ORIN DAFIDI 137

137
Àwọn Ọmọ Israẹli Kọrin Arò ní Ìgbèkùn
1Lẹ́bàá odò Babiloni ni a jókòó, tí a sọkún,
nígbà tí a ranti Sioni.
2Lára igi wilo níbẹ̀ ni a fi hapu wa kọ́ sí,
3nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn tí ó kó wa ní ìgbèkùn
ti ní kí á kọrin fún àwọn.
Àwọn tí ó ń pọ́n wa lójú sọ pé kí á dá àwọn lárayá, wọ́n ní,
“Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.”
4Báwo ni a óo ṣe kọ orin OLUWA ní ilẹ̀ àjèjì?
5Jerusalẹmu, bí mo bá gbàgbé rẹ,
kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó rọ.
6Kí ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ èrìgì mi,
bí n kò bá ranti rẹ,
bí n kò bá sì fi Jerusalẹmu ṣe olórí ayọ̀ mi.
7OLUWA, ranti ohun tí àwọn ará Edomu ṣe
nígbà tí Jerusalẹmu bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá,
tí wọn ń pariwo pé,
“Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o títí dé ìpìlẹ̀ rẹ̀.”
8Babiloni! Ìwọ apanirun!
Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ̀san lára rẹ,
fún gbogbo ohun tí o ti ṣe sí wa!
9Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá kó àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ,
tí ó ṣán wọn mọ́ àpáta.#Ifi 18:6

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 137: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀