JOBU 25

25
1Bilidadi ará Ṣuha bá dáhùn pé,
2“Ọlọrun ni ọba, òun ló sì tó bẹ̀rù,
ó ń ṣe àkóso alaafia lọ́run.
3Ta ló lè ka àwọn ọmọ ogun rẹ̀?
Ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí?
4Báwo wá ni eniyan ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun?
Báwo ni ẹni tí obinrin bí ṣe lè jẹ́ ẹni mímọ́?
5Wò ó, òṣùpá pàápàá kò mọ́lẹ̀ tó,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìràwọ̀ kò mọ́ tó lójú rẹ̀;
6kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti eniyan tí ó dàbí ìdin,
tabi ọmọ eniyan tí ó dàbí ekòló lásánlàsàn!”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOBU 25: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀