23
1Nígbà náà ni Jobu dáhùn pé,
2“Lónìí, ìráhùn mi tún kún fún ẹ̀dùn,
ọwọ́ Ọlọrun ń le lára mi,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mò ń kérora.
3Áà! Ìbá jẹ́ pé mo mọ ibi tí mo ti lè rí i ni,
ǹ bá lọ siwaju ìtẹ́ rẹ̀!
4Ǹ bá ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ̀,
gbogbo ẹnu ni ǹ bá fi ṣàròyé.
5Ǹ bá gbọ́ èsì tí yóo fún mi,
ati ọ̀rọ̀ tí yóo sọ fún mi.
6Ṣé yóo gbéjà kò mí pẹlu agbára ńlá rẹ̀?
Rárá o, yóo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
7Ibẹ̀ ni olódodo yóo ti lè sọ ti ẹnu rẹ̀,
yóo sì dá mi sílẹ̀ títí lae.
8“Wò ó! Mo lọ siwaju, kò sí níbẹ̀,
mo pada sẹ́yìn, n kò gbúròó rẹ̀.
9Mo wo apá ọ̀tún, n kò rí i,
mo wo apá òsì, kò sí níbẹ̀.
10Ṣugbọn ó mọ gbogbo ọ̀nà mi,
ìgbà tí ó bá dán mi wò tán,
n óo yege bíi wúrà.
11Mò ń tẹ̀lé e lẹ́yìn, mo súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí,
n kò tíì yipada kúrò ní ọ̀nà rẹ̀.
12N kò tíì yapa kúrò ninu àṣẹ tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde,
mò ń pa wọ́n mọ́ ninu ọkàn mi.
13“Ṣugbọn Ọlọrun kìí yipada,
kò sí ẹni tí ó lè yí i lọ́kàn pada.
Ohun tí ó bá fẹ́ gan-an ni yóo ṣe.
14Yóo ṣe ohun tí ó ti pinnu láti ṣe fún mi ní àṣeyọrí,
ati ọpọlọpọ nǹkan bẹ́ẹ̀ yòókù
tí ó tún ní lọ́kàn láti ṣe fún mi.
15Ìdí nìyí tí ẹ̀rù fi bà mí níwájú rẹ̀,
tí mo bá ro nǹkan wọnyi, jìnnìjìnnì rẹ̀ a bò mí.
16Ọlọrun ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi,
Olodumare ti dẹ́rùbà mí.
17Nítorí pé òkùnkùn yí mi ká,
òkùnkùn biribiri sì ṣú bò mí lójú.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOBU 23: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀